Ondo Ritual Killer: Ẹni tó gé orí olóri fún ògùn owó náá sán kú ni agọ́ ọlọ́pàá l'Ondo

Ẹni tó gé orí olóri fún ògùn owó náá sán kú ni agọ́ ọlọ́pàá l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Ondo/Police

Bii kayeefi ni ọrọ naa ri bi afunrasi to fẹ fi eeyan se ogun owo, Tunde Olayiwola ṣe ku si sẹẹli ọlọpaa lẹyin ti ẹka ile isẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo mu.

Iroyin ni ṣaaju iku rẹ, awọn ọlọpaa ti kọkọ mu u tori wọn ba ori eeyan tutu tí wọn ṣẹṣẹ pa lọwọ rẹ.

Olayiwola ni wọn se afihan rẹ pẹlu awọn afurasi mẹjọ miiran ti wọn mu fun oniruuru ẹsun to niṣe pẹlu ipaniyan, ijinigbe, ṣiṣe ẹgbẹ okunkun ni ọjọbọ ọsẹ to kọja lo kun si ile iwosan ọlọpaa ni ilu Akurẹ ti ṣe oluulu ipinlẹ Ondo.

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete

Olayiwola ẹni ti o ni babalawo akọṣẹmọṣẹ ni ohun ti o si ti n ṣe isẹ naa fun ọdun mẹtalelaadọta, ni oun ra ori tutu yii lọwọ alabara rẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira lati lo fun etuntun oogun owo.

O jẹwọ pe ori ti wọn ri ni ọwọ oun ni oun pinu lati fi ri pe oun ni aye ti o dara ati pe oun ko kabamọ kankan pe oun fẹ fi ori eniyan ṣe etutu.

Babalawo naa ni ti o ba jẹ pe ọmọ oun ni wọn pa lati se oogun owo, o tumọ si pe opin aye rẹ naa ni, ko si si nnkankan ti oun yoo ṣe si.

O kọ lati jẹwọ awọ alabaṣiṣẹ pọ rẹ, o ni a fi dandan oun naa fẹ lowo bi awọn to ku oun.

Kọmisọna ọlọpaa Oyeyemi Oyediran to fi awọn ọdaran naa han, ṣalaye pe ọlọpaa gba ipe pe ẹnikan ti o pe ara rẹ ni Alfa Tunde Olayiwola ti awọn eniyan funra si pe o jẹ oloogun fẹ gba ẹru kan ti wọn fura si pe o jẹ ori eeyan.

Àkọlé fídíò, Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Oyediran ni kia ni awọn ọlọpaa bọ si oju isẹ ti wọn ti wọn si mu ọkunrin naa ni agbegbe Ajagbale Oka nilu Ondo.

O fi kun pe ori eeya ti wọn ṣẹṣẹ pa ni wọn ri ni ọwọ rẹ.

Sugbọn lọ́jọ́ Aiku ti ṣe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejiola ọdun 2021 ni ọrọ bọ sita lati ẹnu ọlọpaa kan ti ko fẹ ki ẹnikẹni darukọ oun pe ọdaran ti wọn mu ni Oka ni ilu Ondo dede subululẹ ti o si ku ni ẹka agọ ọlọpaa ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn ẹlẹgbẹ okunkun ni agbegbe FUTA ni ilu Akure.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ naa Funmilayo Odunlami naa fidi ọrọ iku ọkunrin naa mulẹ sugbọ ko ṣalaye ni ẹkunrẹrẹ nnkan ti o fa iku rẹ