Olori Naomi Ogunwusi: Ki ní yóò sẹlẹ̀ sí Àrẹ́mọ Ooni Ile-Ife tí wọ́n bá gbé e kúrò l'Áàfin?

Aworan Olori Naomi, Baba Ifayemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Kii ṣe wọn ni wọn pe mọ pe Olori l'Aafin Ọọni ile Ife ti kede pe ou ki wọn ma pe oun ni olori Ọọni ife mọ biko ṣe olori awọn eniyan.

Ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ loju opo Instagram rẹ @queen_silekunolanaonaomi_oguwusi lo ti ṣalaye pe nnkan ti o se pataki julọ ni lati mu oju to arẹmọ ọba, ọmọ ọba Tadenikawo.

Bakan naa lo fi ku pe oun ti tẹsiwaju ninu irinajo aye oun.

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada

Ibeere ti ọpọ wa n bere lasiko yii ni pe:

Kini yoo ṣẹlẹ si arole ọba ti wọn ba gbe e kuro l'Afin?

Ooni Ife ati Iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bí ọpọ ṣe wa n bere awọn ibeere yii ni a BBC ṣe iwadii lọwọ awọn to tun mọ aṣa ati iṣẹṣe Yoruba awọn nnkan ti o le ṣeẹ ti wọn ba gbe arẹmọ ọba kuro l'Afin.

Ninu ọrọ rẹ Araba ilu Osogbo, Ifayemi Elebuubọn ṣalaye kii ṣe gbogbo ọmọ ọba lo maa n gbe aafin ọba dagba nitori idi kan tabi omiran.

Alaye ti Araba ṣe ni pe nigba miiran ki ọmọ ma ba maa yọ ayọ ayọju ati lati kọ awọn ẹkọ kan ti ko le kọ ninu ile.

O fi kun pe ni ti eyi to ṣẹlẹ ni afin Ọọni Ife kii ṣe nnkan tuntun nitori dandan kọ ni ki aarẹmọ gbe aafin dagba.

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete
Àkọlé fídíò, Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Ara awọn idi ti ọmọ ọba mii kii si fi dagba ni aafin ni ki o ma ba ma yọ ju tabi si agbara lo ti o ba ti mọ pe ọmọ ọba ni oun

Araba Ifyemi ni o se pataki ki wọn ni ẹkọ, ni ifarada ati lati mọ mọ bi aye se ri odi keji, sugbọn nigba miiran ko ni kọ ọgbọn ti o yẹ ki o ni ti o ba dagba si aafin.

Bakan naa lo fi kun pe kii ṣe gbogbo arẹmọ ni yoo jọba nitori naa ko le joko si oju lati maa reti pe oun ni yoo jọba.

Nitori naa ti o ba to asiko, awọn ijoye kan ti wa laafin ti o ba to asiko ti o yẹ ki o jẹ, Awọn arọkin ati opitan ni yoo wa lati kọ ẹni ti o ba yẹ ki o jọba.

Fun idi eyi ko ti si ẹni ti o mọ boya ọba yoo si kan arẹmọ ọba ile Ife lọla.

Kiní yóò sẹlẹ̀ si Àrẹ́mọ Ọ̀ọ̀ni Ile-Ife ti wọn ba gbé é kurò l'Áàfin

Oríṣun àwòrán, Sileokunola/instagram