Notable Deaths in 2021: Soun Ogbomoso, Orisabunmi, Dudu Heritage, Baba Suwe, Timothy Adegoke àti àwọn ikú mìí tó milẹ̀ lọ́dun 2021

Awọn eeyan nla to jade laye

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awaye ma ku ko si,gbogbo wa naa la n pada bọ wa dagbere faye bo pẹ bo ya.

Bi a ba ṣe n ranti pe ọdun 2021 ti wa o si ti n lọ, bẹẹ la o maa ṣe iranti awọn eeyan to dagbere faye lọdun yi.

Nilẹ kaarọ o jiire ati lorileede Naijiria lapapọ awọn iku awọn eeyan kan milẹ to si gba omijẹ loju awọn araalu.

Awọn taa n wi yi ko ipa ribiribi nigba ti wọn wa laye koda awọn mii, ọna ti wọn gba ku lo jẹ ohun tawọn eeyan fi n ṣe iranti wọn.

Diẹ ree ninu wọn:

Wolii TB Joshua

Wolii TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Pius Utomi Ekpe

Oludasilẹ ijọ Synagogue Church of All Nations dagbere faye lọjọ Karun un oṣu kẹfa ọdun 2021 lẹyin to pari eto isin kan nile ijọsin rẹ lEko.

Ọpọ ni iroyin iku rẹ sọ sinu ibanujẹ tawọn miran ko si gba pe lootọ lo dagbere faye.

O ku ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọta,ọsẹ kan lo ku ti yoo fi ṣe ọjọ ibi rẹ to yẹ ko waye lọjọ Kejila oṣu Kẹfa.

Àkọlé fídíò, Prophet Hezekiah New Year Prayer: Gbogbo wa ni ká ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè Naijiria
Àkọlé fídíò, Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì àti Kàyéfì tó wáyé lọ́dún 2021 rèé nínú fídíò
2px presentational grey line

Pasitọ Dare Adeboye

Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Pst Dee

Ọmọ bibi Pasitọ Enoch Adeboye to jẹ oludari ile ijọsin Redeemed Christian Church of God [RCCG] ni Pasitọ Dare Adeboye jẹ

Nigba aye rẹ, oun ni alakoso ẹka ile ijọsin naa kan to wa ni Abuja.

Ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrin oṣu Kaarun ọdun 2021 lo dagbere faye lẹni ọdun mejilellogoji.

Awọn gbajumọ oṣere tiata ati akọrin to ki duniyan pe o digba

Aworan osere

Lagbo oṣere tiata ati orin kikọ, iku yọwọ awọn eeyan jankan jankan lawo.

Iku ogbontarigi oṣerebinrin ere Yoruba ati ede Gẹẹsi Rachel Oniga jẹ ọkan ninu wọn.

O jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọta niile iwosan kan nilu Eko.

Mọlẹbi rẹ ṣapejuwe iku rẹ gẹgẹ bi amuwa Ọlọrun ti wọn si lo gbe igbe aye rere.

Rachel Oniga nikan kọ lo ṣebẹ gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra,ninu ọdun yi naa ni gbajugbaja oṣere tiata Naijiria Iyaafin Folake Aremu tọpọ mọ si Orisabunmi.

Iku tiẹ yi jẹ kayefi nitori pe o ṣebi ẹni jọ akufa nitori laarin igba diẹ si ara wọn, Orisabunmi, ẹgbọn rẹ ọkunrin ati aburo rẹ obinrin ni wọn jade laye.

Orisabunmi, ẹgbọn ati aburo rẹ

Oríṣun àwòrán, Bukola Janet

Nkan bi ọjọ meloo kan lẹyin iku rẹ, ẹgbọn rẹ Steve Onisola ati aburo rẹ Janet Ademola naa ku ni ṣiṣẹntẹle.

Babatunde Omidina

Iku doro to si da ẹrin mọ ẹnu adẹrinposonu ilumọọka nii Baba Suwe ninu ọdun 2021.

Fọnran fidio ati ikede ikur lati ọwọ ọmọ r lawọn eeyan kọkọ ri, nigba ti ilẹ yoo fi ṣu iroyin ti kan pe ọkọ Moladun kẹnkẹlẹwu ti dagbere faye.

Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Baba Suwe: Àwọn ǹkan ti ọ̀pọ̀ ko mọ nípa Baba Suwe

Ọpọ oṣere ati awọn ololufẹ lo kẹdun iku Babatunde Omidina to si ṣe pe ko fẹẹ si iroyin mii tawọn iwe iroyin n gbe lasiko yi ju tiẹ lọ.

Ọjọ Kejilelogun oṣu Kọkanla ni Baba Suwe fayue silẹ lẹni ọdun mẹtalelọgọta.

2px presentational grey line

Soun Ogbomoso, Oba Oyewumi Ajagungbade Kẹta,waja

Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ni aarọ ọjọ Aiku,ọjọ kejila, oṣù Kejila, odun 2021 ni a gbọ pe Soun ti lọ ba awọn baba nla rẹ lọrun aremọbọ.

Gẹgẹ bi musulumi, ni irọlẹ ọjọ Aiku yii naa ni wọn sin Oba Oyewumi ni ilana ẹsin musulumi.

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ̀ ipò tí ìlú Owo l'Ondo ní lórí ìtẹ́ Ile Ife? Ẹ kálọ sí ìlú mi

Ọpọ awọn eeyan jankan jankan lo peju pesẹ si ibi eto isninku naa.

Inu aafin adateba ilu Ogbomoso ni wọn si Soun si.

Dudu Heritage

Dudu Heritage

Oríṣun àwòrán, others

Opọ awọn eeyan ni wọn ṣe idaro Ola Ibironke to jẹ oludari Dudu Heritage to doloogbe.

Koda awọn akẹgbẹ Bimbo Oshin to jẹ oṣere fiimu Yoruba lọ si ile wọn ni agbegbe Bodija nibadan.

Ara ore ojulumọ pejọ pọ lati kedun iku rẹ. O jẹ ẹni to n ba awọn eeyan gbe orin jade.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Timothy Adegoke

Iku Timothy Adegoke, akẹkọọ gboye imọ kun imọ Masters degree ni ileẹ̀kọ́ giga fasiti OAU nilu ile ifẹ jẹ eyi to mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Ile itura kan taa mọ si Hilton Hotel nilu Ile ifẹni wọn lo lọ kẹyin ki wn to ri oku rẹ ninu igbo.

Ọrọ yi titi di asiko taa wa yi ko ti ni iyanju.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

Awọn mọlẹbi Timothy n fojojumọ ke gbajare koda awọn ọmọ ilu r naa ko dake lori ọrọ yi.

Awọn afurasi kan ti wa ni ahamọ ọlọpaa ti ireti si wa pe wọn yoo ri ọrọ yi yanju laipẹ yi.