Orisabunmi: Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ ò! Lẹyìn ikú ẹ̀gbọ́n Orisabunmi, àbúrò rẹ̀ tún jáde láyé

Oríṣun àwòrán, thenewstrack.com.ng
Awọn mọlẹbi oserebinrin tiata Naijiria, Orisabunmi, ti tun wa ninu ẹkun ohun ibanujẹ ni kopẹ-kopẹ ti wọn padanu ẹgbọn Orisabunmi, iyẹn alagba Steve Onisola.
Lọsan ọjọ Abamẹta ni arabinrin Bukola Janet Ademola, to jẹ aburo abikẹyin fun iya Orisabunmi naa jade laye.
BBC Yoruba fidi ọrọ yi mulẹ lati ẹnu ọkan lara awọn to sunmọ arabinrin Bukola Janet, wolii ajihinrere Obaloluwa Hephzibah.
Ninu alaye rẹ, Wolii Hephzibah ni ọdọ arabinrin Janet ni oun gbe dagba.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Hephzibah
Koda o sọ pe ọpọ eeyan lo maa n pe oun ni akọbi Janet Bukola.
Hephzibah ni iku arabinrin Bukola Janet jẹ nkan ti o fọwọ kan ni lẹmi, to si ba ni lojiji pẹlu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- August Agboola Brownie, ọmọ Yorùbá tí wọ́n n wárí fún ní Poland
- "Ìbejì ní wá ṣùgbọ́n àyẹwò fí hàn pé baba ọtọ́ọ̀tọ̀ ló bí wà"
- Wo ìdí tí Alaafin fi ṣún ayẹyẹ àádọ́ta ọdún tó gorí ìtẹ́ síwájú
- Buhari, pa ìtìjú mọ́ra láti sanwó fáwọn ajaguntà tí yóò kojú Boko Haram - Soyinka
- Sójà àti awakọ̀ fìjà pẹ́ẹ́ta nítorí ọgọ́rùn náírà, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sòfò
- Agbẹjọ́rò àgbà ní Nàìjíríà ti pàsẹ kí wọ́n dáwọ́ ètò ìgbanisíṣẹ́ NDLEA dúró
- Njẹ́ o mọ̀ pé àṣírí rẹ kò bò mọ́ lórí Whatsapp nítorí ìlànà tuntun tí wọ́n gbé síta?
- Nǹkán márùn ún tó yẹ ko mọ̀ nípa Elon Musk, bàbá olówó tó lówó jùlọ lágbàáyé
- Yollywood: Kìí ṣe gbogbo ìgbéyàwó ló ń túká nítorí àgbèrè – Mide Martins
''Wọn ku lọsan ana. Ẹni to si ku lana yẹn lo tọ emi dagba. Ọdọ wọn ni mo gbe dagba.
Aburo Orisabunmi ni wọn jẹ. Awọn ni abikẹyin mama to bi Orisabunmi."

Oríṣun àwòrán, Facebook/Janet Bukola
Nigba ti BBC Yoruba beere lọwọ Hephzibah nipa iroyin to n ja pe Covid-19 lo ṣokunfa iku arabinrin Bukola Janet, o ni awọn ko ro bẹẹ.
''Kii ṣe Corona. A le pe ni ''shock'' ati pe wọn ni Hypertension ti eleyi si n ba wọn finra tẹlẹ.''
Oniṣẹ aṣerun lọṣọ toloyinbo n pe ni Hairdresser ni arabinrin Janet Bukola jẹ nilu Ibadan.
Ọjọ Kejila Osu Keji ọdun yii ni arabinrin Bukola Janet ko ba pe ẹni ọdun mẹtalelaadọta gẹgẹ bi Wolii Hephzibah ti ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Orisabunmi
Lakotan Hephzibah sọ fun BBC pe ilu Ibadan ṣi ni oku arabinrin Janet wa.
"Ko ti daju igba ti wọn yoo sin nitori oku ti Oriṣabunmi to jẹ ẹgbọn ati ẹgbọn wọn agba, Steve Onisola ṣi wa nilẹ bayi, ti awọn mọlẹbi ko ti kede igba ti wọn yoo sin wọn."
Lara awọn ẹbi to ṣẹku fun arabinrin Janet bayii ni ẹgbọn rẹ obinrin Alhaja Abiodun Dan Kazeem to jẹ iyawo sọrọ sọrọ Adeniyi Dan Kazeem.
Ẹ̀gbọ́n Orisabunmi kú lẹ́yìn ọjọ́ méjì tó jáde láyé

Saaju la ti sọ fun yin pe iroyin iku ẹni to jẹ ẹgbọn si gbajugbaja oṣere ere tiata Folake Aremu, Orisabunmi, ti desi eti igbọ wa.
Ẹgbọn rẹ yi, Steve Onisola jẹ oludari ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ awọn obinrin ni Kwara,Kwara Falcons Basketball Club nigba aye rẹ.
Alaga ẹgbẹ awọn to n gba bọọlu alapẹrẹ ni Kwara Dokita Joseph Adeyemo lo fidi ọrọ yi mulẹ fawọn akọroyin lọjọbọ.
Gẹgẹ bi ohun taa gbọ, ko pe wakati mẹrinlelogun sigba ti Oriṣabunmi jade layi ti Onisola tii ṣe ẹni ọdun mọkanlelaadọrin ki duniya pe o digbere.
Oniṣola ti fi igba orisirisi jẹ alakoso ẹgbẹ Falcons ki wọn to wa yan sipo oludari eto ẹgbẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook/steveolaniyi.onisola
O wa lara awọn to ṣapa ti ẹgbẹ naa fi gba agbega si abala liigi to gajulọ ni ọdun 2013.
Bakan naa lo jẹ ọkan lara awọn to gba ami ẹyẹ fadaka nibi idije liigi Kwese lọdun 2018.
Onisola jẹ ọkan lara awọn akọnimọọgba akọkọ ẹgbẹ naa ti wn da silẹ laarin ọdun 1970-80

Oríṣun àwòrán, Facebook/steveolaniyi.onisola
O tun jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ bọọlu alapẹrẹ ni ipinlẹ Kwara ṣaaju iku rẹ.
Adeyemọ ṣapejuwe iku rẹ gẹg bi eyi to fọwọkan ẹmi awọn elere idaraya ati mọlẹbi rẹ nipinlẹ Kwara.
















