Ilesha Baruba: Ìjọba ìpińlẹ̀ Kwara bá ẹbi àwọn tó sòfò ẹ̀mí kẹ́dùn ni Baruteen

Ìjọba ìpińlẹ̀ Kwara bá ẹbi àwọn tó sòfò ẹ̀mí kẹ́dùn ni Baruteen

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gómínà ìpińlẹ̀ Kwara AbdulRahman Abdulrazaq ti bá ẹbí àti ọ̀rẹ́ àwọn tó kú ni ọjọ́ Ẹtì nínú ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ni Ilésha Baruba láàrín ará ìlú àti ikọ̀ ọmọogun aṣọ́bode níbẹ̀.

Gómìnà bá, Emir ilú Ilesha Baruba ọjọgbọ́n Halidu Abubakar àti ẹbi àwọn tí ẹ̀mí wọ́n sọnù nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà kẹ́dun nínú àtẹ̀jáde ti àkọ̀wé ìròyìn gómínà Rfafiu Ajakaye fọ́wọ́sí.

Ó rọ gbogbo ará ìlú láti fọkàn bálẹ̀ àti pé ìjọba yóò ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà lẹ́kùnrẹ́rẹ́.

Kíló fa wàhálà náà?

Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ lọ́jọ́ Jímọ láàrìn àwọn olùgbé Ilesha Baruba níjọba ìbílẹ̀ Baruteen, ìpínlẹ̀ Kwara àti àwọn ọmọọgun tó n sọ ibode lágbègbè náà.

Wọ́n ni ìjà náà bẹ́ sílẹ̀ nítori owó tí àwọn ọlọ́kọ̀ máa n san ti wọ́n bá fẹ́ gbe ìrẹsì wọ inú ọja Sinawa tó wà ni ìlú Ilésha Baruba.

Ìròyìn sọ pé, awakọ̀ kan ló fún ọkan nínú àwọn ọmọogun náà ni owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ọgọ́rùn náìrà nígbà tí ó fẹ́ wọ inú ọjà, sùgbọ́n tí ó kọ̀ láti sa òmíràn nígba tó fẹ́ jáde kúrò nínú ọjà náà.

Àwọn ti ọ̀rọ̀ náà sojú ni, bí awakọ̀ náà ṣe kọ̀ láti san owó òun ti ọmọogun ọ̀hún si fọọ léti, ó ní ko máa fò bi ọ̀pọ̀lọ́, bákan náà ló tún tún gba ọkọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

Èyí ló fàá ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ̀ tọ kù fi tẹ̀lé awakọ̀ náà láti lọ bá àwọn sójà ọ̀hún sọ̀rọ̀, "ibi tí a ti ń tí sọ ọ́ ni gbọmísí omí-òtó ti bẹ̀rẹ̀, ọmọogun kan sì yin àwọn awakọ níbọ̀n, ènìyàn mẹ́ta ló kú lójú ẹsẹ̀, tí àwọn méjì sì padà kú nílé ìwòsàn.

Agbẹnusọ ọlọ́paàá ìpińlẹ̀ Kwara, Ajayi Okasanmi tó fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ sàlàyé pé, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara ti bẹ̀rl ìwádìí.

Bákan náà ló fi kun pé, gbogbo ǹkan ti pada bọ̀ sípò níbẹ̀ báyìí.