Covid-19: Ìdí ti Malami fi ni ki NDLEA dáwọ́ ètò ìgbanísíṣẹ́ dúró náá

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Agbẹjọ́rò àgbà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó tún jẹ́ mínísítà fún ètò ìdájọ́ Abubakar Malami ti kàns í àjọ tó n gbógun ti lílò àti títà òògùn olóró ni Nàìjíríà NDLEA láti dáwọ́ ètò ìgbani ṣíṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún márun dúró.
Sáájú ni ìròyìn sọ pé, àjọ NDLEA ti gbé orúkọ àwọn ẹgbẹ̀rún márùn tó ti ṣe àṣeyege fún ìgbànisíṣẹ̀ náà jáde.
Àjọ náà sì tún kéde pé àwọn tó ṣe àṣeyege náà ní láti péjú sí ẹ̀ka tó n ri si ìkọ́ni ní ilé ìṣẹ́ náà ní ìlú Jos láti láti yanjú ètò ìgbànisísẹ́ wọn.
- Ọkọ̀ bààlú tó gbéro àádọ́ta pòórá lẹyìn tó gbéra láti Jakarta
- Njẹ́ o mọ̀ pé àṣírí rẹ kò bò mọ́ lórí Whatsapp nítorí ìlànà tuntun tí wọ́n gbé síta?
- Ẹ gbà mí o, wọ́n ti ń fi kóló mi kó àwọn èèyàn lómi ọbẹ̀ jẹ- Tawa Ajisefinni
- COVID-19 pa èèyàn mọ́kànlá láàrín ọjọ́ méjì, ènìyàn 1565 míràn tún ko lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní Nàìjíria
Sùgbọ́n, ọgbẹ́ni Malami kéde lọ́jọ́ Eti, ti ṣe ọjọ́ kẹjọ oṣù kíní, ọdún 2020 pé kí, àjọ NDLEA fagilé ètò ìgbanisíṣẹ́ náà láti le bọ̀wọ̀ fún ìlàna àlàálẹ̀ Covid-19.
Orílè-èdè Nàìjíríà ń kojú ọwọ́jà kejì àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19 ti iye ènìyàn tó n ni ààrùǹ náà sì n peléke si lójoojúmọ́ láti bi osù kan sẹ́yìn.
Ó ní láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ààrun náà ìjọba àpapọ̀ tí ni kò sí ààyè fún ìpéjọpọ̀ elérò púpọ ti o sì ti pasẹ ki gbogbo ilé ijó àti ilé ọti wà ni títì pa náà.
Lórí ti ètò ìgbànisíṣẹ́ NDLEA Malami ti rọ akọ̀wé àgbà ilé isẹ́ to n ri si ètò ìdájọ́ láti wádìí ìgbésẹ̀ tó kan láti ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lórí Covid-19 ti ààrẹ Buhari yàn, pàápàá jùlọ lórí ọ̀nà ti àwọn ]en]iy]an ẹgbẹ̀rún márun yóò gbà láti ṣe ètò náà tí kò sí ni dá wàhálà sílẹ̀ lórí ìlerà ọladani.











