Indonesia Sriwijaya Air: Ọkọ̀ bààlú tó gbéro àádọ́ta pòórá lẹyìn tó gbéra láti Jakarta

Ọkọ̀ bààlú tó gbéro àádọ́ta pòórá lẹyìn tó gbéra láti Jakarta

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọkọ baalu kan to gbe eeyan aadọta lati olu ilu Indonesia,Jakarta, la gbọ pe o ti di awati.

Baalu Sriwijaya Air Boeing 737 gẹgẹ bi awọn alaṣẹ se sọ di awati lasiko to n lọ si Pontianak ni iwọ oorun agbegbe Kalimatan.

Oju opo Flightradar to n tọ pipin irinajo awọn baalu sọ pe laarin iṣẹju kan to poora, niṣe ni o ti dẹnu kọlẹ niwọn ẹgbẹrun mẹta mita(10,000ft)

Ileeṣẹ irinna orileede naa s pe awọn ti bẹrẹ si ni ṣe iwadii lati ṣawari baalu naa.

Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Sriwijaya Air sọ pe awọn ṣi n ṣe akojọ iroyin nipa baalu naa.

Baalu eleyi yatọ si 737 Max to jabo ninu ijamba ofurufu meji kan to waye laipẹ yi.

Ni ọdun 2018 ni ijamba akọkọ to waye ti eeyan 189 si padanu ẹmi wọn nigba ti baalu Lion Air kan ja si okun.