Moscow Plane Crash: Ìjàmbá ọkọ̀ bàálu pa arìnrìǹàjò 41

Oríṣun àwòrán, AFP
Eniyan mọkanlelogoji lo ti re salakeji lẹyin ti ọkọ baalu kan ṣaa dede gbina lẹ́yìn to gunlẹ pajawiri ni papakọ ofurufu Sheremetyevo ní ilẹ̀ Moscow.
Fọnran to wa kaakiri ẹrọ ayelujara ṣafihan awọn arinrinajo ti wọn n gba ọna àbùjá ọkọ baalu naa lati sa asala fun ẹmi wọn ninu baalu Aeroflot.
Awọn ile iṣẹ iroyin orilẹede Russia jabọ pe ọmọde meji ati oṣiṣẹ inu baalu kan wa lara awọn to ba iṣẹlẹ naa rin.
Eniyan kan ti iṣẹlẹ na ṣoju ẹ ni "iyanu nla lo jẹ" fun ẹni ti ori ba yọ ninu baalu naa to gbe arinrinajo mẹtaleaadọrin ati oṣiṣẹ marun.
"Eniyan mẹtadinlogoji lori yọ - arinrinajo mẹtalelọgbọn ati oṣiṣẹ mẹrin" lohun ti ọkan lara awọn igbimọ aṣewadii, Yelena Markovskaya sọ. Eniyan marun si ti wa nile iwosan bayii.
Iroyin to hande ni wi pe wọn pa a laṣẹ ki ọkọ baalu Aeroflot ti orilẹede Russia pada si papakọ ofurufu nitori iṣoro to nii ṣe pẹlu ọkọ naa.
Iroyin miiran sọ pe ẹrọ ọkọ baalu naa ran ina loju ọna to ti n ba lẹyin to fi agbara kaka ba. Wọn igbiyanju lati kọkọ́ ba rẹ ko yọri si rere.
Ẹni ori yọ o di'le
Mikhail Savchenko to ni oun jẹ ọkan lara awọn arinrinajo ni oun wa ninu ọkọ baalu naa nigba to gbina oun si tiraka lati "bẹ sita".
O fi fọnran awọn arinrinajo to n sa kuro nibi ọkọ to n jona sita to si kọ akọle pe "ẹyin ara, alafia ni mo wa o ati ara pipe".
Arinrinajo mii to ye e, Dmitry Khlebushkin sọ wi pe oun dupẹ pupọ lọwọ awọn oṣiṣẹ inu ọkọ baalu naa.
Ẹlomiiran ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ sọ fun BBC pé "o ba mi lojiji lati ri ọkọ baalu naa bo ṣe gbina ni iṣẹju perete to yẹ ki oun wọ ọkọ baalu mii lati rinrin ajo".
Ẹwẹ, iroyin sọ pe aarẹ orilede Russia, Vladmir Putin ti gbọ si i o si ti ba awọn ẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa rin kẹdun.













