Ethiopian Airline crash: Àbájáde ìwádìí ọkọ̀ bàálù Ethiopia wẹ awakọ̀ bàálù mọ̀ ọ́

Baalu Ethiopian Airline

Oríṣun àwòrán, Ethiopian Airline

Àkọlé àwòrán, Baalu naa ko eero mọkandinlaadọjọ, to fi mọ awọn oṣiṣẹ baalu mẹjọ.

Ileeṣẹ igbokegbodo ọkọ lorileede Ethiopia ti fi esi abajade awọn iwadi ti wọn kọkọ ṣe nipa ọkọ baalu Ethiopia Airline 302 to ja loṣu to kọja.

Iwadi naa fi han pe awakọ baalu na tẹle gbogbo ilana ti Boeing to ṣe baalu na ni ki wọn tẹle.

Eeyan mẹtadinlọgojọ lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Mo ń retí láti ọ̀dọ̀ bàbá mi nígbà tí mo gbọ́ pé ó bá ìjàmbá bàálù lọ

Dagmawits Moges to jẹ Minisita fun eto irinna sọ fun awọn akọroyin pe gbogbo iwe aṣẹ to yẹ ki baalu naa ni, ni o ni, ti awọn ti o si wa ọkọ ofurufu ọhun tẹle gbogbo ilana to yẹ. Ṣugbọn baalu naa papa jabọ.

Isẹlẹ ọkọ ofurufu to ja yi ti mu ki awọn orilẹede kaakiri agbaye dawọ lilo ọkọ ofurufu Boeing 737 duro nitori pe baalu iru rẹ meji lo ja laarin oṣu maarun sirawọn.