Isẹlẹ Iran: Ijamba baalu pa eeyan 66

Oríṣun àwòrán, Konstantin von Wedelstaedt
Awọn osisẹ ileesẹ baalu kan lorilẹede Iran ti sọ wipe eeyan mẹrindinladọrin lo jẹ Ọlọrun nipe ninu baalu kan to jabọ l'orilẹede Iran.
Baalu ileesẹ Aseman, eleyi to n lọ si igboro Yasuj to wa ni guusu iwọ-orun ilẹ naa lati Tehran, jabọ laarin awọn oke Zagros ti wọn wa laarin-gbun-gbun Iran.
Ẹgbẹ alaanu Red Crescent ton se iranlọwọ pajawiri ti tari awọn adoola ẹmi lọ sibi ti isẹlẹ naa ti waye lẹba igboro Semirom nipinlẹ Isfahan.

Osisẹ kan l'orilẹede naa so wipe, kuru-kuru oju-ọjọ ko jẹ ki wọn le lo ọkọ baalu aba-sibi-o-ri, lati fi s'awari ibi tisẹlẹ naa ti waye.
Ọgọta ero, ẹsọ meji, osisẹ baalu meji ati awakọ ofurufu meji lo wa ninu baalu naa
Agbẹnusọ kan sọ wipe: "Wọn ti ta gbogbo awọn osisẹ iranwọ pajawiri ji lati wa ni sẹpẹ."
Wọn ni awọn nigbagbo wipe, baalu naa jẹ irufẹ baalu ATR 72-500 to ti lo to ogun ọdun.
Iroyin sọ wipe awọn to wa ninu baalu na jẹ ogota ero, ẹsọ meji, osisẹ baalu meji ati awakọ ofurufu meji.








