Abiola Ajimobi: Iku Ajimọbi jẹ́ ǹkan ìjayà nítori kò só sí ẹnìkan tó ń reti irúẹ̀ lásìkò yii
Ṣẹnetọ to ṣoju aringbungbun Ọyọ, "Oyo Central Senatorial District", Teslim Folarin lo ko awọn akẹgbẹ rẹ marun un mii ṣodi lati lọ ba wọn kẹdun nile gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Ṣẹnetọ Abiọla Ajimọbi to di oloogbe.Ni ọsan ọjọ Abamẹta ni awọn aṣofin naa abẹwo si ile Ajimọbi to n bẹ ni agbegbe Oluyọle niluu Ibadan.Lara awọn aṣofin naa ni Sẹnetọ Abdulfatai Buhari to n ṣoju ẹkun ariwa ipinlẹ Ọyọ,

Oríṣun àwòrán, @Ajimobiinstagram
"Oyo North senatorial district" nile igbimọ aṣofin agba, Họnọrebu Shina Abiola Peller, Họnọrebu Akeem Adeniyi Adeyemi ati Otunba Akin Alabi.
Wọn ti ọwọ bọ iwe lati ṣe idagbere ikẹyin fun goimina Ọyọ tẹlẹri bẹẹ sini wọn ba awọn ẹbi rẹ kẹdun.Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ nile oloogbe, Sẹnetọ Tẹslim Fọlarin ṣe alaye iku Ajimọbi je nnkan ijaya nitori ko si ẹnikan ti o ni ireti pe iru ẹni to o da pe bẹẹ le dede jade laye, ṣugbọn o fi ọpẹ fun Ọlọrun fun igbe aye rere ti oloogbe gbe.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ abiola ajimobi
O ṣe apejuwe Ajimọbi gẹgẹ bi ẹnikan ti o da yatọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ ti o si ni igboya. Fọlarin tẹsiwaju wi pe yoo nira lati di alafo ni iku Ajimọbi ṣi silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC l'apapọ.Ninu ọrọ tiẹ, Sẹnetọ Abdulfatai Buhari ni gbogbo nnkan patapata ni Ọlọrun fun oloogbe, Ṣẹnetọ Abiọla Ajimọbi ni igbesi aye rẹ.O ni ko si ẹni ti ko ni aleebu tiẹ lara, ṣugbọn daadaa Ajimọbi tayọ ohun ti awọn eeyan le maa wo lara rẹ gẹgẹ bii aleebu.

Oríṣun àwòrán, Ajimobi
O tẹsiwaju wi pe, " Emi ṣiṣẹ labẹ wọn gẹgẹ bii Kọmisana n'igba ti wọn ṣe ni ti alakọkọ. A dupẹ fun Ọlọrun loriii awọn nnkan pupọ ti Ọlọrun loo fun oun naa ni awa naa n jẹ loni.Ki Ọlọrun Ọba alaanu ki o ba wa ṣe iku ni isinmi fun un."Họnọrebu Shina peller, Họnọrebu Akeem Adeniyi Adeyemi ati Alhaji Kunle Sanni ti o jẹ alaga awujọ awọn Musulumi ni fasiti ilẹ Ibadan naa ko gbẹyin ninu ipejọpọ awọn abanikẹdun ti o fi irobinujẹ wọn han lorii ipapoda gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Ishaq Abiọla Ajimọbi.Awọn ṣoju ijọba, oloṣelu ati lẹgbẹlẹgbẹ naa pẹlu awọn fi o fi ara han lati t'ọwọ bọ iwe idagbere ikẹhin fun oloogbe.
Abiola Ajimobi: Gómìnà kòṣẹlẹ̀rí àkọ́kọ́ tó fi ọba 21 jẹ lọ́jọ́ kan ṣoṣo nílẹ̀ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Instagram/ abiola ajimobi
Abiola Ajimobi, Gómìnà tí ọ̀rọ̀ kìí kú mọ lára, à fi kó fèsì
Iku pa Abírí, Abírí ku, iku pa Abìrì, Abìrì rọrun, iku pa akọ̀kọ́, omi akọ̀kọ́ danu, ko si ẹni ti ko ni ku, ko si ẹni ti oko baba rẹ ko ni di igboro.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu adele alaga ẹgbẹ oselu APC, tii tun ṣe gomina ana nipinlẹ Oyo, Ṣẹnetọ Isiaka Abiola Akanji Ajimobi to dagbere faye lasiko aisan ranpẹ.
Ajimobi, ẹni tii ṣe onimọ nipa oko-owo epo rọbi ati oloselu to dantọ ṣe gudu gudu meje ati ya ya mẹfa nigba aye rẹ,
Idi si ree ti BBC fi ṣe akojọpọ igbe aye agba oselu naa ati awọn ohun ribiribi to gbe ile aye ṣe.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ajimobi
Itan igbe aye Abiola Ajimobi:
Ọjọ nla ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun 1949 ti alagba Ganiyu Ajimobi ati aya rẹ, Sikiratu Abeje bi Isiaka Abiola Akanji sile aye.
Agboole Ajimobi ni adugbo Ọja Ọba nilu Ibadan, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo, ni Abiola ti jade wá.
O lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ Patrick Mimọ ladugbo Oke Paadi nilu Ibadan amọ O pari ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ ni ile ẹkọ Ibadan City Council, ICC Orita Aperin nilu Ibadan.
Bakan naa ni Abiola morile ile ẹkọ girama Lagelu ladugbo Agugu nilu Ibadan feto ẹkọ oniwe mẹwa rẹ, to si gbajumọ bii isana ẹlẹẹta ninu ere idaraya,
Idije bọọlu ẹlẹyin ori tabili, bọọlu afẹsẹgba, to si jẹ adari akẹkọọ feto ere idaraya.
Ẹkọ iwe lo tun sọ Abiola silẹ Amẹrika, to si lọ gba oye imọ ijinlẹ nipa akoso okoowo nile ẹkọ fasiti New York to wa ni Buffalo, níbi to ti gba oye imọ ijinlẹ ninu imọ sayẹnsi.
Abiola ko duro lori eyi, o tun tẹsiwaju lati gba oye imọ ijinlẹ keji ninu iṣẹ iwadii ati kata-kara ni Governors state University to wa ni University Park, Illinois nilẹ Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiola ajimobi
Iṣẹ ti Ajimobi yan laayo:
Yoruba ni ajo ko dabi ile nitori ile labọ sinmi oko, idi ree ti Abiola Ajimobi fi pada wa sile, to si ri iṣẹ pẹlu Ileesẹ elepo rọbi kan National Oil eyi to wa labẹ Ileesẹ elepo rọbi Shell,
Nibẹ, to si sun kẹrẹ-kẹrẹ de ipo oludari agba fun Ileesẹ naa.
Lẹyin to sin Ileesẹ National Oil fun ọdun mẹrindinlọgbọn gbako, Abiola fẹyinti nileesẹ naa, to si dara pọ mọ eto iselu to wa ninu ẹjẹ rẹ nitori ile lo ba a.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Abiola Ajimobi
Ipo oselu ti Ajimobi dimu:
Baba Abiola, Ganiyu jẹ oloselu to gbajugbaja, to si dibo wọle sile asofin ẹkun ìwọ oorun Naijiria ijọhun laye saa isejọba alagbada kinni,
Ti aburo baba rẹ naa si jẹ Minisita fun isẹ ode ati igbokegbodo ọkọ nigba naa.
- Ayefele fi orin ẹ ṣeun sẹ́nu kí Ajimobi
- Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti ní Ajimobi létọ̀ọ́ láti yan ọba l’Ọyọ
- Seyi Makinde, bàtà tí Ajimobi bọ́ sílẹ̀ ni ko tẹsẹ̀ bọ̀ fún àṣeyọrí Ọyọ - APC
- Arisekola ló fún mi ní ilẹ̀ tí ìjọba Ọyọ gbẹ́sẹ̀ lé, ń kò ní gbà - Ajimobi
- Mí ò bẹ̀bẹ̀ fún oyè igbákejì alága APC kí wọ́n tó ó fún mi - Abiola Ajimobi
Lọdun 2003 ni Abiola dibo sile asofin agba labẹ ẹgbẹ oselu Alliance for Democracy AD, to si wọle lati soju ẹkun idibo guusu ipinlẹ Oyo, to si ṣe ọdun mẹrin gbako nibẹ.
Lẹyin naa lo tun gbinyanju lati du ipo gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2007 labẹ ẹgbẹ oselu ANPP, amọ, to fidi rẹmi,
Ṣugbọn wọn ni ẹṣin kii da ni, ka ma tun un gun, Abiola tun gbinyanju lẹẹkan si lati du ipo gomina losu kẹrin, ọdun 2011, to si yege.

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiola ajimobi
O fi ẹyin gomina to wa lori aleefa nigba naa, Otunba Christopher Adebayo Alao Akala janlẹ lati gbegba oroke, to si fi ibo perete moke ninu ibo naa.
Yoruba ni aidun ọsan la a mu mejila, bi ọsan ba dun, eeyan yoo mu igba.
Eyi lo mu Abiola du ipo gomina ni ẹẹkan si fun saa keji, to si tun wọle pada bii gomina ipinlẹ Oyo, eyi ti ko sẹlẹ rí ninu itan oselu ipinlẹ naa.
Idi si ree ti ọpọlọpọ eeyan fi n pe e ni Gomina Kosẹlẹri nitori oun ni ẹni akọkọ ti yoo wọle fun ipo gomina ni saa keji ninu itan oselu ipinlẹ Oyo, nitori saa kan pere ni awọn gomina to wa niwaju rẹ ṣe.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ Ajimobi
Aseyọri ati akude Ajimobi bii gomina ipinlẹ Oyo:
Lasiko ti Abiola Ajimobi wa lori aleefa bii gomina nipinlẹ Oyo fun odindi ọdun mẹjọ gbako, ọpọ aseyọri ati iṣẹ ribiribi lo ṣe lori aleefa,
Eyi je ki aimọye iṣẹlẹ Kosẹlẹri ni rere si waye nipinlẹ Oyo ni saa isejọba ọlọdun mẹjọ rẹ.
Lara awọn aseyọri rẹ bii gomina ni lila ọpọlọpọ opopona tuntun ati atunse awọn oju popo ti ko dara jakejado ipinlẹ Oyo eyi to to igba,
Atunse ati bibu ẹwa kun ayika ipinlẹ Oyo,
Kíkọ afara abẹyẹfo to wa ni Mokola nilu Ibadan, gbigba awọn ọdọ ti ko niṣẹ lọwọ bii osisẹ Yes-O, rira ọkọ pẹlu kẹkẹ Ajumọse ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lara awọn aseyọri Kosẹlẹri ti Ajimobi ṣe lori aleefa, ni agbekalẹ ofin atunto oye jíjẹ nilẹ Ibadan, to si fi ọba mọkanlelogun jẹ nilẹ Ibadan ni ọjọ kan ṣoṣo,
Eyi ti okiki rẹ gbalẹ kan, ti awuyewuye igbesẹ rẹ yii ko si jẹ ki ilana oye jijẹ nilẹ ni ojutu titi di oni yii.

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiola ajimobi
Ajimobi maa n fi ọwọ sọya ni ọpọlọpọ igba pe oun ni Gomina to tii ṣe aseyọri julọ ninu itan ipinlẹ Oyo,
Ati pe oun tun ni gomina ti alaafia to peye ati eto aabo to pegede si jọba nipinlẹ Oyo lasiko isejọba rẹ.
Awọn Awada Ajimobi n kọ?
Ṣugbọn bo ti ṣe aseyọri to lori aleefa, Ajimobi jẹ alawada ọkùnrin, to si maa n fi awada agbekalẹ awọn ọrọ rẹ, eyi ti ọpọlọpọ eeyan maa n si i gbọ, ti ọrọ rẹ si maa n bọ sapo ibinu wọn.
Fun apẹẹrẹ, Ajimobi gba alejo awọn akẹkọọ fasiti imọ ẹrọ Ladoke Akintola nilu Ogbomoso, ti wọn wa fi ẹhonu han lọgba Secretariat,
Asiko yii si lo koro oju si akẹkọọ kan lori bo ṣe sọrọ si bii gomina lọna tí ko yẹ, Ajimobi wa beere pe "Ṣe Aláṣẹ ti ofin gbe kalẹ (Constituted Authority) lo n sọrọ si baun"?
Gbolohun naa fa awuyewuye ati ariwisi laarin ilu, ọpọlọpọ eeyan fara, ti wọn si n pe gomina Ajimobi ni "Mr Constituted Authority" lati igba naa.

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiola ajimobi
Ọpọ eeyan si lo n ṣe apejuwe oloogbe naa bii ẹni ti ọrọ kii ku mọ lara nigba aye rẹ,
Nitori gbogbo ọrọ lo ni esi lọdọ Abiola Ajimobi, to si maa n sọ pe "ọmọ Ibadan ni mi, mo si mọ esi ọrọ".
Ninu idibo ọdun 2019, ti saa keji isejọba Abiola Ajimobi n tẹnu bọ odo lọ, o tun gbinyanju lati dije fun ipo Ṣẹnetọ sile asofin agba,
Amọ ṣe lo fidi rẹmi ninu idije naa, ti Ṣẹnetọ Kola Balogun si jawe olubori.
Lẹyin ti Ajimobi kuro ni ipo gomina, ni ẹgbẹ oselu rẹ, APC tun yan an sipo igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ fun ẹkun ìwọ oorun Naijiria,
Ninu eyi to si tun di adele alaga fẹgbẹ oselu naa ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹfa ọdun 2020.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ajimobi
Iku Abiola Ajimobi:
Amọ o ṣeni laanu pe asiko yii ni agba oselu naa ti wa lori aisan, ti ẹnu si n kun un pe arun Coronavirus lo n ba a finra, bẹẹ ni ko lo ipo naa fun ọjọ kan ṣoṣo, ko to pa ipo da.
Nigba to si jẹ pe aisan lo ṣe e wo, a ri ti ọlọjọ ṣe, Isiaka Abiola Akanji Ajimobi mi kanlẹ nile iwosan kan nilu Eko ni Ọjọbọ, ọjọ Kẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2020, to si ki aye pe o digbose.
Abiola fi aya rẹ, Oloye Florence Ajimobi ati ọmọ marun-un silẹ saye lọ.

Oríṣun àwòrán, Ajimobi
Lara wọn ni Idris Ajimobi, to fẹ ọmọbinrin Gomina Abdullahi Ganduje tipinlẹ Kano ni aya pẹlu Abisola to fẹ ọmọ Oloye Kola Daisi, tii ṣe gbajugbaja olokoowo ni ọkọ.
Bi onirese Abiola Ajimobi ko tiẹ fin igba mọ amọ eyi to ti fin silẹ ko le e parun, ti BBC Yoruba si n gbadura pe, ki Ọba oke tẹ agba oselu ati ojulowo ọmọ bibi ilẹ Ibadan naa si afẹfẹ rere.

Oríṣun àwòrán, Ajimobi















