Hajj 2020: Yàtọ̀ sí covid-19, wo ìgbà mẹ́wàá míì táwọn mùsùlùmí kò lè ṣiṣẹ́ Hajj ní Mecca
Eyi kọ ni igba akọkọ ti ijọba orilẹ-ede Saudi Arabia ko ni faye gba ọpọ eeyan lati wa ṣiṣẹ Hajj ni Saudi.
Laipẹ yii ni ijọba ilẹ naa kede pe awọn eeyan lati ilẹ mii ko ni lanfaani lati ṣiṣẹ Hajj fun ti ọdun 2020.
O ti ṣẹlẹ lawọn igba kan sẹyin ti ogun tabi ọrọ oṣelu dena mọ awọn eeyan ti wọn fẹ ṣiṣẹ Hajj.
Lilọ Hajj jẹ ọkan pataki ninu opo to di ẹsin Musulumi mu, wọn si mu u ni ibaada fun gbogbo musulumi lati rii wi pe wọn lọ si Mecca, o kere tan lẹẹkan ki wọn to dagbere faye.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eyi ni awọn igba igba miiran tawọn musulumi ko lanfaani lati ṣiṣẹ Hajj:
1) Okuta dena iṣẹ Hajj ni eyi ti ko si Hajj fun odindin ogun ọdun
Lara awọn igba tawọn musulumi ko le ṣiṣẹ Hajj lo ṣẹlẹ 930, A.D.
Eyi jẹ nigba ti ẹgbẹ Shiite musulumi gan an ti wọn pe ara wọn ni Qarmatians yabo ilu Mecca nitori wọn gbagbọ pe awọn keferi lo n ṣiṣẹ Hajj.
Akọsilẹ sọ pe awọn Qarmatians ṣekupa ọpọlọpọ awọn musulumi to lọ fun Hajj lọdun yii, wọn si ji okuta dudu Kaaba lọ eyi tawọn musulumi gbagbọ pe o wa lati ọrun.
Wọn gbe okuta naa lọ si Bahrain, wọn si foote le iṣẹ Hajj fun ogun ọdun, to fi di igba ti ọkunrin alagbara kan, Abbadis san owo itanran ki wọn le da okuta naa pada

2) Ọrọ oṣelu fopin de Hajj fun ọdun mẹjọ
Lọdun 983, A.D. awọn olori ni Baghdada ba Egypt jagun.
Awọn alaṣẹ Fatimid ni Egypt sọ pe awọn ni ojulowo olori ẹsin musulumi, eyi to mu wọn tako ijọba Abbasid lorilẹ-ede Iraq ati Syria.
Aawọ naa ko jẹ kawọn musulumi lati Mecca ati Medina le ṣiṣẹ Hajj fun ọdun mẹjọ to fi di 991, A.D.
Nigba ti ijọba Fatimid da wo lọdun 1168,, A.D. awọn ara ilẹ Egypt ko le wọ Hijaz.
Bakan naa ni a gbọ pe awọn ara Baghdad ko le ṣe ṣiṣẹ Hajj fun ọpọlọpọ ọdun.
Ikọlu awọn ologun labẹ alaṣẹ Napoleon eyi to tako ijọba akonilẹru ilẹ Gẹẹsi ni ẹkun naa ko fun ọpọ musulumi laye lati ṣiṣẹ Hajj laarin ọdun 1798 si 1801.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ajakalẹ aarun atawọn nnkan miiran ti ko jẹ kawọn musulumi ṣiṣẹ Hajj fun igba mẹjọ to ku:
- Lọdun 967 A.D., ajakalẹ aarun kan to bẹ silẹ ko fawọn musulumi lanfaani lati ṣiṣẹ Hajj.
- Ọgbẹlẹ ati iyan mu ki Olori Fatimid wọgile eto Hajj lọdun 1048 A.D.
- Ajakalẹ aarun onigbameji niluu Mecca ati Medina lọdun 1858 ko jẹ ki ọpọ musulumi ṣiṣẹ Hajj
- Ajakalẹ aarun onigbameji ṣekupa ẹgbẹrun un awọn musulumi ti wọn n lọ fun Hajj.
- Wọn da iṣẹ Hajj duro laarin ọdun 1837si 1858 nitori ajakalẹ aarun bakan naa.
- Lọdun 1837, ajakalẹ aarun mii bẹ silẹ niluu mimọ eyi to jẹ ki wọn wọgile eto Hajj titi di ọdun 1840.
- Lọdun 1846, ti aarun onigbameji tun bẹ silẹ ni Mecca, eeyan to le lẹgbẹrun un mẹẹdogun lo padanu ẹmi wọn.
- Lọdun 2012 si 2013, ijọba ilẹ Saudi gba awọn agbalagba ni imọran pe ki wọn maa wa si Hajj nitori ajakalẹ aarun MERS.
- Lọdun 2020, ijọba Saudi Arabia ko faaye gba ọpọ eeyan lati wa fun iṣẹ Hajj nitori ajakalẹ aarun covid-19,
Eeyan to le ni 161,000 lo ti lugbadi aarun Coronavirusnaa nibẹ nigba ti awọn to ti ku ju 1,300 lọ.















