BBC and MTN: ọ̀fẹ́ ni ẹ o máa gbọ́ ìròyìn Yorùbá, Pidgin, Igbo àti Hausa lórí 'MyMTN App' yìn!

ololufe

Oríṣun àwòrán, MTN

Àkọlé àwòrán, Ire déé! MTN àti BBC World Service bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ lórí ìròyìn ìṣẹ́jú kan BBC

Bi o ba jẹ ọkan lara awọn ololufẹ ileesẹ BBC ti o si ti n ronu bi wa a ti se maa gbadun iroyin isẹju kan wa nigbakugba nibi kibi, iroyin ayọ la mu tọ yin wa yi.

Ileesẹ BBC World Service ati ileesẹ MTN ti setan lati maa mu iroyin yi wa si eti igbọ yin lọfẹ lede Yoruba, Pidgin Igbo ati Hausa.Enikẹni to ba ti kan si MyMTN APP ni anfaani nla yi wa fun.

Iroyin Isẹju Kan BBC lawọn ede wọnyi jẹ iroyin ni soki ti a se akojọpọ rẹ fun awọn ololufẹ wa lai fi ti ọjọ ori se.

Wón yoo si maa gbọ nipa iroyin agbaye, ohun to n lọ nigboro, ere idaraya, imọ ẹrọ ati iroyin amuludun nibẹ.

Pẹlu ibasepọ tuntun yi, awọn ololufẹ wa yoo laanfani lati maa gbadun iroyin to ta leti ọhun nigba to ba wu wọn, lalẹ tabi lọsan gangan.

Bẹẹ naa ni yoo jẹ ki awọn eeyan gbọ ojulowo iroyin lawujọ lasiko yii ti o jẹ pe ayederu iroyin ti gbalẹ kaakiri.Ọga agba to n dari ẹka ede ni Iwọ Oorun ilẹ Afirika fun BBC, Toyosi Ogunseye fi idunnu rẹ han lori igbesẹ akọni yii.

Iroyin
Àkọlé àwòrán, Ohun ayo ni iroyin iṣẹju kan BBC yoo jẹ fun awọn ọdọ Naijiria

Toyosi sọ pe: ''Ajọsepọ yi pẹlu MTN safIhan ifarajin BBC lati mu iroyin de ọdọ awọn eeyan nibikibi ti wọn ba wa ni Naijiria.

Inu BBC si dun pe a ni anfani lati ni ajọsepọ to dan mọran pẹlu awọn ọdọ latari igbesẹ yi''

Ọga agba ẹka ẹrọ ayelujara fun MTN, Srinivas Rao ni:

''Iwuri ni ibasepọ yi jẹ fun MTN ati pe ọna kan gboogi tawọn ọdọ Naijiria yoo maa fi ri iroyin to peye si lo jẹ''

Ninu ọrọ tirẹ, Kolawole Oyeyemi to jẹ oludari eto to n risi igbadun onibara MTN sọ pe:

''Igbesẹ yi n safihan iru igbadun to gaju lọ ti awọn onibara wa yoo ma ri bi wọn ba ti lo My MTN App''

Mary Lusiba to jẹ olori ẹka idagbasoke eto karakata ileesẹ BBC World Service ni tirẹ sapejuwe ibasepọ yi gẹgẹ bi eleyi ti yoo ''jẹ ki awọn ọdọ mọ si i nipa BBC.

O ni: Igbesẹ yi n sagbega orukọ rere ti BBC ti ni nipa iroyin to gbamuse ti yoo si de ọdọ awọn ọdọ lorile-ede Naijiria''

Àkọlé fídíò, Mobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama