TuFace di aṣojú pàtàkí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé UN Goodwill Ambassador àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà

Awọn oju to n ṣoju ajọ agbaye.

Oríṣun àwòrán, UNHCR Nig

2Baba Idibia di akọkọ aṣoju pataki 'UN goodwill Ambassador' lati Naijiria, ki lo mu wọn yan?

Ni ohun ta le sọ pe o je akọkọ ninu itan awọn ọmọ Naijiria, Tuface Idibia, ilumọọka akọrin Naijiria di aṣoju ajọ to n risi ọrọ awọn atipo, UNHCR, yoo kede gẹgẹ bii aṣoju pataki wọn.

Ajọ UNHCR sọ pe lati nkan bi ọdun mẹta sẹyin ni Tuface ti n gbaruku ti ipolongo 'LuQuLuQu' ti wọn gbe kalẹ.

Ipolongo yii lo ko awọn oriṣi eeyan to fẹ pese iranlọwọ fun awọn ti wahala kan ti wón le kuro nile wọn.Ninu fọnran fidio kan ti UNHCR Naijiria fi sita ni Tuface ti sọ pe "nkan iwuri ati idunnu lo jẹ" bi wọn ti ṣe yan oun lasoju pataki.

Ajọ UNHCR ni lọdun 2017, Tuface kọwọrin ba wọn ṣe abẹwo kaakiri lọ wo awọn ti ogun le kuro nile wọn lọ si ibudo awọn Aṣatipo to wa ni ipinlẹ Borno.Bayi ti wọn ti wa yan an si ipo yi, ti awọn eeyan si ti n ki i ku oriire lọtun losi, njẹ ko yẹ ki a beere pe kini iṣẹ ti yoo ma ba wọn ṣe ati pe ki ni eeyan gbọdọ ṣe lati le fi di iru ipo yi mu?

Àkọlé fídíò, Mobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama

Ki ni o le sọ eeyan to di aṣoju pataki ajọ iṣọkan agbaye, UN?Ajọ UN ni awọn ilana tọ gbe kalẹ ki eeyan to le jẹ aṣoju pataki labẹ eyikeyi ẹka rẹ bi i UNICEF, UNDP, WHO ati bẹẹ bẹẹ lọ.O ni lati jẹ ilumọọka eeyan lagbo iṣẹ ọna, litireso, imo sayensi, ere idaraya, amuludun tabi ni ẹka miran. O gbọdọ ṣetan lati fi asiko rẹ silẹ pẹlu ẹbun ti Ẹlẹda fi kẹ o.

O pọn dandan ki o ni ifarajin lati pe akiyesi awọn eeyan si iṣẹ ti ajọ UN n ṣe lati mu iyipada rere ba igbe aye awọn ọpọ eeyan kaakiri orilẹ aye.O gbọdọ ni iwa rere ki o si mọ bi eeyan ṣe n gbe igbesẹ lati mayedẹrun lawujọOrukọ rẹ gbọdọ jẹ eyi ti awọn eeyan mọ lorileede rẹ ati lagbaye.Wọn ko ni san owo oṣu fun ọ bo ti lẹ jẹ wipe ajọ UN yoo fun ọ ni dọla kan gẹgẹ bi afihan pe wọn san owo fun ọ

Iru iṣẹ wo ni aṣoju pataki yi n ṣe?Iru ajọ UN to ba yan eeyan gẹgẹ bii asoju ni yoo ṣe itọkasi iru iṣẹ ti eeyan naa yoo maa ba won ṣe.Bii ti iru 2baba to ṣe pe akọrin ni, yoo maa ba wọn kọrin fun awọn ti o jẹ Aṣatipo nigbakigba ti wọn ba lọ bẹ wọn wo.Bakan naa ni o gbọdọ yago fun gbogbo nkan ti yoo ba ta epo sí asọ aala rẹ gẹgẹ bi aṣoju pataki ajọ UN.Ajọ iṣọkan agbaye UN sọ pe iye awọn aṣoju pataki ati ojiṣẹ ọrọ alaafia ti awọn ni kaakiri agbaye kọja irinwo.Iwo naa o ya mura ki o le dara pọ mo wọn.

2face

Oríṣun àwòrán, UNHCR Nig

Àkọlé àwòrán, TuFace di aṣojú pàtàkí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé UN Goodwill Ambassador àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà