Abiola Ajimobi: Àwọn ìgbà tí aráàlú fajúro lórí ìṣèjọba rẹ̀!

Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Yoruba ni ariṣe ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ti onikaluku ba se lonii, ọrọ itan ni yoo da bo ba d'ọla.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu iku gomina ana nipinlẹ Ọyọ, Sẹnatọ Abiola Ajimobi to papoda l'Ọjọbọ lẹni aadọrin ọdun.

Lasiko ti oloogbe naa ṣi n ṣe saa lori alefa gẹgẹ bii gomina nipinlẹ Ọyọ, oniruuru awuyewuye lo waye lasiko naa nipa awọn igbesẹ kan ti ijọba rẹ gbe.

Idi si ree ti BBC Yoruba fi se akojọpọ awọn awuyewuye meje to waye, eyi to mu ki ẹnu maa kun Ajimobi lasiko to jẹ gomina nipinlẹ Ọyọ.

Akoko mẹjọ ti ẹnu kun Abiola Ajimobi lori ipo gomina:

Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi

Igba to wo isọ ati ile lulkaakiri ipinlẹ Ọyọ:

Ni saa akọkọ gomina Abiola Ajimobi lo wo awọn sọọbu kan to wa lẹba oju popo yika ipinlẹ Ọyọ, paapa nilu Ibadan.

Awijare gomina ni pe igbesẹ kikọ isọ sẹba titi lewu pupọ, to si lee se ijamba fun ẹmi araalu, ti mọto ba lọ ya ba wọn.

Bakan naa, ni ijọba Ajimobi tun wo awọn ile kan to wa lẹba odo ati awọn to wa lẹba oju popo ki anfaani lee wa lati fẹ oju popo yika ipinlẹ Oyọ.

Awọn igbesẹ naa si lo bi awuyewuye laarin araalu, ti wọn si n pariwo pe ika ni gomina Ajimobi fi igbesẹ naa se.

Idi ree ti wọn fi sọ ni inagijẹ Isiaka wolewole lasiko naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Asiko Ajaalẹ ni Soka:

Ajimobi se abẹwo si Ajaalẹ ni Soka

Oríṣun àwòrán, Others

Igba keji ti ẹnu tun kun oloogbe Abiola Ajimobi lasiko to wa lori oye gomina ni igba ti isẹlẹ ajaalẹ waye ladugbo Soka nilu Ibadan.

Ajaalẹ yii ni asiri tu pe awọn ajọmọgbe n lo lati maa ta ẹya ara eeyan, eyi ti wọn sọ ni ajaalẹ Soka.

Bi o tilẹ jẹ pe ijọba fi katakata wo ajaalẹ naa mọlẹ, to si run womuwomu, sibẹ ọpọ eeyan lo n fi ẹnu kun ijọba Ajimobi pe ko fi ẹnikẹni jofin lori isẹlẹ naa.

Jija si agba:

Ni ọpọ igba tun ni ẹnu kun oloogbe Abiola Ajimobi pe o kundun ko maa ja si agba.

Idi ni pe ti gomina ba n sọrọ nipa ẹnikẹni, yoo bẹrẹ si sọrọ nipa ọjọ ori onitọun, ti yoo si ni aburo oun ni tabi pe oun ju wọn lọ.

Koda, ẹni to ba ju Abiola Ajimobi, yoo tun sọ fun pe "ọjọ melo gan lẹ fi ju mi lọ".

Yiyan ọba mọkalelogun ni ọjọ kan:

Abiola, aya rẹ Florence pẹlu awọn ọba mọkalelogun to gbe ade le lori nilẹ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Others

Eruku sọ lala lori Abiola Ajimobi lasiko to se atunto ofin ati ilana oye ọba jijẹ nilẹ Ibadan.

Atunto ilana oye ọba naa si lo fun Ajimobi lanfaani lati yan ọba mọkalelogun ni ọjọ kansoso labẹ Olubadan tilẹ Ibadan.

Ọrọ naa di awuyewuye, ti wọn si ri iwa gomina naa bii ọyaju si Olubadan, ti igbesẹ naa si pin igbimọ Olubadan si meji di oni oloni.

Ajẹsilẹ owo osu awọn oṣiṣẹ ati oṣiṣẹ fẹyinti:

Ẹnu tun kun Abiola Ajimobi lasiko ti ko san owo oṣu awọn oṣisẹ ati oṣisẹ fẹyinti.

Bi o tilẹ jẹ pe ọrọ aje Naijiria lo dagun nigba naa ti ijọba rẹ ko fi ri owo oṣu san, amọ eyi ko ni ki ẹnu ma kun Ajimobi.

Awọn oṣisẹ ni awọn ọrọ kobakungbe ti Ajimobi maa n sọ fun awọn lai san owo oṣu lasiko, to si tun n mu awọn oṣisẹ to ba pẹ de ẹnu iṣẹ lo fa eyi.

Ajimobi n ba awọn asaaju ẹgbẹ osisẹ ipinlẹ Oyo sọrọ nigba to wa lori aleefa

Oríṣun àwòrán, Others

Asiko yii ni Ajimobi se ayẹwo fawọn osisẹ, to si tun da pupọ wọn duro tori wọn ko ni iwe ẹri to jinna, tawọn osisẹ naa si ni eyi ko ri bẹẹ.

Awọn osisẹ ti ọrọ yii kan lo lee sọ, ti idaduro ojiji yii si ran ọpọ wọn sọrun ọsan gangan, nigba ti awọn miran di alarun, to fi mọ awọn osisẹ fẹyinti.

Koda, Abiola Ajimobi sọ ni ọjọ kan ti awọn osisẹ fẹyinti n beere ajẹsilẹ owo ajẹmọnu wọn pe:

"Se wọn ko ni ọmọ to wulo to lee maa tọju wọn lọjọ ogbo ni eyi ti ko ni jẹ ki wọn gbe ara le owo ajẹmọnu ifẹyinti lati ọdọ ijọba."

Ọrọ Ajimobi yii si lo da họhu-họhu silẹ nigba naa.

O seleri lati mase gbe igba ibo mọ amọ ti ko mu ileri naa sẹ:

Abiola Ajimobi ati aya rẹ, Florence n dibo

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi

Igba miran ti ẹnu tun kun Abiola Ajimobi ni akoko to ṣeleri pe oun ko ni gbe igba ibo mọ lati bẹbẹ fun ipo oṣelu lọdọ araalu.

Gbogbo eeyan lo n kan saara si nigba naa amọ ko pẹ lẹyin naa ti Ajimobi fi ko ọrọ naa jẹ, to si beere fun ipo Sẹnatọ .

Ọpọ eeyan lo n yọ suti ete si Abiola Ajimobi nigba naa pe ki lo tun n wa lagbo oselu, to se tun jade pe oun fẹ lọ sile asofin agba, se ko ni itẹlọrun ni?

Sugbọn Ajimobi tẹsiwaju lati dije fun ipo Sẹnatọ naa, bi o tilẹ jẹ pe o ti lọ sile aṣofin agba ri , ko to di gomina ipinlẹ Ọyọ.

Lẹyin o rẹyin, Abiola Ajimobi fidi rẹmi ninu ibo naa, ti Sẹnatọ Kola Balogun si jawe olubori lati lọ sile aṣofin agba ni Abuja.

Ija ojoojumọ pẹlu awọn akẹkọọ nile ẹkọ giga ati girama:

Awọn akẹkọ LAUTECH n fi ẹhonu han

Oríṣun àwòrán, Others

Lasiko ti Abiola Ajimobi wa lori aleefa bii gomina ipinlẹ Ọyọ, ojojoojumọ ni awuyewuye maa n waye ni ẹka eto ẹkọ nitori awọn igbesẹ to n gbe lẹka eto ẹkọ.

Fun apẹẹrẹ, o le ni ọdun kan ti awọn akẹkọọ fasiti imọ ẹrọ Ladoke Akintola, LAUTECH fi joko sile.

Igba ti awọn akẹkọọ naa si se abẹwo si ọdọ rẹ lọgba Secretariat ,lati fi ẹhonu han lori akude to ba eto ẹkọ wọn, ni wọn ba ibinu Ajimọbi pade tori wọn baa sọrọ lọna aitọ.

Awọn akẹkọ ile ẹkọ girama n fi ẹhonu han

Oríṣun àwòrán, Others

Idi ree ti Ajimọbi fi beere pe "ṣe Constituted Authority lẹ n ba sọrọ bayẹn?"

Lati igba naa si ni wọn ti n pe ni ni "Constituted Authority" di oni.

Ko tan sibẹ, awọn akẹkọọ girama naa se iwọde tako ilana ijọba Ajimobi ni ẹka eto ẹkọ, eyi to mu ki igboro mi titi, ti awuyewuye si waye lasiko naa lẹka eto ẹkọ.

Dida ile orin Ayefele wo:

Ile orin Ayefele ti ijọba Ajimobi da wo lulẹ

Oríṣun àwòrán, Yinka Ayefele Instagram

Pabambari awuyewuye to waye lasiko isejọba gomina Abiola Ajimobi ni bo se da ile orin Yinka Ayefele wo, ladugbo Challenge, nilu Ibadan.

Ajimobi ni ile orin naa lo wa lẹba oju popo, ti Ayefele ko si tun ni iwe onilẹ to yẹ nipa ilẹ to kọ ile le lori.

Ayefele ni iwe wa fun ilẹ oun, ti wọn si pe ọrọ naa lowe, amọ to ni araaro ninu.

Ni idaji ọkọ kan, ni ijọba Ajimobi ko ẹrọ katakata lọ bi ile naa wo, eyi to bọ si ibinu ọpọlọpọ eeyan.

Yinka Ayefele n bọ Abiola Ajimobi lọwọ

Oríṣun àwòrán, Yinka Ayefele

Bi o tilẹ jẹ pe ẹnu kun Abiola Ajimobi lasiko to wa nijọba, sibẹ ọpọ aseyọri lo se lori aleefa, eyi to jẹ manigbagbe.

O ti wa se iwọn to lee se, o si ti dagbere fun aye pe o digbo se, a wa n gbadura pe Ọba oke yoo dẹ ilẹ fun akikanju ọmọ Ibadan to rele.

Ìpínlẹ̀ Oyo sọ àsìá Nàìjíríà kalẹ̀ láti dárò Abiola Ajimobi

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde/twitter

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣapejuwe gomina ipinlẹ Oyo nigba kan, Abiola Ajimobi, gẹgẹ bi ẹni to ko ipa to jọju ninu idagbasoke Naijiria.

Oludamọran Pataki fun aarẹ lori eto iroyin, Femi Adesina to fi ikede ibanikẹdun naa sita lorukọ aarẹ sọ pe:

"Ajimọbi kú lasiko ti ẹgbẹ APC, ati orilẹ-ede rẹ nilo imọran tẹ lati gba iwosan ati idagbasoke."

Aarẹ Buhari kẹdun iku Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Aarẹ Buhari sọ pe titi lai ni ipa ti Ajimobi ko ninu idagbasoke ipinlẹ Oyo yoo wa ni iranti.

Abiola Ajimobi ati Makinde

Oríṣun àwòrán, @AAAjimobi/Twitter

Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbí Abiola Ajimobi to d'oloogbe l'Ọjọbọ.

Ninu ọrọ rẹ, Makinde sọ pe ipapoda rẹ ba oun lọkan jẹ. Ati pe oun ko ti ẹ le fi ori ṣiro ibanujẹ ti iku rẹ jẹ fun ẹbí rẹ.

O gbadura pe ki Ọlọrun fun wọn ni okun lati le gba iku rẹ mọra.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa lo sọ pe "ilana ti Ajimobi la kalẹ, lo jẹ ipilẹ diẹ lara awọn iṣẹ ti iṣakoso wa n ṣe.

"Gbogbo ọ̀wọ̀ to tọ si iru eeyan to jẹ́, ni ao nawọ rẹ si ẹbí rẹ̀."

Makinde si ti paṣẹ pe ki wọn o sọ asia orilẹ-ede Naijiria kalẹ loni ọjọ Ẹti, lati le ṣe idaro "arakunrin, ọrẹ, ati eekan ọmọ bibi ipinlẹ Oyo".

Akinwumi Ambode

Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Akinwumi Ambode naa ko gbẹhin lara awọn eekan ìlú to ti ṣedaro Ajimobi to ku.

Ambode sọ pe ibaṣepọ oun ati Ajimobi nigba aye rẹ ju ti ọmọ iya tabi akẹẹgbẹ lọ.

"O jẹ ẹni to kun fun ọrọ ọgbọn, awada, to si maa n ṣetan lati sọ okodoro nipa iṣẹlẹ yoowu ni gbogbo igba."

Ẹgbẹ oṣelu APC l'Eko

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nipinlẹ Eko naa ti darapọ mọ awọn to n daro iku Ajimobi.

Ninu ikede ti agbẹnusọ ẹgbẹ, Seye Oladejo, fi sita, wọn ba ẹbi ati ẹka ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo kẹdun.

Bakan naa ni wọn gboriyin fun pe o fi ipa manigbagbe silẹ ni ẹka iṣẹ aladani, to si tun jẹ ẹni to sin awọn eniyan rẹ tọkan-tọkan.