Sotitobire latest news: Adájọ́ ṣí àṣùwọ̀n ìfowópamọ́sí Wòlíì Sotitobire, ṣùgbọ́n kò fàyè béèlì sílẹ̀ fún un

Alfa Babatunde

Ile ẹjọ giga kan ni ilu Akurẹ ti gbẹsẹ kuro lori aṣuwọn ifowopamọsi pasitọ ijọ Sọtitobirẹ Praising Chapel ni ilu Akurẹ, Wolii Alfa Babatunde.

Amọṣa, adajọ to n gbọ ẹjọ ijinigbe ti wọn fi kan Alfa Babatunde atawọn eeyan mẹfa miran, iyẹn Onidajọ Oluṣẹgun Oduṣọla ko faye gba ki wọn gba oniduro rẹ.

Àkọlé fídíò, Ohun tẹ́ẹ gbúdọ mọ nípa kókó orí ọyàn yín lásìkò fífọ́mọlọ́yàn

Wolii Alfa Babatunde ti ọpọ mọ si Wolii Sọtitobirẹ n jẹjọ ẹsun ijinigbe lori ọmọdekunrin ọmọ ọdun kan to sọnu ni ijọ rẹ loṣu kọkanla ọdun 2019 lasiko ijọsin nibẹ.

Ọmọdekunrin naa, Gold Kọlawọle ni oun ati iya rẹ lọ si ileejọsin naa lọjọ naa ki iṣẹlẹ ọhun to waye.

Ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹfa ọdun 2020 ni agbẹjọro fun Wolii Sọtitobirẹ, Amofin Oluṣọla Oke lo pẹjọ fun gbigba beeli wolii naa atawọn mẹfa miran ti wọn jijọ n jẹjọ lori ẹsun naa ti Onidajọ Oduṣọla si sun igbẹjọ lori boya ki wọn gba beeli rẹ tabi rara siwaju.

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀

Nigba to n gbe idajọ kalẹ lori rẹ, Onidajọ Oduṣọla ṣalaye wi pe oun ko ni fọwọ si gbigba beeli wolii Sọtitobirẹ atawọn ọmọ ijọ rẹ mẹfa ti wọn n jẹjọ pẹluu rẹ.

Ile ẹjọ ni ọna ti Wolii Sọtitobirẹ n gba beere fun beeli ko si ni ibami pẹlu ofin.

Amọṣa adajọ ni ki wọn gbẹsẹ kuro lori aṣuwọn ifowopamọsi rẹ eyi ti wọn ti sọ agadangodo si lati igba ti igbẹjọ naa ti bẹrẹ.

Eyi fihan pe wolii Alfa Babatunde yoo lee na owo inu aṣuwọn ifowopamọ si rẹ bayii, amọṣa yoo ṣi wa ninu ahamọ ọgba ẹwọn to wa titi di igba ti idajọ yoo fi waye lori ẹsun ti wọn fi kna an.

Wo ohun tí Adájọ́ sọ nípa ìgbẹ́jọ́ Wòlíì Sotitobire l'Ondo

Woli babatunde Alfa de si ile ẹjọ

Oludasilẹ ijọ Sọtitobirẹ ni ilu Akurẹ, Wolii Babatunde Alfa atawọn mẹfa miran ti fi ẹnu ẹjọ wọn jona sibikan bayii ti wọn si n reti bi idajọ ile ẹjọ giga nilu Akurẹ yoo ṣe ri fun wọn.

Gbajugbaja wolii, Babatunde Alfa atawọn mẹfa kan ninu ijọ rẹ n jẹjọ lọwọ lori bi ọmọdekunrin ọmọ ọdun kan ti orukọ rẹ n jẹ Kọlawọle Gold ṣe poora ni ileejọsin naa ni oṣu kọkanla ọdun to kọja.

Adajọ to n gbọ ẹjọ naa ti kede ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan an, ọdun 2020 gẹgẹ bi ọjọ ti awọn agbẹjọro olupẹjọ ati olujẹjọ yoo gbe apilẹkọ awijare wọn kalẹ niwaju ile ẹjọ naa ki Adajọ lee ṣe idajọ to ba yẹ.

Amọṣa Adajọ naa ti laago ikilọ fun awọn agbẹjọro to n lọwọ ninu igbẹjọ naa to ba fẹ gbẹyinbẹbọjẹ lori ẹjọ naa.

Onidajọ Oluṣẹgun Oduṣọla ni idajọ ododo loun wa fun nitori naa agbẹjọro yoowu to ba fẹ daṣọ bo otitọ lori ẹjọ naa lee kan idin ninu iyọ nitori oun ko ni faye gba irufẹ igbesẹ bẹẹ.

Woli sotitobi atawọn oṣiṣẹ ileesjọsin rẹ ti wọn jọ n jẹjọ

Sotitobire: Kò sí èléyìí tó kàn mí nípa ìjínígbé Gold Kolawole!

Agbẹjọro ijọba lori ọrọ Woli Sotitobire ti ni ọwọ adajọ lo ku si lati sọ bọya Sotitobirẹ jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Agbẹjọro naa ni Woli Sotitobirẹ ti sọ wi pe ohun ko mọ nkankan nipa iijnigbe Gold Kọlawole ti wọn jigbe lọ ni Ile Ijọsin rẹ ni Akure.

O ni lasiko ifọrọwanilẹnuwo, Woli Sotitobirẹ sọ wi pe aago mẹta ọsan ni oun to gbọ wi pe wọn n wa ọmọ to sọnu ni ile ijọsin oun.

Agbẹjọrọ ijọba naa fikun pe ijinigbe ọmọ naa ko ni nkankan ṣe pẹlu oun, nitori naa ko kan oun.

Amọ, iya ati baba ọmọ ti wọn jigbe lọ fi ẹsun kan Woli Sotitobirẹ pe ko bikita nipa ọmọ ti wọn jigbe lọ naa ni wọn ṣe fun ra sii.

Sugbọn, Woli Sotitobirẹ ni idi ti oun ko fi kọ ibi ara si ọrọ awọn obi ọmọ ti wọn jilọ naa ni wi pe, awọn obi ọmọ naa bu oun pe oun ko sin Olorun to ni ọmọ naa fi di awati ni ile ijọsin rẹ.

Ẹlẹ́rìí mẹ́rìn ló tẹ̀lé Alfa Babatunde wá síwájú ilé ẹjọ́

Nínú ìgbẹ́jọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ lóri ọmọ tó sọnu nínú ilé ìjọsin Sotitobirẹ nílùú Akure, Alfa Babatude ló léwáju láti sọ tẹnurẹ lórí ǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà.

Nílé ẹjọ lónìí, Babatunde ni òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ti wọ́n fi kan òun. Bákan náà ni ni olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Deji Akure olóyè Taiwo Fagite náà wà lára àwọn to wá jẹ́rìí nilé ẹjọ́ lónìí.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Fagite ni àwọn òbí ọmọ tó sọnu náà ko ṣe tó bó ti tọ́ àti bó ti yẹ.

O ní lẹ́yin ti wọ́n wá rojọ́ fun kábíyèsí tán, ní àwọn òbi ọmọ náà àti àwọn olùkọ ilé ìjọsìn ọmọdé mẹ́rìnlá wa búra ni ààfìn kábíyèsí

Deji Akure tún pé Alfa Babatunde àti òbi ọmọ náà, ṣùgbọ́n Alfa Babatunde nìkan ló padà yọju

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Ẹlẹ́rìí kaarún tó sọ̀rọ̀ nilé ẹjọ́ lónìí Ajíyìnrere Funmilayo Ogunlusi ṣàlàyé pé lẹ́yìn ti wọ́n jí ọmọ náà ní Alfa Babatunde pe fún àdúrà àti ààwẹ ọlọ́jọ́ mẹ́sàn-an pé kí Ọlọ́run ṣàwári ọmọ náà.

Lẹ́yìn tí wọ́n gbà ọ̀rọ̀ lẹ́nu gbogbo ẹlẹ́rìí bi márùn nínú ìgbẹ́jọ náà ni àdájọ Olusegun Odusola ni nítori àwítúnwi ọ̀rọ̀, òun kò ni pé ẹlòmíràn mọ́.

Alufaa ijọ Sọtitobirẹ

Oríṣun àwòrán, facebook

Igbẹjọ lori ẹsun ijọmọgbe ti ijọba n ba Wolii Alfa Babatunde ti ijọ Sotitobire si n tẹsiwaju ni ọjọ Aje to n bọ.

Nigba ti igbẹjọ ọhun waye ni Ọjọbọ, Agbẹjọro agba ati Kọmisana feto idajọ nipinlẹ Ondo, Adekola Olawoye, lo soju ijọba ipinlẹ Ondo lori ẹjọ naa.

Olawoye ni ijọba Ondo ti setan lati ri idi okodoro ọrọ to wa nidi ẹjọ yii, ti igun olupẹjọ ko si ni gba ki wọn fi akoko sofo lori ẹjọ naa rara.

Nigba to bẹrẹ igbẹjọ ọhun, agbẹjọro fun ikọ olujẹjọ, Olusola Oke salaye pe ogun ẹlẹrii ni yoo ma jẹri gbe onibara oun.

Àkọlé fídíò, 'Ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ t'óyún máà bàjẹ́ lára mi ni mo tó rí àànú gbà'

Amọ o sọ fun Adajọ Olusegun Odusola to n gbọ ẹjọ naa pe ẹlẹrii mẹta ni olujẹjọ naa yoo ko yọju sile ẹjọ ọhun lana.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn olujẹjọ naa si la ti ri aya olori ijọ Sotitobire, Arabinrin Abisola Alfa.

Wayi o, adajọ Odusola ti wa sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn osu Kẹfa ọdun 2020, eyiun ọsẹ to n bọ.

Woli babatunde Alfa de si ile ẹjọ

Abisola, aya wòlíì Babatunde ti ń jẹrìí nípa bí ọmọ ọdún kan ṣe sọnù

Ninu awọn ẹlẹri ogun ti yoo jẹri gbe wolii ati olori ijọ Sotitobire, Alfa Babatunde lonii, mẹta ti yọju sile ẹjọ.

Ninu awọn ẹlẹrii mẹtẹẹta naa, ẹlẹri akọkọ ti yoo kọkọ sọrọ ni iyawo Woli Sọtitobirẹ, Ajihinrere Busola Alfa.

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran n nile ẹjọ

Oun si lo n salaye nipa ohun to ṣẹlẹ ni ọjọ ti ọmọ kekere, ọmọ ọdun kan, Kolawole Gold sọnu.

Agbẹjọro agba ati Kọmisọna fun eto idajọ nipinlẹ Ondo, Adekola Olawoye naa ni yoo maa ṣoju ijọba ninu ẹjọ to pe tako olori ijọ Sọtitobirẹ.

Alfa Babatunde ati awọn ẹmẹwa rẹ ni wọn n jẹjọ iwa ajinigbe onikoko mẹta, to fi mọ ẹsun iditẹmọni ati biba ẹri jẹ.

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran n fọ ọwọ wọn ki wọn to wọnu ile ẹjọ

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe lonii Ọjọru, ọjọ Kẹẹdọgbọn osu kẹfa ọdun 2020, ni igbẹjọ ẹsun ijọmọgbe tun n tẹsiwaju nile ẹjọ pẹlu olori ijọ Sotitobire, Alfa Babatunde.

Ni deede aago mẹwa ku isẹju diẹ ni olujẹjọ naa ati awọn afurasi yoku to n jẹjọ pẹlu rẹ de sile ẹjọ, ninu asọ ọgba ẹwọn alawọ eweko ti wọn maa n wọ.

Nibamu pẹlu akoko yii, awọn olujẹjọ naa fọ ọwọ wọn pẹlu ọṣẹ ati omi ti wọn gbe siwaju abawọle ile ẹjọ, ti wọn si tun fi ibomu-bonu bo imu ati ẹnu wọn.

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran n wọnu ile ẹjọ

Ni báyìí, agbẹjọro fún olórí ẹni afẹsunkan, Olusola Oke tí ṣàlàyé fún ilé ẹjọ́ báyìí pé, àwọn ẹlẹri ogun tí dé lati jẹri, ṣùgbọ́n, mẹta péré ni yóò farahàn niwaju adajọ loni.

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran n nile ẹjọ

Igbẹjọ naa ti bẹrẹ nile ẹjọ bayii, bo ba si se n lọ, la maa mu iroyin naa wa fun yin.

Àwọn ohun tuntun tí a mọ̀ nípa ìgbẹ́jọ́ Wòlíì Sotitobire

Woli sotitobire

Yatọ si ọkan o jọkan awọn ẹlẹri to n jẹri lori ẹjọ, fidio wolii Babatunde Alfa ti ọpọ mọ si Sọtitobirẹ ni wọn tẹ pẹpẹ rẹ sita nile ẹjọ lọsẹ yii gẹgẹ bi ara awọn ẹsibiiti ti olupẹjọ fẹ tẹ siwaju ile ẹjọ.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, Wolii Alfa Sọtitobirẹ n jẹjọ pẹlu awọn mẹfa miran lori ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan an nipa ọmọdekunrin jojolo Gold Kọlawọle to sọnu ni ile ijọsin rẹ loṣu kọkanla ọdun 2019.

Nibi igbẹjọ to waye l'Ọjọbọ, awọn olupẹjọ pe ẹlẹri lara awọn oṣiṣẹ ajọ DSS atawọn ẹlẹri miran.

Woli sotitobire

ṣaaju ni adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Onidajọ Oluṣẹgun Oduṣọla ti kọkọkoro oju si bi awọn oṣiẹ ọgba ẹwọn ṣe pẹ ni gbigbe awọn afunrasi naa wa si ile ẹjọ.

Inu ojo ti ọwọ rẹ le kikankikan ni wọn gbe wolii sọtitobirẹ atawọn afunrasi yooku wọ ile ẹjọ lowurọ ọjọbọ.

Wọn sún igbejo sì ọjọ́ karundinlogbon, ọjọ́ kokandinlogbon àti ọgbọ́n ọjọ́ Oṣù Kẹfà, ọdún yìí.

Woli sotitobire
Woli sotitobire

Sotitobire: Ìgbẹ́jọ́ Wòlíì Alfa Babatunde Sotitobire ti gúnlẹ̀ sí iléẹjọ́ ní ìtẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀

Pasitọ Babatunde Alfa ti ọpọ mọ si sọtitobirẹ ti gunlẹ si ileẹjọ bayii nibi ti yoo ti tẹsiwaju igbẹjọ ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan an.

Eyi ni awọn aworan igba ti o gunlẹ si ileẹjọ giga nilu Akurẹ lowurọ ọjọ Aje.

Wolii Sọtitobirẹ atawọn afunrasi yooku

Sotitobire: Ìgbẹ́jọ́ Wòlíì Alfa Babatunde Sotitobire yòó tún tẹ̀síwájú lónìí

Sotitobire

Wolii ijọ Sọtitobirẹ Prayer Minisitry nilu Akurẹ, Alfa Babatunde, ti ọpọ mọ si Wolii Sọtitobirẹ yoo pada si ile ẹjọ loni, ọjọ Aje ọjọ Karundinlogun oṣu kẹfa.

Gbajugbaja iranṣẹ Ọlọrun naa yoo maa fojubale ẹjọ ni itẹsiwaju igbẹjs ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan an niwaju ile ẹjọ giga kan nilu Akurẹ.

Wolii Alfa Babatunde Sọtitobirẹ atawọn oṣiṣẹ ẹka ileejọsin awọn ọmọde ni ileejọsin naa ni wọn n jẹjọ ti ile ẹjọ si n gbọ awijare awọn olupẹjọ fun ijọba lọwọ bayii.

Ni ọjọ kẹwaa oṣu kẹfa ti ẹjọ naa waye kẹyin niwaju Onidajọ Oluṣẹgun Oduṣọla ni awọn ileeṣẹ Agbofinro DSS n ṣe alaye idi to fi jẹ awọn lo n ṣe iwadii ẹsun naa dipo awọn ọlọpaa to kọkọ bẹrẹ iwadii rẹ.

Pasitọ ijọ Sotitobire, Alfa Babatunde njẹjọ lori ọmọ ọdun kan to poora ninu ile ijọsin rẹ lọdun 2019.

Àkọlé fídíò, LASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...

Sotitobire: Ìdí tí a fi ń 'wọ́dìí' Wòlíì Alfa Babatunde Sotitobire-DSS

Ọpọ eeyan lo ti n beere ibeere lori idi to fi jẹ pe awọn ẹṣọ agbofinro ọtẹlẹmuyẹ apapọ, DSS lo n ṣe ẹjọ ijinigbe ti wọn n fi kan ilumọọka wolii Alfa Babatunde Sọtitobirẹ ni ilu Akurẹ.

Amọṣa ileeṣẹ agbofinro DSS ti bọ si gbangba walia lati ṣalaye idi to fi jẹ awọn gan an lo n ṣe kokaari ẹjọ naa.

Lọjọ Aje ni igbẹjọ miran tun waye nile ẹjọ giga to n gbọ ẹjọ ti ijọba fi kan Wolii Alfa Sọtitobirẹ nilu Akurẹ,

Nibẹ ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ naa ti wọn pe gẹgẹ bii ẹlẹri olupẹjọ nibi igbẹjọ naa ti ṣalaye nipa idi to fi jẹ pe ajọ DSS lo n ṣe ẹjọ naa.

O ni pe iwe ifisun ti awọn eekan ilu ati lajọlajọ bii ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Nigeria Human rights commission, atawọn ajọ miran kọ si ileeṣẹ agbofinro ọtẹlẹmuyẹ DSS lẹyin ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ loṣu kọkọanla, ọdun 2019 lo le awọn oṣiṣẹ ajọ naa lati ti ẹsẹ bọ iwadii ọrọ ọhun.

Bi a ṣe n sọrọ yii awọn agbofinro ti gbẹsẹ le aṣuwọn ifowopamọsi Wolii Alfa Babatunde Sọtitobirẹ eleyi ti awọn agbẹjọro fun Wolii naa ti kọwe si ile ẹjọ naa lati tako o.

Àkọlé fídíò, Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Bakan naa ni ile ẹjọ tun ti tẹwọ gba iwe iforukọsilẹ awọn ọmọde ni ileejọsin awọn ọmọde to wa ni ileejọsin fasiti Adura, Sọtitobirẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn ẹri niwaju ile ẹjọ naa.

Ninu eyi ni wọn si tun ti fi idi rẹ mulẹ pe orukọ ọmọdekunrin Gold Kọlawọle ti wọn n wa naa wa ni nọmba kẹtadinlaadọrun ninu iwe ọhun.

Onidajọ Oluṣẹgun Oduṣala to n gbọ ẹjọ ọhun wa sun igbẹjọ si ọjọ Aje to n bọ tii ṣe ọjọ karundinlogun osu yii.

Sotitobirẹ

Sotitobire: Pásìtọ̀ Alfa Babatunde padà s'ẹ́wọ̀n, Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀

Alfa Babatunde

Ileẹjọ giga ipinlẹ Ondo to wa niluu Akure ti sun igbẹjọ Pasitọ ijọ Sotitobire, Alfa Babatunde si ọjọ Aje to n bọ tii ṣe ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹfa ọdun 2020.

Alfa Babatunde Sotitobire lo mn jẹjọ pẹlu awọn mẹfa mii lori ẹsun igbimpọ lati ji ọmọ ọdun kan, Gold Kolawole gbe lọdun 2019.

Ileẹjọ fidi rẹ mulẹ pe iwe iforukọ silẹ awọn ọmọde eyi ti orukọ Gold wa nibẹ fihan pe lootọọ lọmọ naa wa ni ṣọọṣi lọjọ to di awati.

Adajọ Olusegun odusola kọ eti ikun ẹbẹ agbẹjọro Alfa Babatunde lati ṣi apo ifowopamọ rẹ marun un eleyi ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS tipa.

Adajọ tun sun igbẹjọ beeli awọn afurasi naa di ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹfa yii kan naa.

Igbẹjọ Pasitọ ijọ Sotitobire n lọ nileẹjọ giga l'Akure

Pasitọ ijọ Sotitobire, Alfa Babatunde ti wa nile ẹjọ giga ilu Akure bayii, ni itẹsiwaju igbẹjọ ọmọ ọdun kan to poora ninu ile ijọsin rẹ lọdun 2019.

Ni dede aago mẹsan an ku iṣẹju mẹwaa owurọ ọjọ Aje ni wọn gbe pasitọ naa atawọn mẹfa mii de lati ọgba ẹwọn Olokuta to wa ni ilu Akure.

Sotitobire

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Sotitobire: Alfa Babatunde Sotitobire yóò tún fojú balé ẹjọ́ lọ́jọ́ Ajé tó ń bọ̀

Woli sotitobi atawọn oṣiṣẹ ileesjọsin rẹ ti wọn jọ n jẹjọ

Alfa Babatunde Sotitobire tún fojú balé ẹjọ́ lọ́nìí, ni itẹsiwaju igbẹjọ rẹ niwaju ile ẹjọ giga ni ilu Akurẹ lori sun igbimpọ lati ji mọ gbe.

Ilé ẹjọ́ tí sún igbejọ lori ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan gbajugbaja wolii kan ni ilu Akurẹ, Alfa Babatunde ti p eeyan m si Sọtitobirẹ siwaju di ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdún yìí láti jẹ ki igbejo náà yà kíákíá.

Leyin ọ̀pọ̀lọpọ̀ atotonu àwọn agbejoro fun wòlíì Babatunde Alfa Sọtitobirẹ ni ile ẹjọ́ àgbà tí ìpínlè Ondo to fikalẹ si ilu Akurẹ lọjọru, ilé ẹjọ́ gba ẹri àwọn agbofinro ọtẹlẹmuyẹ àjọ DSS wọlé pé, wọn fi ẹ̀sùn méjì kan àlùfáà náà tí ó dà lórí ijinigbe àti ifowosowopo láti ṣíṣe láabi náà

Woli sotitobi atawọn oṣiṣẹ ileesjọsin rẹ ti wọn jọ n jẹjọ

Ẹlẹ́rìí àwọn àjọ DSS, Khadijat Oriyomi ṣàlàyé pé, ní ọjọ́ Kejìlá Oṣù Kejìlá Ọdún 2019, ní wón mú ọkàn lára àwọn afunrasi naa, arábìnrin Margaret Oyetola, tí ó sì kọ ìwé sílè pé Lóòótọ́ ni iṣẹlẹ náà ṣẹlẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ye ohun bóyá Lóòótọ́ ni àlùfáà náà jí ọmọ gbé ati pé lóòótọ́ ni ọkàn lára wọn, Peter Anjorin fò fóònù mọ́lẹ̀ èyí tí ó jẹ ti àlùfáà Babatunde níwájú àjọ náà.

Woli sotitobi atawọn oṣiṣẹ ileesjọsin rẹ ti wọn jọ n jẹjọ ni gbọngan ile ẹjọ

Alfa Babatunde Sotitobire tún fojú balé ẹjọ́ lọ́nìí, bàbá ọmọ jẹri níwájú adájọ́

Sotitobire
Àkọlé àwòrán, Alfa Babatunde Sotitobire tún fojú balé ẹjọ́ lọ́nìí, bàbá ọmọ jẹri níwájú adájọ́

Bàbá ọmọ ọdún kan tí wọ́n jígbé ni ilé ìjọsìn Praising Chapel Akure ní inú oṣù kọkánlá ọdun tókọja, Temitope Kolawole ti jẹri níbi ìgbẹ́jọ tó n lọ lọ́wọ́ láàrín òun àti olórí ìjọ náà wòlí Alfa Babatunde àti àwọn mẹ́fà míràn.

Adájọ́ Olusegun Odusola to gbọ́ ẹjọ́ náà gbà pé ẹ̀rí ni ọ̀rọ̀ Temitope Kolawole jẹ́ níwájú ilé ẹjọ́ èyí tó ti fi lélẹ̀ lásìkò ti àwọn ẹka ọlọ́pàá tó n rí sí ijínigbé fọ̀rọ̀ wáa lẹ́nuwò.

Ìròyìn sọ pé Alfa Babatunde àti àwọn tó kù ti padà sí inú ẹ̀wọ́n Olokuta ní Ondo láti tẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ lọ́la

Sáájú ni Temitope Kolawole tó jẹ́ bàbá ọmọ tó sọnù sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn olólùfẹ́ Alfa Babatunde pébò òun ti wọ́n sì fa aṣọ òun ya kí òun tó sá lọ ba Deji Akure láti ṣe àwárí ọmọ òun.

Bákan náà ni àwọn ọgbà ẹ̀wọn ní kí àwọ́n ẹlẹ́wọ̀n tẹlé ìlànà ìmọ́tótó ki wọ́n tó wọ ilé ẹjọ́ tó fi mọ Alfa Babatunde.

Ilé ẹjọ́ dá pásítọ̀ ìjọ Sotitobire àti àwọn tókù padà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó sún ẹjọ́ síwájú di ọ̀lá

Woli babatunde Alfa de si ile ẹjọ

Ile ẹjọ giga ilu Akure to n gbọ ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan pasitọ ijọ Sotitobire, Alfa Babatunde ti sun ẹjọ naa si Ọjọ Kẹfa, oṣu kẹrin ọdun 2020.

Adajọ ile ẹjọ naa, Olusegun Odusola sun ẹjọ naa lẹyin wakati mẹjọ gbako ti wọn ti wa nile ẹjọ ọhun, lati le faye gba awọn ẹlẹri mẹrin ijọba lati wa sọ tẹnu wọn.

Gbọingbọin ni awọn ololufẹ pasitọn naa wa nile ẹjọ titi di igba ti ẹjọ ọhun pari.

Ni bayii, wọn ti da pasitọ naa atawọn mẹfa mii ti wọn fẹsunkan ṣogba ẹwọn Olokuta to wa nilu Akure titi di Oṣu Kẹrin ti igbẹjọ mii yoo waye.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Iroyin lati ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ ijinigbe ti wọn fi kan gbajugbaja iranṣẹ Ọlọrun kan niluu Akurẹ ẹni ti ọpọ mọ si Baba Sọtitobirẹ, Wolii Alfa Babatunde n jẹ ko di mimọ pe gbaragada ni iya ọmọ naa, arabinrin Modupẹ Kọlawọle bu s'ẹkun ni ile ẹjọ naa loni nigba to n jẹri lori ẹjọ naa.

Awọn akọwe ile ẹjọ naa ni ṣe aajo rẹ lẹyin to fidijanlẹ sori aga.

Oludasilẹ ijọ Sọtitobirẹ Miracle center nilu Akurẹ, Woli Alfa Babatunde pada si ile ẹjọ lori iṣẹlẹ ọmọdekunrin kan to sọnu ni ileejọsin naa loṣu kọkanla ọdun to kọja.

Awọn oṣiṣẹ ileejọsin naa mẹfa miran n jẹjọ pẹlu woli Babatunde lori ẹsun ijinigbe ati igbimọpọ huwa ijinigbe.

Woli babatunde Alfa de si ile ẹjọ

Ireti wa pe iya ati baba Gold Kọlawọle ni yoo ṣiwaju awọn ẹlẹri marun tawọn agbẹjọro ijọba yoo pe jade loni nile ẹjọ.

Nibi ijoko ile ẹjọ naa to waye lọjọ Aje to kọja, iya-iya ọmọ naa ati mọlẹbi rẹ kan wa lara awọn ti wọn pe gẹgẹ bi ẹlẹri nibi igbẹjọ ọjọ naa.

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, gba-gba-gba lawọn agbofinro wa nikalẹ lati mojuto eto abo ni ile ẹjọ naa.