Edo governorship election: Ẹ̀kọ́ márùn ún tí a rí kọ́ nípa eré tíátà tó ń wáyé l'ágbo òṣèlú ìpínlẹ̀ Edo

Gomina Edo

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Edo state news: Godwin Obaseki ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Bi eeyan ba ti n fi ọkan ba awuyewuye to n waye lagbo oselu nipinlẹ Edo lorileede Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yi, yoo ri pe ara ọtọ ni oselu Naijiria, ti o si gba ki eeyan fi ọgbọn ba awọn oloselu ibẹ lo.

Lẹnu igba ti aawọ laarin Gomina Godwin Obaseki ati alaga ẹgbẹ Adams Oshiomole bẹrẹ yi, a ti ri itu orisirisi lati ọwọ awọn to n kopa ninu ohun to fẹ jọ ere ori itage yii, sugbọn to se pe awọn oloselu ni oṣere to wa ninu rẹ.

Ki wa lawọn ẹkọ ta le ri dimu ninu ere agbelewo ti gbogbo ọmọ Naijiria n reti ibi ti yoo kangun si yi?

A o gbiyanju lati se atupalẹ diẹ ninu wọn ni meni meji.

Ibi a ba ti ki wọn pẹ o daarọ,a tun le sọ pe ekaalẹ níbẹ

Awọn agba Yoruba lo ma n pa lowe pe ibi ta ba ti sọ pe o daarọ, a kii pada sibẹ lati ki wọn pe ẹ kaalẹ sugbọn lagbo oselu Naijiria ọrọ yi ko fẹẹ ri bẹ.

Gomina Obaseki ti o jẹ Gomina labẹ ẹgb oṣelu APC la ti ri pe o pada si ẹgbẹ oselu PDP, eyi to ti bẹnu atẹ lu tẹlẹ ri.

Bakan naa la ri ninu ere ori itage Edo yi pe Adams Oshiomole to ti kẹyin si Ize Iyamu to ko ipa ribi ribi nigba ti Oshiomole fi dupo Gomina ti wa pada wa fontẹ lu Iyamu gẹgẹ bi ayanfẹ rẹ bayi.

Ọrọ yi ko jẹ tuntun sawọn to ba mọ isesi awọn oloselu Naijiria.

Ṣugbọn ti o ba se pe o n se ẹyin ni kayeefi, ẹkọ nla kan re fun yin lati kọ - oloselu ko ni ọrẹ titi lailai. Wọn le ba o se ọrẹ loni, bo si di lọla, wọn a ṣe ipolongo lati tako ọ.

Aarẹ Buhari ko se gbọkanle pe o ni baba ni igbẹjọ

Ẹkọ pataki yii la ri kọ lati ara aawọ to waye laarin Adams Oshiomole ati Godwin Obaseki.

Bi eeyan ba jẹ oloselu lode toni tabi to n gbero lati darapọ mọ oselu, o ti wa foju han gbangba bayi pe ko le mu aarẹ Naijiria gẹgẹ bi baba isalẹ ti yoo gba a la lọjọ iṣoro.

Buhari

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Gbogbo igbiyanju Gomina Obaseki lọ si ile aarẹ ni Aso Rock lọdọ aarẹ nigba ti ẹgbẹ APC fẹ yọwọ rẹ lawo lati dupo Gomina lo ja si.

Bi o se pe Obaseki woye ohun to sẹlẹ s'ara waju ninu ẹgbẹ naa ni, ko ni wulẹ daamu ara rẹ.

Gẹgẹ bi awọn onwoye oselu Naijiria ti se sọ, Aarẹ Buhari kii da si ọrọ aawọ to ba n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ APC.

Ko sẹsẹ bẹrẹ , eyi si kọ ni yoo jẹ opin. Nitori naa, ẹkọ nla re e f'ẹnikẹni to ba fẹ sa lọ ba aarẹ lati gbeja rẹ.

Paṣan ti a fi na iyale...

Gbogbo nkan ta n ri ninu awuyewuye oselu ipinlẹ Edo n jẹki ọrọ yi rinlẹ si lọkan gbogbo ẹni to ba n fi ọgbọn ati oye ba bọ wi pe awọn oloselu kii ba ara wọn se ọrẹ timọ timọ.

Ki se igba akọkọ re e ta o ri ti baba isalẹ ati ọmọ lẹyin to fa si ipo yoo ma doju ija kọ ara wọn.

Ni ipinlẹ Eko, Gomina Akinwumi Ambode ati agbaọjẹ oloselu ipinlẹ naa Ahmed Bola Tinubu to faa kalẹ gẹgẹ bi Gomina, pada gbena woju ara wọn.

Ni Kano, iru nkan bayi naa lo sẹlẹ laarin Gomina Abdullahi Ganduje ati ẹni to gbe ipo le lọwọ, Rabiu Kwankwaso.

Ni ipinlẹ Kwara naa ati ri iru rẹ to sẹlẹ ti Abubakar Olusola Saraki to fa Gomina Muhammed Alabi Lawal silẹ wa pada wa doju ija kọ.

Koda, Bukola Saraki to jẹ ọmọ bibi Dokita Olusola Saraki sebi ẹni tako baba rẹ pẹlu bi ko se gbaruku ti aburo rẹ, Sẹnẹtọ Gbemi Saraki ti baba rẹ fẹ ki o jẹ Gomina lẹyin rẹ.

Ipo ta fẹ du ṣe pataki ju ilana ẹgbẹ lọ

Lawọn orileede kan, eeyan a ma da ẹgbẹ oselu mọ pẹlu ilana wọn ati ohun to jẹ afojusun to mu wọn da ẹgbẹ silẹ.

Bi oloselu ba gbe igba ibo, abẹ ilana yiii ni yoo fi gbe eto ati erongba isejọba rẹ kalẹ.

Sugbọn niagbo oselu Naijiria nilẹ toni to mọ yi, awọn oloselu ko fi tẹgbẹ se.

Ibi ti wọn yoo ti ribi du ipo lọkan wọn a ma wa.

Àkọlé fídíò, Ó dára kí obìnrin níṣẹ́ lọ́wọ́ - Toyin Lawani

Apẹrẹ ti a ri lati fi kin ọrọ yi lẹyin ni bi Gomina Godwin Obaseki ko ti se jẹ ki ọjọ pẹ rara ki o to sare lọ darapọ mọ ẹgbẹ oselu PDP lẹyin ti APC lawọn ko fun ni tikẹẹti ẹgbẹ.

Labẹ pe awọn oloselu ko bikita fun erongba tabi ilana yi naa la ti ri pe awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP naa gba tọwọ tẹsẹ, ti wọn si tun fi aaye awọn nkankan gba a, ki o ba le jẹ ẹni ti ẹgbẹ fẹ gbe asia le lọwọ lati du ipo.

Sinima to gun ni ọrọ oṣelu Naijiria, ko fẹ ẹ ni opin

Nibi ti ọrọ de duro yii, ko si ẹni to le sọ pe ibi kan ni yoo ja si nigbẹyin.

Nigba ti awuyewuye yii bẹrẹ, Adams Oshiomole lo dipo alaga ẹgbẹ APC mu.

Ni ba ti se n sọrọ yi, ile ẹjọ giga ti yẹ aga nidi rẹ tawọn miran si ti n ja witiwiti lati wa ni ipo alaga.

Labẹ pe ibẹrẹ kọ l'onisẹ, afi ẹni ba laa ja, awọn ti o fi ẹgbẹ oselu APC silẹ fun Oshiomole bi aarẹ ile asofin agba tẹlẹ ri Bukola Saraki ni wọn wa n gba Godwin Obaseki lalejo ninu ẹgbẹ oselu PDP bayi.

Njẹ ajọsepọ awọn to kora jọ lati doju ija kọ ara wọn wọn yi, yoo jẹ ọlọjọ pipẹ tabi awọn naa yoo pada wa tutọ si ara wọn loju?

Oju re e, iran ree lọrọ to wa nilẹ yi.

E jẹ ki a jijọ maa fọkan ba ọrọ yi bọ.

Godwin Obaseki ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party

Gomina Edo

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Edo state news: Godwin Obaseki ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo Godwin Obaseki ti kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Party lọ si ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party.

Akọwé gómìnà Crusoe Osagie lo fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún BBC

Sáájú ni Obaseki ti kéde lọ́jọ́ ìsẹ́gun ọjọ́ kẹrindinlógún, oṣù kẹfa ọdún 2020 pé òún yóò kòwé fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC silẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Lósàn òní ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo Godwin Obaseki tìkara rẹ̀ kéde nílé ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) nílùú Benin pé òun ti di ọmọ ẹgbẹ́ náà.

Fọ́nran tó jẹyọ lójú òpó twitter ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni gómínà tí sọ pé "O ní ni ìpínlẹ̀ Edo àti jákèjádò orílẹ̀ -èdè Naijiria ní òún ti dí ọmọ ẹgbẹ́ náà"

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Osagie fi kun pé Gómìnà ń pinu láti dupò gómìnà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sún ìdìbò abẹ́nú Edo síwájú síi

gomina Godwin Obaseki

Oríṣun àwòrán, facebook/godwin obaseki

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP nipinlẹ Edo to sun ọjọ idibo abẹnu fun awọn to fẹ dipo Gomina ni ipinlẹ naa siwaju.

Idibo ọhun yo yẹ ki o waye lọjọ kokandinlogun ati ogunjọ oṣu Kẹfa yoo ma waye ni ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹfa bayi.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka ninu iwe iroyin Naijiria The Punch,akọwe ipolongo ẹgbẹ naa Kola Ologbondiyan fidi ọrọ yi múlẹ pe" awọn ti sunjọ idibo naa titi di ọjọ Kẹtalelogun oṣu Kẹfa."

Ṣaaju ni iwe iroyin naa ti jabọ pe Gomina Obaseki ti ṣe ìpàdé kan pẹlu alaga igbimọ awọn Gomina labẹ ẹgbẹ naa Aminu Tambuwal ati alaga ẹgbẹ Uche Secondus l'#Ojọru.

Bayi ti isunsiwaju yi ti waye, o ṣeeṣe ki ẹgbẹ naa ma palẹmọ gbogbo eto lori gbigbe asia ẹgbẹ fun Obaseki lati dupo Gomina naa labẹ orukọ ẹgbẹ wọn.

Gómìnà Godwin Obaseki yóò d'ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ́sẹ̀ yìí

O daju pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ni Gomina Godwin Obaseki nlọ, yoo si darapọ mọ ẹgbẹ naa ki eto idibo abẹle lati yan oludije ipo gomina ipinlẹ Edo lọjọ kọkandinlogun ati ogunjọ oṣu yii.

Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Edo, Tony Aziegbemi lo fi to BBC News leti bẹẹ.

O ni lootọ ko si idaniloju taarata pe oun ni yoo gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu naa nitori iwe ofin rẹ ko faaye gba bẹẹ ṣugbọn o daju pe Obaseki yoo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa.

Ọgbẹni Aziegbem ni bayii ohun to mumu lọkan oun gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Edo ni "lati rii daju pe gomina Ọbaseki darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa."

gomina Godwin Obaseki

Oríṣun àwòrán, facebook/godwin obaseki

Ni tirẹ, Kọla Ologbondiyan to jẹ agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ ṣalaye fun BBC pe "ki gomina Obaseki to lee di ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ṣan an, igbesẹ naa yoo bẹrẹ pẹlu ẹka ẹgbẹ oṣelu naa ni ipinlẹ Edo ki o to kan apapọ ẹgbẹ oṣelu ọhun."

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bakan naa, igbakeji gomina ipinlẹ Edo, Phillip Shaibu pẹlu ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.

Koda awọn aworan kan to n jade lori ayelujara ṣe afihan Shaibu nibi to ti n yọ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa danu ti o si n pariwo 'o digba fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ileejọba ipinlẹ Edo'

Ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹfa ni gomina Obaseki kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lẹyin ti wọn yọ ọwọ rẹ kuro lawo idije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu naa gẹgẹ bi oludije ipo gomina nibẹ.

Irọ funfun balau ni iroyin to tan kalẹ kaakiri lori ayelujara pe Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ologbondiyan lo sọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu lori ago pẹlu BBC Yoruba.

Ṣaaju ni igbimọ ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣayẹwo awọn oludije nipinlẹ Edo ti wọn yọ ọ kuro lara awọn oludije fun ipo gomina ninu idibo abẹle to n bọ.

Ṣugbọn Obaseki ti sọ pe ni oun ko ni pe ẹjọ kotẹmilọrun lori igbesẹ igbimọ naa.

Ẹwẹ, Ologbondiyan ni awọn ilana kan wa ti eeyan ni lati tẹle ki o to le darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

O ni ati wọọdu leyan ti le darapọ mọ ẹgbẹ, ati pe alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Edo ko sọ ohun to jẹ bẹẹ f'oun nigba tawọn mejeji jọ sọrọ.

Obaseki: Mi ò ní pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí bí APC ti yọ mí kúrò lára olùdíje ìbó abẹ́lé fún ipò gómìnà Edo

Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti tako igbesẹ igbimọ ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣayẹwo awọn oludije nipinlẹ Edo ti wọn yọ ọ kuro lara awọn oludije fun ipo gomina ninu idibo abẹle to n bọ.

Ṣugbọn Obaseki ni ohun ko ni pe ẹjọ kotẹmilọrun lori igbesẹ igbimọ naa.

Ohun ti wọn sọ ni pe kudiẹ kudiẹ si wa ninu awọn iwe ẹri rẹ ti fi mọ iwe ẹri agunbanirọ rẹ.

Godwin Obvaseki ati Adams Oshiomole

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adams Oshiomole

Ninu atẹjade ti Obaseki fi sita lọjọ Ẹti nipasẹ oluranlọwọ rẹ lori ọrọ iroyin, o ṣalaye pe ko ni itumọ ti oun ba ni ki oun pe ẹjọ kotẹmilọrun.

O fikun ọrọ rẹ pe bi wọn ti yọ oun kuro ninu awọn oludije ibo abẹle fun idibo gomina ipinlẹ Edo ko sẹyin bi alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomhole ti sọ pe oun ni ileẹjọ to ga julọ ninu ẹgbẹ naa.

O ni ohun itiju nla gbaa lo n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC labẹ alaga Oshiomole.