Police: Mo réèmọ̀ nígboro ayé, adigunjalè dìhámọ́ra lọ ja àgọ́ ọ́lọ́pàá lólè

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ole ba ja eeyan lawujọ, ibi ti eeyan kọkọ n morile naa ni agọ ọlọpaa nitori pe ẹni to ba to nii gba lo yẹ ka fọrọ lọ.
Ki ni ka ti wi ni ti iṣẹlẹ to ṣẹ leyi ti awọn adigunjale ti lọ ja agọ ọlọpaa lole. Ta ni ki wọn wa sa di o?
Ni orilẹede Ghana lọjọbọ, nṣe lawọn adigunjale kan ya bo agọ ọlọpaa kan lolu ilu orilẹede naa.
Awọn ọlọṣa naa wọ agọ awọn ọlọpaa naa ti wọn si ko awọn dukia kan to wa nibẹ lọ.
Lara awọn dukia ti awọn adigunjale naa ko ni ags ọlọpaa Nima to wa ni aringbungbun ilu Accra ni ẹrọ kọmputa alagbeka, tẹlifiṣan, awọn iwe atohun elo ikọwe to fi mọ ẹwu awọn ọlọpaa kan.
Nibayii awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ hulẹhulẹ iṣẹlẹ manigbagbe naa.
Iṣẹlẹ idigunjale naa ṣe ọpọ ni kayefi nitori kii si igba kan ti kii si ọlọpaa to n ṣọ agọ ọlọpaa naa. Bi a o ba si ranti daadaa, wọn kii tilẹkun ileeṣẹ ọlọpaa nitoripe awọn ọlọpaa kii ṣiwọ iṣẹ ọlọjọyipo.
Amọṣa awọn alaṣẹ ṣalaye pe ile iko nnkan ija si ati ibi ti awọn ti wọn timọle ba wa lawọn ọlọpaa maa n ṣọ ju lọ.













