FRSC thunder strike: Lẹ́yìn ìwádìí ìkú àrà tó sán pa òṣìṣẹ́ FRSC mẹ́ta lọ̀rọ̀ ètùtù kò ṣe ètùtù tó lè wáyé

Awọn ẹṣọ aabo ojuupopo

Oríṣun àwòrán, others

Ajọ to n risi eto irinna oju popo, FRSC ti ni awon ko lee fi idi ẹ mulẹ pe ara lo san pa oṣiṣẹ ajo FRSC mẹta to ku ni ipinlẹ Ogun.

Adari Ajọ FRSC nipinlẹ naa, Ahmed Umar lo sọ bẹ fun BBC lati mọ iru iku to pa awọn oṣiṣẹ naa.

Umar ni oun ti ajọ naa mọ ni wi pe ina lo sokunfa rẹ, bọya ina dede gbe wọn ni tabi ara lo san pa wọn, ati wi pe nitori naa ni awọn ṣe bẹrẹ iwadii lori rẹ.

Amọ, O fikun wi pe ti iwadii ba fidi ẹ mulẹ pe lootọ ara lo san pa wọn, oun ko le e ṣe ẹbo tabi ṣe etutu nitori ẹlẹsin Musulumi ni oun, oun ko si gbagbọ ninu rẹ.

Adari Ajọ FRSC nipinlẹ naa, Ahmed Umar wa fikun pe awọn yoo fi eri iwadii awọn lede lẹyin ti wọn ba ti pari iwadii wọn tan.

Àwọn akẹgbẹ́ ẹ̀ṣọ́ àjọ FRSC mẹ́ta tí àrá sán pa l'Ogun gbọdọ̀ ṣ'ètùtù- Elebuibọn

Awọn ẹṣọ aabo ojuupopo

Oríṣun àwòrán, Twitter/FRSC Twitter

Ikilọ ni iṣẹlẹ ara to san pa awon ẹṣọ alaabo oju-popo (Federal Road Safety Corps) meta, ti opo si farapa nipinlẹ Ogun.

Ẹlẹsin ibilẹ, Yemi Elebuibọn lo sọ bẹẹ nigba to ba BBC Yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Itele-Ijebu ni Old-gate ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni Ọjọru.

A gbọ wi pe bi ara yii ṣe san lo pa awon ẹṣọ meta naa loju ẹsẹ, to si jan awọn mii mọlẹ, ti gbogbo agbegbe naa si di erujeje.

Iroyin to tẹ wa lọwọ tun sọ pe awon oniṣango lọ ṣe etutu to yẹ ko to di pe wọn gbe oku wọn fun ijọba.

Amọ, baba Elubuibọn ni iṣẹ kan kii ṣẹ lasan, ti ko ba si nidi obinrin kii jẹ ikumolu.

Awọn ọlọpaa ati awọn ẹṣọ ojupopo

Oríṣun àwòrán, Twitter/FRSC Nigeria

Baba Ṣango kii ṣadeedee payan bayẹn ti ko ba jẹ wi pe awọn eeyan naa ti jale tabi ṣe nnkan aitọ kan.

Baba Elebuubọn ni o yẹ ki wọn ṣe etutu lati dena ajalu miiran papaa julọ awọn alabaṣiṣẹ pọ awọn to ku.