Abiola Ajimobi: Irọ́ ikú làá pa mọ́ àdá, kokoko lara baba wa le, ẹbí Sẹ́nétọ̀ Abiola Ajimobi pariwo síta láàrín ìròyìn ikú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiola ajimobi
Irọkẹkẹ iroyin nipa agba oṣelu, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi lo gba igboro kan lalẹ ọjọbọ nigba ti iroyin dede lu sita pe gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ naa ti dagbere faye; bẹẹ lawọn to sun mọọ pẹlu n pariwo irọ iku laa pa mọ ada, kokoko lara ọta le.
Lati bi ọsẹ diẹ sẹyin ni oniruuru ti n jade si oju opo ayelujara gbogbo nipa ipo ilera gomina ana nipinlẹ Ọyọ naa, Oloye Abiọla Ajimọbi.
- Fatima Ganduje, ìyàwó ọmọ Ajimọbi ní iró ni pé Bàbá ọkọ òun kú!
- Wo àwọn Gómìnà Naijiria tí àrùn Covid-19 ti bá fínra
- Àwọn akẹgbẹ́ ẹ̀ṣọ́ àjọ FRSC mẹ́ta tí àrá sán pa l'Ogun gbọdọ̀ ṣ'ètùtù- Elebuibọn
- Mo mọ̀ pé ibi tó dára ni Ibidun Ighodalo wà báyìí- Adeboye
- Seyi Makinde ṣí iléèwé padà ní ìpínlẹ̀ Oyo, Cross River pa ọ̀rọ̀ dà lórí ìwọlé akẹ́kọ̀ọ́
Bawo gan ni ọrọ ṣe bẹrẹ?

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiola ajimobi
Ni nnkan bii ọsẹ diẹ ni iroyin bẹrẹ si ni tan kalẹ pe sẹnetọ ajimọbi n ṣojojo ati pe ara rẹ ko le. Awọn eeyan kan to ms agba oṣelu ọmọ bibi ilẹ ibadan naa ti wọn si mọ pe kii ṣe ẹni ti a lee pa ohun ms agogo rẹ lẹnu pẹlu n miri pe o ṣeeṣe ko ri bẹẹ nitori o to ọjọ mẹta ti wọn gburo rẹ nita gbangba. Kia ti ikọ iroyin BBC News Yoruba gbọ iroyin yii nigba naa lo tọ awọn to sun mọ agba oṣelu naa bi iṣan ọrun lọ lati mọ ootọ ọrọ nigba naa ti wọn si fi to wa leti pe ko sohun to jọ bẹẹ ati pe ara rẹ ya gaga bi ara akẹkọọ aṣọ.
Ko pẹ pupọ ni ẹka ẹgbẹ oṣelu APC nilẹ Gẹẹsi APC UK chapter gbe iroyin kan jade loju opo ayelujara wọn ti wọn fi n ki agba oṣelu naa pe ko maa faraalẹ o.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Too, a mu ẹnu ro nigba naa, gbogbo aye si ba ko lee daa bọ. Amọṣa ko tun pẹ pupọ ni iroyin miran ba tun lu igboro kan pe aisan to n ṣe agba oṣelu naa tun ti burẹkẹ sii koda wọn ti gbee si ẹka awọn alaisan tọrọ wọn le diẹ nileewosan aladani kan ti a ko ni fẹ darukọ nilu Eko. Lẹẹkan si a tọ agbẹnusọ fun oloye Ajimọbi lọ, ohun pẹlu si ni lootọ ara rẹ ko ya amọ irọ to jinna sootọ ni pe o daku lọ gbọrangandan nileewosan gẹgẹ bi awọn kan ṣe n sọ ọ kaakiri nigba naa.
Ki lo ba ti iroyin o ku, ko ku jade.
Ni aṣalẹ Ọjọbọ lawọn kan bẹrẹ lori ayelujara pe agba oṣelu naa ti jade laye. Gboogi lara awọn wọnyii ni Fisayọ Soyọmbọ ti ọpọ mọ si oniroyin lori yaelujara. Ninu atẹjade rẹ kan loju opo twitter lo ti kọkọ kede pe eeyan oun kan 'ti ko ja oun kulẹ ri' sọ pe Abiọla Ajimọbi ti jade laye,
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

End of X post, 3
Amọṣa ni kia masa werewere lawọn ẹbi oloogbe naa ti bọ sigboro lati bu omi pa iroyin naa eyi ti wọn ni irọ gbuu lasan ni.
Bakan naa ni wọn tun ṣalaye pe lootọ ara Ajimọbi ko ya, sibẹ o wa laaye ko ku.
Lara awọn to kọkọ jade sọrọ ni iyawo ọmọ rẹ Fatima Ganduje Ajimobi. ṣe ẹ ko gbagbe pe bi ọdun meji sẹyin ni Ajimọbi ko ẹbi ara ati ọrẹ lọ ṣe idana nilu Kano ni ile gomina Ganduje nibiti o ti mu Fatima ọmọ Ganduje fi ṣe aya fun ọmọ rẹ.
Fatima ọhun lo bọ sita loju opo twitter to kọkọ wi pe, 'Alhamdulilah, baba wa ṣi wa laye'
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Bakan naa ni agbẹnusọ fun Abiọla Ajimọbi, Tunji Bọlaji ṣalaye pe ko si ootọ ninu rẹ. O ni gbogbo ohun tawọn kan n gbe kiri nipa ilera rẹ lati bi ọsẹ diẹ sẹyin kii ṣe ootọ.
Bakan naa ni Kẹmi Olunlọyọ ti oun pẹlu sun mọ idile naa naa ṣalaye pe ko si ootọ ninu iroyin naa ati pe lẹyin ti oun ba ọmọ agba oye ilẹ ibadan naa sọrọ, o jẹ ko da oun loju pe aaye ni Abiọla Ajimọbi kii ṣe oku ni bi a ṣe n sọrọ yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5