Coronavirus Nigeria : Àwọn gómìnà Naijiria mẹ́rin tó tí ní àrùn Coronavirus

Govs

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lati igba ti arun Coronavirus ti rapala wọ orilẹ-ede Naijiria loṣu keji ọdun 2020, ọpọlọpọ eeyan ni o ti ran.

Lara awọn to ti ko arun naa ni a ti ri gomina, olori oṣiṣẹ aarẹ, awọn oṣiṣẹ eto ilera ati ọpọ awọn eeyan miran lawujọ.

Pupọ ninu awọn gomina to ko arun naa lo ti gba iwosan.

Awọn gomina ipinlẹ ni Naijiria to ti ni arun Coronavirus ree:

Seyi Makinde, Oyo

Ọgbọn ọjọ, ọṣi Kẹta ọdun 2020 ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kede loju opo Twitter rẹ pe oun ti ni arun Covid-19.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

O ni "Mo ṣẹṣẹ gba esi ayẹwo Covid-19 ti mo ṣe, esi naa si fi han pe mo ti ni arun naa. Bo tilẹ jẹ pe mi ko safihan apẹrẹ arun ọhun, mo maa fi ara mi si igbele."

Lẹyin naa lo kede pe oun ti yan adari fasiti ẹkọṣẹ iṣẹgun to wa ni ilu Ibadan, Temitope Alonge lati tukọ igbimọ amuṣẹya to n ri si ọrọ arun naa ni ipinlẹ Oyo.

Kayode Fayemi

Ojumọ ọjọ kejilelogun oṣu keje ọdun 2020 ni gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi kede loju opo Twitter rẹ pe oun ti lugbadi arun Covid-19.

Fayemi sọ pe igba kẹta ti oun ṣayẹwo arun naa ni esi fi han pe oun naa ti darapọ mọ awọn to ni arun ọhun ni Naijiria.

Makinde, Ikpeazu ati El Rufai

Oríṣun àwòrán, others

Lẹyin naa lo ni oun ti ni ki igbakeji oun ma a tukọ ilu lọ, ti oun yoo si ma a ṣiṣẹ lati iyẹwu.

Bala Mohammed, Bauchi

Ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹta ọdun 2020 ni iroyin gbode kan pe Bala Mohammed, to jẹ gomina ipinlẹ Bauchi ti ni arun Coronavirus.

Ṣaaju akoko naa, gomina ọhun ti kopa ninu ọpọ ayẹyẹ nibi to ti ṣalabapade ọpọ ero.

Oluranlọwọ agba fun gomina ọhun, Mukhtar Gidado sọ ninu atẹjade kan pe gomina naa ti ṣalapade ọmọ igbakeji aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar, ti oun naa ni arun ọhun.

Bala

Oríṣun àwòrán, @daily_nigerian

Malam Nasir El-Rufai, Kaduna

Gomina ipìnlẹ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai funra rẹ lo fi fidio kan lede loju opo Twitter ijọba ipinlẹ naa pe oun ti ni arun Coronavirus.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

El-Rufai sọ ninu ikede ọhun pe oun yoo wa ni idanikanwa gẹgẹ bi ilana ajọ to n ri si idena ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC ṣe gbe kalẹ.

Ko pẹ si ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹrin ti gomina ọhun moribọ lọwọ arun naa.

Àkọlé fídíò, #JusticeforTina: Àwọn obi Tina Ezekwe ń bèrè fún ìdájọ́ òdodo pẹ̀lú omijé lójú

Okezie Ikpeazu, Abia

Afẹmọju ọjọ Kẹjọ, oṣu kẹfa ọdun 2020 ni iroyin kan jade pe gomina ipinlẹ Abia, Okezie Ikpeazu naa ti fara kasa arun Covid-19.

Ni igba to n b a BBC sọrọ, agbẹnusọ gomina ọhun, Onyebuchi Ememanka sọ pe gomina naa ti wa ni igbele, ati pe awọn akọṣẹmọṣẹ dọkita ti n ṣe itọju rẹ.

Ẹmemanka ni Ikpeazu kọ ni gomina akọkọ ti yoo ni Coronavirus ni Naijiria, ati pe oun naa yoo ru la bi awọn akẹgbẹ rẹ iṣaaju.

Lọwọ yii, apapọ awọn to ti ni arun Coronavirus kaaakiri orilẹ-ede Naijiria ti di 12486, awọn 3959 lo ti ri iwosan gba, nigba ti awọn 354 ti dero ọrun nitori arun ọhun.

Abia

Oríṣun àwòrán, Abia state Government

Awọn to ṣayẹwo ṣugbọn ti ko ni Covid-19

Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ṣe ayẹwo arun Coronavirus ṣugbọn ori koo yọ

Akeredolu sọ loju opoTwitter rẹ pe Kọmisọnna eto ilẹra nipinlẹ Ondo lo fi esi ayẹwo naa sita pe oun ko ni arun Coronavirus.

Àkọlé fídíò, Say no to rape: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá pariwo síta lórí wàhálà ìfipábánilòpọ̀

O dupe lọwọ Olorun fun aṣeyọri esi ayẹwọ naa, o si gbadura fun awọn to ti ni arun naa pe ki Olorun fun wọn ni iwosan pipe.

bakan naa ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu naa ṣe ayẹwo arun naa lẹyin ti mẹwaa lara awọn to n ṣiṣẹ nile ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Marina lugbadi arun ọhun.

Ṣugbọn esi ayẹwo oun ati iyawo rẹ fi han pe awọn memeji ko ni arun naa.

Àkọlé fídíò, Báyìí ni ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọmọnìyàn ṣe pè fún ìdájọ́ ikú fún àwọn afipábánilòpọ̀