Ajikanle ní òun ti ta ọ̀pọ̀ dúkìá lórí apá àti ẹsẹ̀ tó rọ láti ọdún kẹta náà

Oríṣun àwòrán, Instagram/murphyafolabi20
Yoruba ni ẹni ti ija ko ba, nii pe ara rẹ ni ọkunrin, bi ere ba si ba ẹdun nilẹ, yoo di ọlẹ ni.Bẹẹ ni ọrọ ri fun gbajumọ oṣere tiata kan, Mufutau Ajikanle, ẹni ti apa ati ẹsẹ rẹ ti rọ lati ọdun mẹta sẹyin.Nigba to n salaye ohun ti oṣere tiata naa n la kọja faraye, gbajugbaja oṣere tiata miran, Murphy Afolabi sọ loju opo Instagram rẹ pe, ọkunrin naa nilo iranwọ araalu kiakia.
- Ayálégbé wa tó fi tipá já àbálé mi ṣe àkóbá fún ìgbé ayé mi - Foluke Daramola
- Ọmọ pupa làwọn olólùfẹ́ wa fẹ́ wò nínú fíìmù làwọn òṣèré tíátà fi ń bóra- Muka Ray
- Níbo ni Sẹ́nétọ̀ Abiola Ajimobi, gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Oyo wà?
- Olorì Anu Adeyemi ń ṣe ọjọ ìbí, ẹ gbọ́ ǹkan tò sọ sí Kábíyésì
- Ẹ wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó jogún eré ṣíṣe lọ́dọ̀ òbí wọn
- Nàìjíríà kò ní olórí, ẹ pín sí ẹlẹ́kùnjẹkùn - Soyinka
Ninu fidio to gbe jade ọhun ni Ajikanle, ẹni to ko ipa ribiribi ninu sinima Mufu Olosha Oko ati Olosha Molete, ti n bẹbẹ si araalu pe ki wọn saanu oun pẹlu iranwọ owo.
Mufutai, to jokoo lori ibusun pẹlu ọpa lọwọ ni "ibi ti wọn ti n tọju mi ni mo wa, n ko ni alaafia rara, awọn ẹgbẹ ti mo n ṣe ati awọn ọrẹ ti gbinyanju, ti mo si ti ta dukia mi tan."O wa bẹbẹ pe "ẹ saanu mi, Ọlọrun ko ni fi aarẹ ṣe yin, a ti nawo sẹyin lai ri iwosan, amọ mo sẹṣẹ wa ri ibi ti wọn yoo ti tọju mi daadaa bayii ni, sugbọn ko si owo mọ."
- Ẹ sọ ìlò afẹ́fẹ́ aláta àti ìbọn ònírọ́bà di òfin fáwọn obìnrin - Oluwo
- Èèyàn 389 ló tún lùgbàdì àrùn Coronavirus ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní Naijiria
- Ìlú yóò le, ọmọ le kú, àìsàn yóò pọ̀ bí eégún kò bá jáde nílùú Ibadan - Olóòlù
- ₦35,000 ni mò ń gbà bíi Adelé ọba, kò sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ - Adelé Olúbọ̀rọ̀paAjikanle wa bẹ awọn ẹlẹyinju aanu lati bun owo lowo fi tọju apa kan, ẹsẹ kan to rọ naa nitori ko si iranwọ lati ibikíbi mọ.O ni gbogbo dukia tí oun fi aarọ ọjọ aye oun ko jọ ni oun ti ta tan lori aisan naa, to si n rọ ọmọ Naijiria lati ran lọwọ.








