Yoruba culture: Adelé Olúbọ̀rọ̀pa ní ọmọ ọdún 16 ni òun jẹ́ Adelé, kó tó lọ sí Fáṣítì

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialoluboropa_of_iboropa
Adelé Olúbọ̀rọ̀pa tilu Bọ̀rọ̀pa, Ọmọọba Tinuade Babalola Adejuyigbe ti koro oju si bi ko ṣe si itọju gidi fun awọn ọba alaye ati awọn Adelé.
Adelé Olúbọ̀rọ̀pa woye ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto kan ni ikanni BBC Yoruba.
Adelé Adejuyigbe ni ẹgbẹrun lọna marundinlogoji naira ni oun n gba lowo osu eyi ti ko ran nkankan, bẹẹ ni ijọba ko fun oun ni ọkọ ayọkẹlẹ nidii.
"Ọpẹlọpẹ awọn araalu to n fun mi lowo, oun ni mo fi n gbọ bukata ara mi, ko si apọnle kankan fun wa."
Adelé, ẹni to ṣẹṣẹ jade nile ẹkọ fasiti, to si n sinru ilu lọwọ, wa mọ riri atilẹyin iya rẹ ati awọn ijoye rẹ, o ni itọni wọn lo mu ko rọrun fun oun lati dari ilu.
Nigba to n sọ iriri rẹ lasiko to wa nile iwe, ọba alaye lobinrin naa to ti lo ọdun marun lori itẹ tun salaye pe, oun kii pa idanwo ati kilaasi jẹ, ti awọn olukọ si da oun mọ pẹlu buba, Sokoto ati ilẹkẹ lọwọ ati lọrun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialoluboropa_of_iboropa
Lori ọrọ ifẹ pẹlu ọkunrin, Adele Olúbọ̀rọ̀pa ni "lootọ ni awọn ọkunrin n wa mi wa amọ n ko gbọdọ ba ara mi jẹ nipa nini ibalopọ gẹgẹ bii Adelé nitori eewọ nla ni, asa wa ko gba ki n lo ifẹ ikọkọ tabi sun mọ ọkùnrin."
Ọba alaye lobinrin ọhun, to ni oun ko tii ni afẹsọna kankan, wa rọ ijọba lati maa ran awọn ọba alaye ati adele lọwọ.












