WAEC: ANCOPSS ní òun àti ẹgbẹ́ olùkọ́ yóò ṣèpàdé lọ́jọ́ Ẹti lórí ìpínu ìjọba àpapọ̀

Akẹkọọ kan n kọwe idanwo

Oríṣun àwòrán, dnt

Ẹgbẹ agbarijọpọ awọn ọga ileẹkọ girama jakejado Naijiria (ANCOPSS) kede pe, iyalẹnu nla ni ikede ijọba apapọ jẹ pe awọn akẹkọọ ko ni se idanwo asejade WAEC mọ lọdun 2020.

Alaga apapọ ẹgbẹ Ancopss lorilẹede yii, Anselm Izuagie ni haa-hii ni ikede ijọba apapọ naa si jẹ fun awọn, lẹyin ọjọ kan ti minisita feto ẹkọ ti fi ikede ọhun sita.

Ancopss ni oun bawọn peju sibi ipade awọn eeyan ti eto ẹkọ gberu lọjọ Isẹgun to kọja, nibi ti gbogbo awọn ti fẹnu ọrọ jona.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni adehun tawọn se ni pe ki eto idanwo WAEC waye, pẹlu sise awọn ilana eto aabo kan.

Olukọ ati awọn akẹkọọ ni kilaasi

"Nibi ipade naa la ti se gbogbo agbeyẹwo ati eto aabo fun gbogbo awọn eeyan ti ọrọ kan, ti yoo kopa ninu eto idanwo naa.

A si fẹnu ko pe asise kankan ko gbọdọ waye, amọ ni kete ta pẹyinda tan, ni minisita feto ẹkọ sọ nnkan miran sita."

Izuagie ni ẹgbẹ Ancopss yoo pada se ipade lọjọ Ẹti pẹlu ẹgbẹ awọn olukọ, NUT, lati se agbeyẹwo gbogbo ọrọ naa, ti wọn yoo si fi ikede wọn sita fun araye.

Àwọn ilé ìwé Unity School kò ni kópa nínú ìdánwò WAEC nítorí Coronavirus - Ìjọba àpapọ̀

Awọn akẹkọọ kan n kọwe idanwo

Oríṣun àwòrán, legit

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, ijọba apapọ ni awọn ile iwe girama ijọba apapọ, Unity Schools, ko ni kopa ninu idanwo WAEC ọdun yii titi di igba ti o yẹ.

Minisita eto ẹkọ, Adamu Adamu lo kede bẹẹ nibi ipade kan to waye lori ayelujara.

Lẹyin naa lo gba ajọ WAEC atawọn ijọba ipinlẹ ni imọran lati ma ṣi awọn ile iwe lasiko yii nitori o lewu lati ṣe bẹẹ.

Ṣaaju ni alaga igbimọ amuṣẹya to n ri si ọrọ Covid-19 ni Naijiria, PTF, Boss Mustapha ti kọkọ sọ pe ipele awọn akẹkọọ kan yoo pada sẹnu ẹkọ wọn lọna ati gbaradi fun idanwo aṣekagba.

PTF ni o ṣe pataki ki awọn ọmọ ile iwe to wa ni ipele kẹta akọkọ ile iwe girama, JSS 3, ati awọn to wa ni ipele kẹta keji, SSS 3 pada sile iwe.

Wọn ni akoko naa yoo fun awọn akẹkọo ọhun laaye lati gbaradi fun idanwo to n bọ lọna.

Ṣugbọn Adamu ti sọ pe ko yẹ ko ri bẹ nitori bi ẹni fi ẹmi awọn ekẹkọọ wewu ni ọrọ naa yoo ja si.

Adamu pari ọrọ rẹ pe "O lewu lati ṣi ile iwe bayii."

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣeyin?

New WAEC timetable 2020: Ọjọ́ Kẹrin oṣu Kẹ́jọ ni ìdánwò WAEC yóò bẹ̀rẹ̀ - Mínísítà ètò ẹ̀kọ́

Akẹkọọ kan n kọwe idanwo

Oríṣun àwòrán, dnt

Ijọba apapọ ti kede pe idanwo aṣepari ni ileewe girama, WAEC, yoo bẹrẹ lọjọ kẹrin oṣun Kẹjọ ọdun 2020.

Minisita eto ẹkọ, Emeka Nwajiuba lo fi ọrọ naa lede nigba ti igbimọ amuṣẹya ijọba apapọ n jabọ ibi iṣẹ de duro lori ọrọ Covid-19 ni Naijiria.

O ni "A ti ṣe iwọn ti a le ṣe pẹlu ajọ WAEC, a dẹ n fi akoko yi sọ fun yin pe idanwo naa yoo bẹrẹ lati ọjọ kẹrin oṣu Kẹjọ titi di ọjọ karun un oṣu kẹsan an ọdun 2020."

Nwajiuba sọ pe aye oṣu kan wa fun awọn ile iwe atawọn ipinlẹ to ba nifẹ si ṣiṣe idanwo naa lati pese awọn ile iwe wọn silẹ fun idanwo ọhun.

Minisita naa sọ pe ileeṣẹ eto ẹkọ yoo pese atẹjade awọn akoko ti idanwo ọhun yoo waye lẹyin ipade pẹlu ajọ NCDC, ẹgbẹ awọn olukọ, NUT, atawọn ajọ miran ti ọrọ kan.

Nwajiuba sọ pe idanwo NECO ati NABTEB yoo bẹrẹ ni kete lẹyin ti wọn ba ti pari idanwo WAEC ọhun.

Ọdun1952 ni wọn gbe idanwo WAEC kalẹ fun awọn akẹkọ lawọn orilẹ-ede iwọ-oorun ilẹ Afirika ti wọn ti n sọ ede Gẹẹsi.

When is WAEC 2020 starting: Ajọ onídánwò WAEC ní kété tí wọ́n bá ṣí iléèwé padà ní ìdánwò WASSCE yóò bẹ̀rẹ̀

Awọn akẹkọọ kan n kọwe idanwo

Oríṣun àwòrán, legit

Ajọ to n ṣe kokari idanwo aṣepari ni ileewe girama, WAEC ti ṣalaye wi pe oun ti ṣetan bayii lati ṣeto idanwo fawọn akẹkọs oniwe mẹwaa lorilẹede Naijiria.

Ajọ naa ni oun to wa laarin ajọ naa ati ṣiṣe idanwo fawọn akẹkọọ oniwe mẹwaa lọdun yii ni ilana ti ijọba ba gbe kalẹ ati ṣiṣi awọn ileewe pada.

Ni ọjọ aje ni igbimọ amuṣẹya ti ijọba apapọ gbe kalẹ lori arun coronavirus lorilẹede Naijiria, PTF ṣalaye pe awọn ileewe ati ileeṣẹ eto ẹkọ nijọba apapọ gbọdọ joko lati fẹnuko lori ilana ti eto ẹkọ yoo gba bi wọn yoo ba ṣi ileewe pada; paapaa fun awọn akẹkọọ onidanwo aṣejade bii WAEC, NECO ati bẹẹbẹẹ lọ.

Nigba ti alukoro ajọ onidanwo aṣekagba girama, WAEC, Ọgbẹni Damian ba ileeṣẹ BBC News Yoruba sọrọ, o ni ohun ti awọn n reti bayii naa ni awọn ilana ti ijọba apapọ atawọn ijsba ipinlẹ ba fẹnuko le lori.

O fi kun un pe bi awọn ileewe ba lee di ṣiṣi pada, aaya bẹẹ lẹ o bẹ s'are ni fun awọn nitori awọn ṣetan lati ṣe idanwo naa ni kete ti wọn ba ti ri ilana gba lati ọdọ ijọba lori ọna ti eto ipada si ileewe yoo gba bayii.