UN Plane Crash: Èèyàn méjì, tó fi mọ́ ọmọ ọdún márùn-ún ló kú nínú bàálù tó já ní Borno

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti leri leka pe ijọba oun yoo gbẹsan ikọlu si baalu ajọ isọkan agbaye ti wọn ja lulẹ, eyi to mu ẹmi eeyan meji lọ.

Aarẹ wa se apejuwe isẹlẹ naa to waye ni nipinlẹ Borno to wa ni ẹkun ariwa orilẹede Naijiria bii 'isẹlẹ laabi' ti ko ni lọ lasan, lai ni 'ipa buruku'.

Ọmọ ọdun marun kan wa lara awọn eyan meji to ku lasiko ikọlu naa to waye lọjọ Satide, eyi ti wọn lo jẹ isẹ ọwọ awọn adunkookomọni. To n daamu ẹkun ariwa Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ti le ni ọdun mẹwa ti wọn ti n lo ọkọ ofurufu naa lati gbe awọn ohun eelo iranwọ lọ sọdọ awọn araalu to wa lagbegbe naa, ti laasigbo to n waye nibẹ n ba finra.

Ni bayii, ajọ isọkan orilẹede agbaye ti dẹkun kiko eroja iranwọ lọ si agbegbe naa

Àkọlé fídíò, Mama Arsenal: Màmá àgbà yìí máa ń lọ sí ìbùdó tí wọ́n ti ń wo bọ́ọ́lù láti wòran

Buhari se'pade pajawiri

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe aarẹ Muhammadu Buhari ti n ṣe awọn ipade pajawiri nilu Abuja loni latari ipo ati irisi orilẹ ede Naijiria.

Atẹjade kan lori opo ayelujara twita fun ọkan ninu oluranlọwọ fun aarẹ, Bashir Ahmad sọ pe awọn gomina mẹfa se ipade ikọkọ pẹlu aarẹ ni ọjọbọ. Ko sọ ohun ti ipade naa dale lori.

Aarẹ Buhari pẹlu awọn ọmọ igbimọ rẹ kan

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Eto aabo to peye ti jẹ ipenija nla fun orilẹede Naijiria

Awọn gomina ti o wa nibẹ ni, Atiku Bagudu ti ipinlẹ Kebbi, Udom Emmanuel lati ipinlẹ Akwa Ibom ati Aminu Masari ti ipinle Katsina.

Awọn ẹlomiran ni awọn gomina Dafidi Umahi ti ipinlẹ Ebonyi, Simon Lalong ti o jẹ gomina ipinlẹ Plateau ati alaga ẹgbẹ awọn gomina orilẹede Naijiria, Abdulaziz Yari ti o jẹ gomina ipinle Zamfara.

Nipa ti awọn Gomina, o tẹ bayi pe:

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ipade lori ọrọ aabo orilẹede.

Atẹjade Basir Ahmad lori ẹrọ Twitta wi bayi pe:

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2