LASTMA: Ẹ̀sùn àgbèrè la gbọ́ pé ó fá ìjà, tó já sí ikú náà

Oríṣun àwòrán, Others
Oṣiṣẹ ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ loju popo nipinlẹ Eko, LASTMA, Emmanuel Mekuri, ti gbẹmi ara rẹ, lẹyin to pa ololufẹ rẹ.
Iroyin sọ pe ija lo waye laarin Emmanuel ati ololufẹ rẹti wọn jọ n gbe, Patricia Ogunshola, ni ile wọn to wa ni Araromi, Morogbo nipinlẹ Eko.
Ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ni wọn pe Emmanuel, ti Patricia si jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji.
- Obìnrin kan pa ara rẹ̀ nítorí pé ọ̀kọ̀ rẹ ń dẹ́yẹ síi pé o dúdú jù
- Irú kí lèyì? Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì í bọ ara rẹ̀ náà níkùn
- Ènìyàn 544 ni èsì àyẹ̀wò fihàn pé ó tún ti ní ààrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Mo ti bá ọmọ ọwọ́ mẹ́ta lòpọ̀ sẹ́yìn, ọmọ oṣù mẹ́ta ló ṣìkẹrin - Afurasí jẹ́wọ́
- Obìnrin kan wọ gàù lẹ́yìn tó kan ìṣó mọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ẹni ọdún mẹ́wàá lórí
Gẹgẹ bi a se gbọ, ede aiyede na da lori iwa agbere, eyi to yọri si kiko ẹṣẹ bo ara ẹni.
A gbọ pe lasiko ija naa ni Emmanuel binu mu ọbẹ, to si fi gun Patricia ni itan, ko to o di pe Patricia raaye sa jade.
Lẹyin naa ni Emmanuel fi ọbẹ naa gun ara rẹ ni ikùn.
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko sọ pe, ariwo ti ọmọ Patricia pa, lo jẹ ki awọn alajọgbele wọn o mọ nipa nkan to ṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Oku Emmanuel si ni awọn ọlọpaa ba nilẹ pẹlu ọbẹ naa nigba ti wọn pe wọn sibi isẹlẹ ọhun.
Iroyin ọhun tẹsiwaju pe, wọn gbe Patricia lọ sile iwosan fun itọju, ti wọn si ti gbe oku Emmanuel lọ sile igboku si.
Iru iṣẹlẹ bayii ko ṣẹṣẹ ma a waye l'orilẹ-ede Naijiria laarin ololufẹ.
A kò mọ ẹni tó pa ọlọ́pàá Ondo àti ìyàwó rẹ̀, òun kọ́ ló pa ara rẹ̀- ọlọ́pàá
Saaju la ti sọ fun yin pe irọ ni iroyin kan to sọ pe ọlọpaa kan ti wọn pe orukọ ni Tolulọpe pa iyawọ ati ara rẹ lori ẹsun pe iyawo naa n ṣe agbere.
Ọjọ kejila, oṣu Kẹta, ọdun 2020 ni iṣẹlẹ naa waye nilu Akungba-Akoko.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba, Ọgbẹni Tee-Leo Ikolo wi pe pẹlu ayọ ati idunnu ni ọlọpaa naa fi kuro nibi iṣẹ rẹ to wa ni Akungba Akoko, oun pẹlu aya ati awọn ọmọ wọn.
Ọgbẹni Ikolo ni ṣa deedee lawọn lawọn gbọ iro ibọn lati ile ọlọpaa ọun eyi to kọju si ago ọlọpaa to ti n ṣiṣẹ niluu Akungba Akoko
- Ẹ yọmí kúrò ní àhámọ́! Sanusi pe Ọ̀gá ọlọ́pàá àti Ọ̀gá DSS lẹ́jọ́
- UEFA wọ́gilé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Real Madrid àti Manchester City nítorí coronavirus
- "Owó oṣù òṣìṣẹ́ yóò di gbèsè, oúnjẹ yóò wọ́n, ìlú yóò le, bí ọrọ̀ ajé Náíjíríà bá dagun"
- Nàìjíríà bèèrè ìrànwó lọ́wọ́ àjọ àgbáyé láti kápá Coronavirus
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé ìdọ̀tí rẹ le è sọ ẹ́ di olówó?
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé ìdọ̀tí rẹ le è sọ ẹ́ di olówó?
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni nigba tawọn de ibẹ lawọn ba oku ọlọpaa naa ati iyawo rẹ nilẹ.
O ṣalaye pe iwadii si n lọ lọwọ lati mọ ohun to ṣe okunfa iku awọn mejeeji gan an.
Ọgbẹni Ikolo ni ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe ọmọ ọwọ ati ọmọ ọdun meji ti iyawo naa n gbe lọwọ to fi ku fun mama iyawo naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo ṣalaye fun araalu ohun to fa iku awọn mejeeji ti iwadii ba ti pari.












