Coronavirus: 'Gbogbo àgbáyé gbọ́dọ̀ pawọ́pọ̀ láti borí àrùn Coronavirus'

Coronavirus
Àkọlé àwòrán, Ènìyàn méjì ló tí lùgbàdì àrùn náà lórílẹ̀ède Naijiria, tó sí ti pa ẹgbẹgbẹrun ènìyàn káàkiri àgbáyé.

Orilẹede Naijiria ti ke si ajọ agbaye lati pese iranwo awọn ohun elo idaabobo fun awọn ọmọ Naijiria lati koju arun Coronavirus.

Minisita fun eto ilẹra lorilẹede Naijiria, Dokita Osagie Ehanire lo kesi awọn ajọ naa lati pese ẹrọ ayẹwo Thermo Scanners ati awọn ohun elo idaabobo ara ẹni fun Naijiria.

Minisita naa lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni orilẹede Naijiria ko ni awọn ohun elo to to lati ṣe ayẹwo ni awọn papakọ ofurufu ati ibudokọ kaakiri Naijiria.

Bakan naa lo fikun pe orilẹede Naijiria ko ṣetan lati ti awọn papako rẹ, tabi fi ofin de irinna ọkọ ofurufu lati orilẹede kan si omiran to n ba arun Coronavirus finran.

Coronavirus

O ni orilẹede kọọkan lo n gbe igbeṣe ti wọn mọ wi pe yoo ṣe awọn ọmọ ilẹ wọn ni anfaani, nitorinaa loun ṣe woye wi pe ayẹwo to peye ni awọn papakọ ofurufu Naijiria yoo ko ipa to dara lati kapa arun naa.

Coronavirus

Minisita fun eto ilera naa wa rọ awọn orilẹede to ku lagbaye lati mura sii ki wọn ma a ṣe ayẹwo awọn eniyan wọn ti o ba n jade kuro ni orilẹede wọn lọ si ibomiran.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, CDC

Minisita naa fikun un wi pe gbogbo orilẹede gbọdọ pawọpọ lati gbogun ti arun naa, ki gbogbo arun naa le di ohun igbagbe.

Ará Yúróòpù ẹ fìdí mọ́lé yín, mo ti gbé ìlẹ̀kùn Amẹ́ríkà tìpa torí Coronavirus - Trump

Aarẹ orileede Amẹrika, Donald Trump ti kede awọn igbesẹ tuntun lati koju itankalẹ aisan Coronavirus, eleyi to ni ṣe pẹlu irinajo lati Yuroopu si Amẹrika.

Labẹ aṣẹ tuntun yii, eleyi to fi sita lori ẹrọ amounmaworan, Trump ni awọn ti so irinajo awọn eeyan lati Yuroopu si Amẹrika rọ fun ọgbọn ọjọ gbako.

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump
Àkọlé àwòrán, Aarẹ Donald Trump ni ikede yi ko kan awọn Amẹrikato ba n bọ lati Yuroopu

Ṣugbọn, o ni igbesẹ naa ko ni kan ilẹ Gẹẹsi nibi ti eeyan ẹtalelọgọtalelenirinwo ti ko aisan naa.

Ni orileede Amẹrika, o le ni ẹgbẹrun kan eeyan to ti ko aisan naa, ti eeyan mejidinlogoji si ti padanu ẹmi wọn.

Aarẹ Trump sọ lati ọọfisi rẹ pe ''Lọna ati mase jẹ ki iṣẹlẹ aisan tuntun wọ ilẹ wa, a ti so gbogbo irinajo eeyan lati Yuroopu si ilẹ wa rọ''

Awọn ọlọpa Amẹrika to bo imu tori Coronavirus

Oríṣun àwòrán, @dcexaminer

''Ago mejila ọjọ Ẹti ni awọn igbesẹ yii yoo gberasọ''

O fi kun pe aṣẹ ọhun ko kan awọn ọmọ orileede Amẹrika to n pada bọ wa sile lati Yuroopu.

Aworan awọn ton de ibomu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Trump tẹsiwaju pe ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, EU ti kuna lati gbe awọn igbesẹ iru eleyi tawọn gbe, lati fi koju aisan naa.

Asẹ ti wọn gbe jade ni kete ti aarẹ Trump pari ọrọ rẹ laa kalẹ pe, igbesẹ ọhun kan ẹnikẹni to ba ti wa ni ibode EU Schengen, laarin ọjọ mẹrinla ṣaaju ki wọn to de si Amẹrika.

Àkọlé fídíò, Waste to Wealth: Ẹ̀gbin tìrẹ ni èròjà táwọn èèyàn míràn fi n ṣiṣẹ́ ajé, okoòwò ńlá ni

Ohun ti eleti tumọ si ni pe, orileede Ireland ko ni si lara awọn ilẹ yi nitori pe ko si lara awọn orileede ibode Schengen mẹrindinlọgbọn to wa.

Bulgaria, Croatia ati Romania wa lara awọn orileede ajọ EU bo tilẹ jẹ pe wọn ko si ni agbegbe ti ibode Schengen kan.