Coronavirus: Ẹ wo ọ̀nà tí ọrọ̀ ajé Náíjíríà tó dẹnu kọlẹ̀ yóó fi ṣàkóbá fún aráàlú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oju ọjọ lẹka ọrọ aje ni Naijiria ṣe bi ẹni ṣokunkun nitori bi ojojo ti n se ogun katakara epo rọbi lagbaye, ti owo agba epo rọbi si ja walẹ.
Eyi ko ṣẹyin ija ọrọ aje to n waye laarin orileede Russia ati Saudi Arabia, to fi mọ airi agba epo ta, ti aisan Coronavirus naa ṣokunfa rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Arìnrìn àjò tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé gbé, ábẹ́ ààbò ọjọ́ mẹ́rìnlá ni wọn yóò wà torí Covid19 - Uganda
- Mò ń fojú sọ́nà láti bá Emir àná, Sanusi kírun lọ́jọ́ Jímọ̀ - Aráàlú Awe
- Ẹ múra o, epo rọ̀bì di òkùtà lọ́jà torí Coronavirus, ìlú yóò le koko - NNPC figbe ta
- Ẹ́ gbaradì, to bá lo jẹnẹrátọ̀ àbí tà á, ò ń fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá ṣeré - Sẹ́nétọ̀ ń dábàá
Bi nkan ṣe ri bayii, ti banki apapọ Naijiria ti ni kawọn eeyan ma mura silẹ de igba ti yoo le diẹ lẹka ọrọ aje, lo mu ki BBC Yoruba fọrọ wa awọn onimọ nipa ọrọ aje lẹnu wo, lati ṣalaye ohun ti awọn ọmọ Naijiria yoo ba pade nigba ti ọrọ aje ba dagun.
Ijakulẹ ọrọ aje Naijiria di dandan
Onimọ kan nipa eto ọrọ aje ọmọwe Chijioke Ekechukwu ni iru nkan bayi ko ṣẹṣẹ ma ṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
O ni gbogbo igba ti nkan ba ti deba owo epo rọbi lagbaye yala owo rẹ lọ si oke tabi o walẹ, o di dandan ki Naijiria mọ lara.
Latari iṣẹlẹ eyi ti o mu iye owo epo rọbi walẹ di bi ọgbọn dọla lati ọgọta dọla, Ọmọwe Chijioke sọ pe ajakulẹ ọrọ aje eleyi ti a mọ si Recession lede oyinbo di dandan.
Iduro ko si mọ fawọn to n ṣe ijọba bayii
Ẹlẹẹkeji ipa to ni adinku iye owo epo yii yoo ni lara awọn eeyan Naijiria ni pe, iye owo gbogbo nkan lọja yoo gbowo lori.
''Ati ẹni to n ta ata lọja ati awọn ti ko ni nkan ṣe pẹlu dọla, gbogbo wọn ni yoo gbe owo ọja lọ soke.''
Pẹlu iru nkan bayi, anfaani wa, bẹẹ si ni ipenija wa pẹlu ṣugbọn gbogbo rẹ ku si ọwọ awọn to n ṣe ijọba.

Oríṣun àwòrán, Thinkstock
Fun idi eyi, onimọ Chijioke ni asiko re ti aarẹ Naijiria ati awọn Gomina ni lati ṣan ṣokoto wọn daada ki wọn si mu adinku ba owo inakuna.
Rẹgi ni ọrọ r ṣe pẹlu ọjọgbọn Nazif Abdullahi Darma to ni iIpenija nla ni ọrọ to wa nilẹ yi nitori abaṣepọ to wa laarin ọrọ aje ati ilera kii ṣe kekere.
Darma ni asiko re lati ṣe agbeyẹwo awọn afojusun Naijiria nipa iṣuna ọdun 2020.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakanna o ni agbeyẹwo iye ti a maa n gbe le owo iṣẹ amayedẹrun ni Naijiria ti wa di dandan bayii.
''A ko le ma darukọ owo gọboi pe a fẹ fi ṣe isẹ agbaṣe .Nibo la ti fẹ ri bayi ti owo dọla ti dẹnu kọ ilẹ?''
''O ti di dandan lati se agbeyewo ibasepọ laarin awọn aladani ati ẹka ijọba ti a mọ si PPP''
Arinrinajo lọ si ilẹ okere fun ẹkọ tabi ilera yoo mọ asiko yi lara
Ninu awọn ti Ọjọgbọn Nazifi Abdullahi Darma sọ pe yoo mọ asiko yi lara ju, ni awọn ti wọn maa n na owo dọla, yala lati fi gba itọju nilẹ okere ni tabi fun eto ẹkọ ni oke okun.
O ṣalaye pe, bi eeyan ba ni dọla bayi, ki o ṣọra lati naa. Bi anfaani ba si wa fun lati yanju nkan to n wa lọ si ilẹ okere, ki o yara yanju rẹ nile lai lọ si ita.
Ẹ múra o, epo rọ̀bì di òkùtà lọ́jà torí Coronavirus, ìlú yóò le koko - NNPC figbe ta
Saaju la ti sọ fun yin pe oludari agba fun ajọ elepo rọbi nilẹ wa, NNPC Mele Kiyari ti fi iboosi bọnu pe kawọn ọmọ Naijiria tete gbaradi fun ilu ti yoo le laipẹ, nitori bi owo epo rọbi se n ja wa silẹ lọja agbaye.

Oríṣun àwòrán, Others
Melee, ẹni to ke gbajare yii asiko to n sọrọ lori ipa ti ebu ẹyin to ba owo epo rọbi yoo ni lori ọrọ aje Naijiria, wa n fi ika hanu pe orilẹede yii ko ni ọrọ aje miran to ju epo rọbi lọ, eyi ti ko ta mọ bayii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ́ gbaradì, to bá lo jẹnẹrátọ̀ àbí tà á, ò ń fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá ṣeré - Sẹ́nétọ̀ ń dábàá
- Agbófinró, tó bá wa ọkada àbí kẹkẹ maruwa l'Eko, o rugi oyin - Sanwo-Olu
- Ará Yúróòpù ẹ fìdí mọ́lé yín, mo ti gbé ìlẹ̀kùn Amẹ́ríkà tìpa torí Coronavirus - Trump
- Ìjọba ń ṣe afárá Eko Bridge l'Eko, àwọn ọ̀nà àbùdá tí ẹ lèè gbà nìyí
O ni arun asekupani Coronavirus to n se ọsẹ kiri yika agbaye lo ko okuta ba epo rọbi lọja, pẹlu orogun owo ti ilẹ Saudi Arabia n ba Russia se nidi okoowo epo rọbi, eyi to mu ki owo epo ja wa silẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Oludari agba fun ajọ NNPC wa n rọ awọn ọmọ Naijiria lati gbaradi fun inira osu mẹta, o kere tan, ki ọja agbaye to bọ lọwọ wahala yii, eyi ti yoo ni ipa ti kii se kekere lori ọrọ aje Naijiria.
O ni ọgọta dọla fun agba epo rọbi kan ni wọn gbe eto isuna ọdun 2020 le lori amọ lọwọ lọwọ bayii, owo agba epo kan ti ja wa silẹ di ọgbọn dọla, to si tun seese ko ja wa silẹ ju bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Others
"Ni bayii, o le ni awọn ile ẹru mejila to wa nilẹ lọja agbaye to kun fun agba epo rọbi, ti ko ri ẹni yọwo rẹ nitori wahala arun Coronavirus to n ja rain nilẹ, eyi ti ọwọja rẹ tun ti tan de awọn ẹya ẹka epo rọbi miran.
Bakan naa ni olokoowo to gbajumọ julọ ni Afirika, Aliko Dangote, lasiko ipade apero ti banki apapọ ilẹ wa se laipẹ yii ti koro oju si bi orilẹede Naijiria ko see tii waọna miran fun ọrọ aje rẹ yatọ si epo rọbi, to ti di okuta lọja agbaye bayii.













