Eko bridge: Ìjọba ń ṣe afárá Eko Bridge l'Eko, àwọn ọ̀nà àbùdá tí ẹ lèè gbà nìyí

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
Ijọba ipinlẹ Eko ti bẹrẹ atunṣe opoopona afara Eko.
Nitori eyi ijọba ipinlẹ Eko ti wa kede awọn ọna abuja lati yago fun sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ lagbegbe to yii ka.
Alakoso opopona ijọba apapọ nilu Eko, Ọgbẹni Adedamọla Kuti lo fi idi rẹ mulẹ pe apapkan afara Eko bridge yoo wa ni titi pa ki wọn lee ṣe awọn eto atunṣe gbogbo to ba yẹ nibẹ.
O ni awọn opo afara naa to ti n rẹ sara laarin agbegbe Alaka si Costain titi wọ Apọngbọn ni wọn fẹ tun ṣe.

Oríṣun àwòrán, others
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lori awọn opopona tawọn awakọ lee maa gba lasiko ti iṣẹ atunṣe yii yoo fi maa waye, ijọba ipinlẹ Eko latẹnu olubadamọran fun gomina ipinlẹ Eko lori ọrọ ohun amayedẹrun ṣalaye pe ijọba ko ṣe eyi lati mu inira ba araalu bikoṣe lati mu abo to peye waye lori awọn ohun amayedẹrun ti wọn n lo.
Eyi ni awọn ọna abuda fun awọn ọlọkọ lasiko ti atunṣe afara Eko bridge naa yoo maa fi waye:








