Emir of Kano: Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna fún Sanusi ní ipò tuntun

Emir Sanusi

Oríṣun àwòrán, SANI MAIKATANGA

Gomina ipinlẹ Kaduna ti yan Mahammadu Sanusi keji gẹgẹ bi ọkan lara awọn ajọ to n risi ọrọ karakata ni ipinlẹ Kaduna,(KADIPA).

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti fi lede wi pe wọn fẹ fi eyi ṣe atunto ẹka to n risi idagbasoke ọrọ aje ni ipinlẹ naa.

Wọn fikun wi pe awọn gbe igbeṣẹ naa nitori wọn mọ pe ipinlẹ Kaduna yoo fi ohun ribiribi kọ lara ọgbọn ti Sanusi ni ati oye rẹ nipa eto ọrọ aje.

Emir Sanusi sọ pé òun yóò pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún bí wọ́n ṣe lé e kúró nílùú Kano

Awọn agbẹjọro Emir ilu Kano ti wọn ṣẹṣẹ rọ l'oye ti sọ pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun tako igbesẹ ijọba ipinlẹ Kano.

Ninu atẹjade kan ti agbẹjọro agba, Abubakar Balarabe Mahmoud, fi sita l'orukọ igbimọ agbẹjọro fun Emir Sanusi, ni wọn ti sọ pe awọn n ṣiṣẹ niluu Kano ati Abuja lọwọlọwọ lati pe ẹjọ, ayaafi ti wọn ba tu Emir naa silẹ ni ihamọ ni kiakia ni ko ni i jẹ ki awọn o gbe igbesẹ nilan ofin.

Igbimọ naa to ṣapejuwe lile Emir Sanusi kuro niluu Kano lẹyin ti wọn rọ ọ l'oye, gẹgẹ bi nkan ti ko ba ode oni mu sọ pe ko si ninu ofin Naijiria.

Ati wi pe ile ẹjọ Kotẹmilọrun l'orilẹ-ede Naijiria sọ ọ ni gbangba pe iru igbesẹ bẹ ko ba ofin mu, lasiko ti ijọba ipinlẹ Kebbi rọ Emir ilu Kebbi l'oye.

Wọn tẹsiwaju lati sọ pe "ko si igba kankan ti ijọba ipinlẹ Kano fi iwe ranṣẹ tabi pe Emir si akiyesi lori ẹsun aigbọran si awọn alaṣẹ, ati kikuna lati maa lọ fun ipade ati eto ti ijọba ba gbe kalẹ, ti wọn fi kan an.

"Bakan naa ni wọn ko fun ni anfaani lati rojọ tabi ṣalaye lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an."

Wọn tẹsiwaju lati sọ pe lẹyin ti gomina ba to o ṣepade ati ijiroro pẹlu igbimọ lọbalaba ipinlẹ Kano nikan lo to le gbe igbesẹ lati rọ Emir kankan l'oye.

"Wọn ko fi ọrọ naa lọ igbimọ lọbalọba ipinlẹ Kano, nitori pe Emir Sanusi ni alaga igbimọ naa.

Ko si si bi wọn yoo sẹ fi to igbimọ l'eti, ti ko ni i mọ si."

Wọn ti gbe Emir ilu Kano tẹlẹ, Sanusi Lamido Sanusi kuro ni ilu Loko, nipinlẹ Nasarawa.

Yaara yii ni Emir Kano tẹlẹ, Sanusi Lamido sun mọju
Àkọlé àwòrán, Yaara yii ni Emir Kano tẹlẹ, Sanusi Lamido sun mọju

Ilu naa lo balẹ si lẹyin ti ijọba ipinlẹ Kano rọ ọ l'oye. Ilu naa lo si sun mọju.

Olori agbegbe Loko, Abubakar Hamed Sabo sọ fun BBC pe wọn gbe Emir Sanusi wa si ilu Loko London, ṣugbọn wọn ti pada gbe e kuro lọ si ilu Awe nipinlẹ Nasarawa bakan naa.

Aafin yii ni wọn kọkọ gbe Sanusi Lamido Sanusi lọ lẹyin ti wọn rọ ọ l'oye
Àkọlé àwòrán, Aafin yii ni wọn kọkọ gbe Sanusi Lamido Sanusi lọ lẹyin ti wọn rọ ọ l'oye

Hamed sọ pe wọn gbe e kuro ni Loko nitori pe agbegbe naa ko tọ si i ni ipo ọlọla to wa.

"A ko ni ẹrọ amuletutu, faanu nikan la ni, agbegbe yii si gbona pupọ."

Èyí ni fídíò bí wọ́n ṣe fi bàálù gbé Emir Sanusi kúrò ní ìpínlẹ̀ Nasarawa

Iroyin kan to tẹwa lọwọ sọ pe wọn ti gbe Emir ilu Kano tẹlẹ, Sanusi Lamido Sanusi kuro ni ipinlẹ Nasarawa lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ.

Iroyin naa sọ pe baalu ayara fefe ẹlikọpita ni wọn fi gbe kuro ni abule Loko ti wọn fi pamọ si lati ọjọ Aje.

Àkọlé fídíò, Wọ́n ti gbé Emir Kano tẹ́lẹ̀, Sanusi Lamido kúrò ní Nasarawa lọ síbi tẹ́nìkan kò mọ̀

Ọjọ Aje ni gomina ipinlẹ Kano rọ Emir Sanusi l'oye, ti wọn si tun le kuro nilu Kano lọ si Nasarawa.

Ao ma a mu wa fun yin bi nkan ba tun ṣe n lọ.

Sanusi ní òun ti gba kádàrá ṣùgbọ́n agbẹjọ́rò rẹ̀ ní àwọn ṣì lè gba ilé ẹjọ́ lọ

Emir ana ilu Kano Sanusi Lamido Sanusi ni oun ti gba kadara iyọnipo to ṣẹlẹ si oun gẹgẹ bi amuwa lati ọdọ Ọlọrun.

Sanusi fi ọrọ yi sita ninu fọnran fidio kan to ṣe ki o to fi afin rẹ nilu Kano silẹ lọjọ Aje.

Ninu fidio naa Sanusi sọ ni ede Hausa pe ''Ọlọrun ti kọ wi pe oun yoo jẹ́ ọba Kano bẹẹ naa si ni akọsilẹ wa wi pe wọn yoo yọ oun.''

O ni ''Inu mi dun mo si dupẹ.Mo ki ẹnikẹni ti wọn ba gbe oye naa fun ku orire.Mo ti sọ fawọn iyawo mi ati mọlẹbi mi pe ki wọn funemir tuntun ni ọwọ to yẹ''

Ni ọjọ Aje ni ijọba Kano yọ Sanusi kuro lori oye ti wọn si paṣẹ pe kio fi ilu silẹ lọ si ipinlẹ Nassarawa.

Lẹyin iyọnipo rẹ, wọngbe ọpa aṣẹ fun Aminu Ado Bayero gẹgẹ bi Emir tuntun ilu Kano.

Iyọnipo Sanusi ko bofin mu, a le gba ile ẹjọ lọ

Ẹwẹ, agbẹjọro Sanusi Abubakar Mahmoud ti sọ pe iyọnipo ati aṣẹ ki Sanusi fi ilu silẹ tako ofin.

Lasiko to n ba ile iṣẹ amounmaworan Naijiria Channels TV sọrọ, Mahmoud ni igbesẹ naa kọdi ẹtọ Sanusi labẹ ofin ati pe ti awọn ba fi le lọ si ile ẹjọ o di dandan ki adajọ yi aṣẹ naa pada.

Agbẹjọro Sanusi,Abubakar Mahmoud

Oríṣun àwòrán, Legalnaija.com

''Nkan to ku bayi ni ki a ṣe ipade pẹlu Sanusi lori igbesẹ ti a o gbe.Nkan ti o ba sọ fun wa ni a o ṣe ni igbesẹ.A o fun lasiko lati da ọrọ yi wo ki a to gbe igbesẹ''