Gov Ganduje Vs Sanusi: Ganduje kò lẹ́tọ̀ọ́ láti yan Emir mẹ́rin

Lamido Sanusi ati Ganduje

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Òpin ọ̀sẹ̀ ni Gomina ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Ganduje fi ìwé àsẹ fún àwọn Emir tuntun mẹ́rin láti bẹ̀rẹ̀ isẹ́.

Ile ẹjọ giga to kalẹ si ipinlẹ Kano ti ni otubantẹ ni igbesẹ Gomina Ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje pẹlu bo se yan Emir mẹrin miran ni ilu Kano.

Ile ẹjọ naa pasẹ fun gomina naa lati da gbogbo nkan pada si bose wa tẹlẹ ki igbẹjọ fi le waye lori igbesẹ gomina to yan Emir tuntun.

Iwe igbẹjọ naa fẹsun kan gomina Ganduje pe ikunsinu lo mu ki o gbe igbesẹ naa lati din agbara Emir Lamido Sanusi ku gẹgẹ bi Emir ilu Kano.

Opin ọsẹ to kọja ni Gomina Ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje fi iwe asẹ fun awọn Emir tuntun mẹrin lati bẹrẹ isẹ.