Ajimobi: Orúkọ èmi, Akala, Ladoja, Adebayo Faleti àtàwọn míì

Oríṣun àwòrán, Abiola Adeyemi Ajimobi/Facebook
Ijọba ipinlẹ Oyo ti fun awọn adugbo pataki kan ni ilu Ibadan atawọn ilu mii nipinlẹ Oyo lorukọ mii.
Abiola Ajimobi, Adebayo Faleti, Alao Akala, Rashidi Ladoja atawọn mii ni wọn ti yi orukọ awn adugbo ọhun padà sí.
Kọmisana eto iroyin, Toye Arulogun ni igbimọ alaṣẹ ipinlẹ ti fọwọ si igbesẹ fifun awọn adugbo naa ni orukọ tuntun.
Arulogun ni igbimọ alaṣẹ gbe igbesẹ ipinu yii ni ipade ti wọn ṣe lọjọ iṣẹgun ọjọ kẹrinla oṣu karun ọdun 2019.
O ni igbesẹ yii jẹ ọna ati mọ riri awọn eniyan to ti ko ipa ribi ribi ninu idagbasoke ipinlẹ Oyo, ninu iṣẹ wọn ati si awọn araalu.
Gẹgẹ bi o ṣe wa ninu akọsilẹ iroyin to jade, awọn ọna naa ni:
1. Ibi afara akọkọ lẹba ile ọ̀fíìsì ijọba kan ni Mokola ni wọn yi pada bayii si Trasmsformation Flyover
2. Ijokodo - Apete road ni wọn pe ni Ambassador Olu Sanu bayii
3. Ibudo tuntun kan ti wọn ṣẹ̀sẹ̀ ṣe to n jẹ Zonal Mediation Centre nilu Ogbomosho yoo gba orukọ Justice Atilade Ojo Mediation Centre.
4. Bakan naa Ilorin Express Junction-Ikoyi - Takie - Palace - Ogbomoso Grammar School road yoo maa jẹ Soun Oyewumi Ajagungbade.
5. Ibadan/Oyo Express/Iseyin-Owode to lọ si Akesan-Palace ati Old Ibadan-Oyo road yoo yipada si Alaafin Lamidi Adeyemi III road.
6. Eleyele-Dugbe ANCE Road bayii ti di Oba Saliu Adetunji road.
7. Idi-Ape - Bashorun Akobo Road ti di Abiola Ajimobi way.
8. Ibarapa Polytechnic Eruwa ni wọn yoo maa pe ni Adeseun Ogundoyin Polytechnic, Eruwa.
9. Ile ẹkọ College of Agriculture, Igboora ti yipada si Lam Adesina College of Agriculture, Igboora.10. Ibudo ilera Maternal &Peadiatric Centre, Olodo Ibadanni wọn ti pe lorukọ Abiola Ajimobi Maternal &Paediaitric Centre.
11. Elebu Road ti wa di Alao-Akala Way.
12. Monatan - Olodo Road di Rashidi Ladoja.
13. Onireke-Agbarigo Road yoo maa jẹ Onikepo Akande Road.
14. Festac Road, Mokola ti di Adebayo Faleti Road.15. Challenge - Efunsetan Road ni yoo maa jẹ Lam Adesina road latoni lọ.













