Sẹnetọ Lekan Balogun: Taló yẹ kó yan ọba bí kò ṣe Ajimobi?

AJIMOBI

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Ogúnjọ́, Osu Kini, ọdún tó kọjá ni ilé ẹjọ́ gíga nípínlẹ̀ Ọyọ ní gomina Ajimobi kó lásẹ láti yan ọba.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti da ẹjọ wi pe Gomina ipinlẹ Ọyo, Abiola Ajimobi ni asẹ lati yan ọba ni ipinlẹ Ọyọ.

Ile ẹjọ naa da ẹjo ọhun lasiko ti wọn n fi ọwọ osi da ẹjọ ti sẹnetọ Rashidi Ladoja pe lati sọ wi pe gomina Ajimobi ko lasẹ lati yan ọba ni ipinlẹ Ọyọ, nu.

Gomina Ajimobi lo lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun, lẹyin ti adajọ ile ẹjọ giga ni ọdun to kọja ni Ajimobi ko lasẹ lati yan ọba mọkanlelogun fun ara rẹ.

Olori awọn ọba ti gomina Ajimobi yan,Sẹnetọ Lekan Balogun lasiko to n ba BBC sọrọ fi idi ẹjọ naa mulẹ, pẹlu ero wi pe lati ayebaye ni gomina ilu ti n yan awọn ọba ilu.

Amọ, asoju olubadan lori ọrọ iroyin, Deola Oloko sọ fun BBC wi pe oun yoo kan si wa lẹyin ti oun ba ti fi idi idajọ naa mulẹ tan.