Àwọn tó ń wojú ọjọ́ rí ihò dúdú tó tóbi jù láyé àtọ̀run

IHO

Oríṣun àwòrán, EHT Collaboration

Àkọlé àwòrán, Fun ìgbà àkọ̀kọ̀, àwọ̀n tọ́ ń wojú ọjọ́ ti ya àwòrán ihò dúdú tó tóbi jùlọ ní gbogbo aye àti ọ̀run tí ó wà ní ọ̀run galaxy.

Awọn to n woju ọjọ ti ya aworan iho dudu to tobi julọ ni gbogbo aye ati ọrun ti o wa ni ọrun galaxy fun igba akọkọ.

Wiwọn rẹ to ogoji biliọnu kilomita to tobi ju aye lọ lọna miliọnu mẹta, ti awọn onimọ sayẹnsi si pe ni abamiẹda "a monster".

Iho dudu yii jina si wọn lọna ọgọrun marun miliọnu triliọnu kilomita si ibi ti wọn ti ya aworan naa pẹlu ohun awojuọrun mejo kaakiri agbaye.

Àkọlé fídíò, JAMB 2019: A ó fagi lé ìdànwò ẹni tó bá ṣe aṣemáṣe

Ninu Iwe Iroyin Astrophysical Journal Letters ni wọn ti gbe e jade.

Ọjọgbọn Heino Falcke, ti ile iwe giga fasiti Radboud University orilẹede Netherlands, to gbe imọ yii kalẹ sọ fun Ile Isẹ Iroyin BBC pe ibi ti wọn ti ri ihọ rabata yii ni ọrun galaxy ti wọn n pe ni M87.

Faicke ni ‘oun ti a ri ju gbogbo ile aye ati ọrun ti a le ri soju, ti o si tobi ju oorun lọna to le ni biliọnu mẹfa.

"Iwo yii rabata, bẹẹ na lo si jin, ti a ko si ri iru rẹ ri. Abamiẹda leleyi o, ti o si jẹ eyi ti o tobi julọ ni gbogbo aye ati orun"