Police arrest: 'Ó léwu láti kọ́kọ́ yẹ ọlọ́pàá wò ní Nàìjíríà'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eewọ, ma danwo! Onimọ nipa ọrọ eto aabo, Ọgbẹni Richard Amuwa ti gba awọn orilẹede Naijiria n'imọran pe o lewu lati kọkọ yẹ ọlọpaa wo ti o ba fẹ yẹ wọn wo.
Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa Ọgbẹni Frank Mba lo kọkọ fi lede loju opo Twitter awọn ọlọpaa pe eeyan le fi irẹlẹ beere lati kọkọ yẹ agbofinro wo ko to yẹ ẹni naa wo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ọrọ yii wa lara awọn ohun ti Ọgbẹni Mba fi sita lori Twitter lori bi awọn eeyan ti le wuwa ti ọlọpaa ba fẹ mu wọn.
Amọ, Ọgbẹni Amuwa to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ko si ibi ti wọn ti n ṣe iru ẹ kaakiri agbaaye.
Amuwa sọ pe niwọn igba ti ọlọpaa ba ti gbaṣẹ lati yẹ eeyan wo, ẹni naa ko nilo lati kọkọ yẹ ọlọpaa wo ṣugbọn o ni lati fu ra ki wọn maa ba fi nnkan to le ṣakoba si i lapo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O fikun ọrọ rẹ pe ẹni to ba da iru laṣa yoo jẹ iyan rẹ niṣu nitori ifẹmi ara ẹni wewu gbaa ni.
O tun sọ pe ọrọ awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria pe fun ọgbọn, o ni kii ṣe agidi rara bibẹẹ kọ, eeyan le kabaamọ igbesẹ rẹ.
O gba awọn eeyan nimọran pe ki wọn ma ṣe kori soju kan naa ti ọlọpaa ba fẹ yẹ ile wọn tabi ọkọ wọn wo.














