Adeleke vs Oyetola: Ilé ẹjọ́ kòtẹmilọ́rùn yóò dájọ́ ìdìbò gómìnà Oṣun ọdún 2018

Ile ẹjọ kotẹmilọrun to n gbejọ lori ọrọ ẹni tó lẹtọ lati jẹ Gomina nipinlẹ Osun laarin Gboyega Isiaka Oyetola ati Ademola Adeleke yo gbe idajọ kalẹ lọjọru.
Eto Idajọ ti wọn fi ikede rẹ sita ninu iwe ile ẹjọ naa ni awọn alatilẹyin awọn ti ọrọ naa kan fi sọwọ sawọn oniroyin yoo waye laago mẹsan owurọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo lori ẹrọ alagbeka, ọkan lara awọn ọmọ igbimọ ipolongo Ademola Adeleke, Niyi Owolade sọ fun BBC Yoruba pe lootọ ni idajọ naa yoo waye nilu Abuja.
Ẹwe, aburo Senetọ Ademola Adeleke kan ti orukọ rẹ n jẹ Dele Adeleke naa ni ohun lohun gba iwe naa nile ẹjọ kotẹmilọrun lAbuja
Aworan ikede naa re e

Oríṣun àwòrán, Dele Adeleke
Kini idajọ yi da lori
Ni ọjọ kejilelogun oṣu Kẹta ọdun yi ni ile ẹjọ to n gbejọ lori ọrọ idibo Gomina ipinlẹ Osun gbe idajọ kalẹ pe Senetọ Ademola Adeleke lo jawe olubori ninu ibi Gomina ipinlẹ Osun.
Kete ti idajọ yi di mimọ ni awọn agbẹjọro Gomina Oyetola gbaile ẹjọ kotẹmilọrun lọ lati tako idajọ naa.
Idajọ ti wọn yoo kede lọla yi da lori pe Oyetola tako idajọ ti Adeleke saaju ri gba lọdọ igbimọ to n gbọ ẹjọ lori idibo naa.














