Osun state: PDP ní nítorí ẹjọ́ lórí ìbò gómìnà Ọ̀ṣun ni Ọlọ́pàá fi mú Sẹ́nétọ̀ Ademọla Adeleke sí àhámọ́

Sẹnetọ Adeleke

Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1

Àkọlé àwòrán, Ọlọpaa ti n n fi ẹsun lilo ayederu iwe ẹri kan Sẹnetọ Adeleke fun igba diẹ bayii

Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ ofin gbe oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP nibi idibo gomina ipinlẹ naa to waye ni ọdun 2018.

Iroyin bọ si gboro ni ọjọ aje pe awọn ọlọpaa ti mu Sẹnetọ Ademọla Adeleke si ahamọ lori ẹsun to niiṣe pẹlu ẹsun pe o lo ayederu iwe ẹri girama.

Iroyin to n tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣalaye pe owurọ ọjọ aje ni Sẹnetọ Adeleke lọ yọju si ileeṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe paa laṣẹ fun.

Àkọlé fídíò, Adeleke fọhùn, 'èmi ni gómìnà tí wọ́n dìbò yàn'

Gẹgẹ bii iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, agogo mẹsan owurọ ọjọ aje ni Adeleke farahan ni olu ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria nilu Abuja. Iroyin ọhun ni nibẹ ni wọn ti gbe e lọ si agọ ọlọpaa Maitama pẹlu 'erongba ati gbee lọ si ile ẹjọ magistrate ti ko si ẹni to mọ ni ọla'

Ki ni ẹgbẹ oṣelu PDP n sọ?

Atẹjade lati ọdọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun eleyi ti alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Sọji Adagunodo fi ọwọ si ni nṣe ni awọn ọlọpaa n fẹ halẹ mọ Sẹnetọ Adeleke nitori ẹjọ to n pe lati gba aga gomina ipinlẹ Ọṣun pada ni ile ẹjọ.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni ṣe ni ijọba apapọ n gbaradi ati gbogun ti Sẹnetọ naa ni lati lee gbagbe ilepa rẹ.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni nṣe ni awọn ọlọpaa fẹ wa ọna bomi pa igbẹj ile ẹjọ lori esi ibo gomina ipinlẹ Ọṣun.

Titi di asiko yii, ileeṣẹ ọlọpaa ko tii sọ ohunkohun lori ọrọ naa.

Sen Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola adeleke

Àkọlé àwòrán, Titi di asiko yii, ileeṣẹ ọlọpaa ko tii sọ ohunkohun lori ọrọ naa

Ki ni ileeṣẹ ipolongo ibo fun Adeleke sọ?

Bakan naa, ileeṣẹ ipolongo ibo fun Sẹnetọ Adeleke pẹlu ti ke sawọn ẹgbẹ ajafẹtọ atawọn to ni ifọn leekanna lorilẹede Naijiria ati lagbaye lati dide fun Sẹnetọ naa.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ naa fi sita, eleyii ti agbẹnusọ rẹ, Ọgbẹni Rasheed fi ṣọwọ si BBC News Yoruba, o ni gbogbo ẹsun ti awọn ọlọpaa fi n kan an ni ile ẹjọ ti n joko le tabi gbe idajọ kalẹ le lori.

"Ọga ileewe girama ti Sẹnetọ Adeleke lọ ti jẹri labẹ ibura niwaju ile ẹjọ giga kan ni agbegbe Bwari pe lootọ ni ileewe naa fun un ni iwe ẹri. Bakan naa ni ajọ onidanwo iwe mẹwa, WAEC pẹlu ti ṣalaye pe lootọ ni Ademọla Adeleke joko ṣe idanwo naa. Fun ọlọpaa lati tun gbe ẹsun yii kan naa dide fi han pe o ni ohun miran ti wọn n wa."