Osun Guber Poll: PDP ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga lórí ọ̀rọ̀ Adeleke kò fẹsẹ̀ múlẹ̀

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ademola Adeleke

Àkọlé àwòrán, Idibo gomina Oṣun

Adeleke ni iwe ẹri tó yẹ lati dije dupo gomina- Amofin Salami

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe ohun yoo lọ si sile ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ giga l'Abuja to fagile iyansipo Ademola Adeleke gẹgẹ bi oludije sipo gomina fẹgbẹ oselu PDP ninu idibo gomina to waye ninú Osu Kẹsan an, ọdun 2018 ni ipinlẹ Osun.

Lasiko to n da ẹjọ naa, Adajọ Agba Oathman Musa sọ wi pe iwadii fihan pe ọdun 1976 ni Adeleke wọ ile iwe girama, amọ ti ko si iwe ẹri to fihan pe o jade iwe mẹwaa ni ọdun 1980.

Ṣugbọn oluranlọwọ fun Sẹnẹtọ Adeleke lori eto iroyin, Bamidele Salami to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe idajọ naa ko lẹsẹ nilẹ rara ati pe ajọ idanwo iwe mẹwaa ti a mọ si WAEC ti bura nile ẹjọ pe Ademola Adeleke ṣe idanwo aṣejade naa.

Àkọlé fídíò, Okùnrin SARS náà sọ pé òun máa pa èèyàn síbi ni- Aladugbo

O ni lakọkọ, akoko lati pẹjọ lori bo ya Sẹnẹtọ Adeleke koju oṣuwọn lati dije fun ipo oṣelu ti kọ ja nitori o ti ju ọgọsan ọjọ ti ofin la kalẹ lọ.

Ọgbẹni Salami sọ pe ẹlẹẹkeji to da bii rẹ ni pe ajọ to n ri si idanwo aṣejade nile iwe girama, eyun ni WAEC jẹri nile ẹjọ tẹlẹ pe Adeleke pari iwe mẹwaa ti ofin la kalẹ gẹgẹ bi amuyẹ fun ẹnikẹni to ba fẹ dije fun ipo gomina ni Naijiria.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ilé ẹjọ́ kòmítẹlọ́rùn yá lórí ìbò gómìnà Oṣun- PDP

O fikun ọrọ rẹ pe iwe ẹri ti oludije sipo gomina fẹgbẹ PDP nipinlẹ Oṣun lo lati dije fun ipo sẹnẹtọ naa lo lo fun ipo gomina, o ni ofin Naijiria ṣi faye gba eleyi.

Àkọlé fídíò, Àyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin

Ọgbẹni Salami ni ẹgbẹ alatako APC lo wa nidi ọrọ yii, ati wi pe APC ko ṣetan lati gba idajọ ododo laaye.

Àkọlé fídíò, Ojojúmọ ní mọ ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọ mi to jẹ akanda

Ṣugbọn amofin Remi Adeoye ṣalaye pe labẹ ofin, idajọ ile ẹjọ giga l'Abuja ọjọ Iṣẹgun ti fagile idajọ igbimọ igbẹjọ eto idibo(Tribunal) to sọ pe Sẹnẹtọ Ademola Adeleke lo wọle ibo gomina Ipinlẹ Oṣun.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ilé ẹjọ́ kòmítẹlọ́rùn yá lórí ìbò gómìnà Oṣun- PDP

Agbẹjọro Adeoye ṣalaye pe ti ile ẹjọ to ga julọ ba sọ pe Sẹnẹtọ Adeleke lo jawe olubori ninu idibo gomina Oṣun, ṣugbọn ti ko ni ẹri to daju pe o pari ile iwe girama, ẹniti o jẹ igbakeji rẹ ni yoo di gomina Ipinlẹ Oṣun.