Ààrẹ orílẹ̀-èdè Algeria Abdulaziz Bouteflika ti kọ̀wé fipo silẹ̀

Abdulaziz Bouteflika
Àkọlé àwòrán, Aàrẹ orill-èdè Algeria to tin wa lori oye lati ọdun 1999

Ààrẹ orilẹ̀-èdè Algeria Abdulaziz Bouteflika ti kowe fipo silẹ lẹ́yin ifẹhonu han ọlọjọ gbọ́ọ́rọ

Bouteflika tó ti wa lori ipo gẹ́gẹ́ bii ààrẹ láti ogun ọdun sẹyin ti fi èrongba ati di ààrẹ niẹ̀ẹ̀kaarun kálẹ si ẹgbẹ́ kan lẹ́yin ti àwọn ọdọ orilẹ̀-èdè Algeria dide lódi si ìpinu rẹ.

Ikọ ọmọ oogun Algeria ti pé ààrẹ ẹni ọmọ ọdun mẹ́jilélọgọrin ọ̀hun láti kédé pe òun okóju osùwọn láti ṣe ìjọba mọ

Láti ọdun mẹ́fa sẹ́yìn ni à[rẹ ti wa lóri akete àìsàn rapárọsẹ̀ ti ko si foju han si gbangba mọ.

Ààrẹ Bouteflika Algeria yoo kọ̀wẹ́ fipò sílẹ̀ ni 28 April

Aworan aarẹ Bouteflika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lati ọdun 1999 ni Aarẹ Bouteflika ti wa lori oye nilẹ Algeria

Ile iṣẹ iroyin orile-ede Algeria sọ pe aarẹ Abdelaziz Bouteflika yoo kọwe fipo silẹ ki saa rẹ to pari ni ọjọ kejidinlọgbọn, Oṣu kẹrin ọdun.

Atẹjade kan lati ileeṣẹ aarẹ ni ọmọ ọdun méjílélọ́gọ́rin naa to ti wa lori oye fun ogun ọdun yoo ri wi pe itẹsiwaju ba eto ijọba ki o to fiṣẹ silẹ.

Iroyin yi wa lẹyin ti iwọde leralera waye eleyi ti awọn eeyan ilẹ naa fi n kesi i wi pe 'o to gẹ' , ki o kọwe fiṣẹlẹ.

Ohun ti iroyin yi tumọ si ni pe o ti jawọ ninu erongba rẹ lati du ipo fun saa karun un.

Ẹwẹ, wọn ti sun ọjọ idibo siwaju ti ijọba si ti ṣadehun pe oun yoo ṣeto apero apapọ nibi ti awọn yoo ti jiroro lori awọn atunto ti yoo mu itẹsiwaju ba ilẹ naa.

Saaju asiko yi, ko si ẹni to le sọ pato boya yoo kowe fiṣẹ silẹ tabi yoo yi wa lori oye.

Aworan iwọde lorileede Algeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ogunlọgọ awọn ọmọ orile-ede Algeria lo kopa ninu iwọde lati jẹ ki aarẹ Bouteflika fipo silẹ

Akọroyin BBC Ahmed Rouba jabọ pe ọpọ ọmọ orile-ede Algeria lo gbagbọ pe alaafia aarẹ naa ti dẹnu kodo debi pe awọn kan lo n loo lati ṣe ijọba ti awọn wọnyi ko si fẹ fi ijọba kalẹ.

Awọn wọnyi lo ni wọn pọ ninu ẹgbẹ National Liberation Front eyi ti o ti n ṣakoso Algeria bọ lati ọdun 1962 ti Algeria ti gba ominira lọwọ ilẹ Faranse.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: