Nigeria 2019: INEC ìpínlẹ̀ Rivers ṣetán láti kéde èsì ìdìbò Rivers

awọn agbofinro

Oríṣun àwòrán, @pius

Àkọlé àwòrán, Wamu wamu ni awọn agbofinro duro nibudo ikede idibo Rivers

Ilana ofin ti INEC la kalẹ fun kika ibo naa jẹ eyi ti wọn kọkọ fara balẹ ṣalaye ṣaaju kika ibo.

Wọn sọ nipa esi idibo awọn ibudo idibo ti ko si iforukọsilẹ to peye tabi ti wọn ko ri to papọ bi o ṣe yẹ.

Awọn ibi ti wọn ni akọsilẹ iforukọsilẹ to dara ti ko dẹ si oṣiṣẹ INEC ti yoo ṣe atojọ esi ijọba ibilẹ naa ni awọn yoo fi pari ikede naa lẹyin iwadii to yẹ.

awon inec
Àkọlé àwòrán, Kika esi idibo ti bẹrẹ ni pẹrẹwu ni Rivers

Ajọ INEC ni atundi idibo yoo waye lawọn ẹkun ti awọn ba ti wọgile esi idibo ibẹ lataari iwa ipa to ṣẹlẹ.

Bawo ni o ṣe ti bẹrẹ lati aarọ

Ohun gbogbo ti ṣetan ni ilu Pọta ni ipinlẹ Rivers ni eyi ti ajọ INEC yoo ti kede esi idibo gomina to ku.

Ọjọ kẹsan an, oṣu kẹta, ọdun 2019 ni awọn eniyan ipinlẹ Rivers ti kopa ninu eto idibo gboogbo ti awọn eniyan Naijiria ti kopa nipinlẹ Mọkandinlọgbọn ti wọn ti n yan gomina.

Ni kete ti ohun gbogbo daru nibudo ikede esi idibo gomina ati awọn aṣojuṣofin ipinlẹ Rivers ni ajọ INEC ti sun ohun gbogbo siwaju.

Lọwọlọwọ ni àwọn agbofinro kun ibudo ikabo naa ti wọn si di opopona mejeeji to jade si olu ileeṣe ajọ INEC nilu Pọta ni opopona PortHarcourt si Aba.

Opọ awọn onile iṣẹ nlanla bii ilé ifowopamọ ati oni ṣọọbu keekeeke ni wọn ti kogba wọle lasiko yii.

oludibo
Àkọlé àwòrán, Gbogbo oludibo n woju ajo INEC nipinle Rivers

Awọn agbofinro, ọtẹlẹmuyẹ, ọmọ ogun ilẹ̀ ati awọn ẹṣọ alaabo ilu ti awa ara wa ni wọn n ṣayẹwo kikun fun gbogbo awọn to ba fẹ wọnu ọgba naa.

Awọn oṣiṣẹ eleto idibo, awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu kọọkan ni wọn ti wa nikalẹ nibẹ.

ibudo ikabo
Àkọlé àwòrán, Opọ lo ti n foju sọna lati mọ ẹni ti yoo tukọ ipinlẹ rivers fọdun mẹrin to m bọ
Àkọlé fídíò, Okùnrin SARS náà sọ pé òun máa pa èèyàn síbi ni- Aladugbo