Ahmed Musa ló fakọyọ jùlọ láàrín àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjírìa lọdún 2018

Oríṣun àwòrán, Kevin C. Cox
Ẹlẹsẹ ayo ikọ agbabọọlu Super Eagles orile-ede Naijiria, Ahmed Musa, ti gba ami ẹyẹ agbabọọlu ọkunrin to pegede julọ ni Naijiria f'ọdun 2018.
Nibi ayẹyẹ ami ẹyẹ ọlọdọọdun ajọ eleto bọọlu ni Naijiria eleyi to waye ni ilu Eko lalẹ ọjọ Aje ni wọn ti fi oye yi da lọla.
Musa wa lara awọn agbabọọlu to kopa fun Naijiria ninu idije ere bọọlu agbaye ni Russai lọdun 2018 ti o si jẹ goolu meji nibẹ.
Eleyi mu ki o jẹ agbabọọlu ti o jẹ goolu julọ fun Naijiria ninu idije naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Adiẹyinmu ikọ agbabọọlu obinrin Naijiria, Onome Ebi lo gba ami ẹyẹ obinrin to fakọyọ pẹlu ipa ribiribi to ko nigba ti ikọ Super Falcons gba ife ẹyẹ Africa Women's Cup of Nations (AWCON) ni 2018.
Lara awọn agbabọọlu miran to gba ami ẹyẹ ni Samuel Chukwueze to gba ẹyẹ agbabọọlu ọjẹwẹwẹ ọkunrin to fakọyọ.
Gbẹnga Ogunbọtẹ gba ẹyẹ akọnimọgba to fakọyọ ti awọn alatilẹyin Kano Pillars, Kano naa gba alatilẹyin to pegede.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Musa tun gba ami ẹyẹ fun goolu to fakọyọ pẹlu goolu rẹ eleyi ti o gba wọ awọn Iceland ninu idije agbaye Russia 2019.