CAF Awards: Ahmed Musa, Alex Iwobi, Asisat Oshoala wà lára olùdíje àmì ẹ̀yẹ CAF

Awọn Super eagles n yọ ninu idije kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà farahàn lára àwọn tí yóò díje fún àmì ẹ̀yẹ̀ agbábọ́ọ̀lù tó pegedé lọ́kùnrin àti lóbìnrin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajọ elere bọọlu ni ilẹ Afirika, CAF ti gbe orukọ awọn agbabọọlu mẹrinlelọgbọn jade lati dije fun ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ lori papa ni saa ere bọọlu ni ọdun 2017 si 2018.

Ajọ CAF gbe iwe orukọ awọn agbabọọlu naa jade ni ọjọ ẹti ninu eyiti ti wọn yoo ti mu mẹta ti yoo figagbaga fun ami ẹyẹ naa lẹyin o rẹyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Balogun ikọ Super eagles, Ahmed Musa ti o n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Al-Nassr ni Saudi Arabia pẹlu Alex Iwobi ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ni agbabọọlu to wa ninu ipele ti ọkunrin.

Ni abala awọn agbabọọlu obinrin, Asisat Oshoala, agbabọọẹu Super Falcons Naijiria ati ikọ Dilian Quanjian ti orilẹede China, Desire Oparanozia ti falcons ati ẹgbẹ agbabọọli Guingamp, Francisca Ordega lati ikọ agbabọọlu Washington Spirit, ati Onome Ebi lati ikọ Hekan Huisanhang ni wọn wa lori orukọ ti ajọ CAF fi sita.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa, orukọ Wilfred Ndidi to n gba bọọlu jẹun ni iks Leicester city ni ilẹ gẹẹsi pẹlu wa ni orukọ awọn agbabọọẹu ti wọn la kalẹ fun ami ẹyẹ agbabọọlu ọdọ ti o pegede.

Ni abala awọn olukọni agbabọọlu, gernert Rohr to jẹ olukọni fun ikọ Super Eagles ati Thomas Dernnerby ti ikọ Super falcons pẹlu wa lara awọn ti wọn fa kalẹ fun olukọni to pegede julọ ni ipele awọn ọkunrin ati obinrin.