Osogbo: Èéfín ẹ̀rọ amúnáwá pa ọlọ́pàá àti ẹbí rẹ méjì ní Oṣogbo

Ẹrọ amunawa to n ṣeefin

Oríṣun àwòrán, Guardian

Àkọlé àwòrán, Ọlọpaa ni eefin ni o jọ bi ẹni pe eefin ẹrọ amunawa lo pa sajẹnti naa ati awọn ẹbi rẹ.

Eniyan mẹta ninu idile kan to n gbe ni agbole Olorisaoko ni Osogbo ni Ipinlẹ Osun gbẹmii mi ni Ọjọbọ. Ọkan ninu wọn jẹ sajẹnti ọlọpaa ti orukọ rẹ n jẹ Mary Samuel.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Osun Folashade Odoro ni o jọ bi ẹni pe eefin ẹrọ amunawa lo pa sajẹnti naa ati awọn ẹbi rẹ.

Awọn miiran ni agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ tun ni o ṣeeṣe ko jẹ ounjẹ ti idile naa jẹ ki wọn to sun lalẹ Ọjọbọ lo gbẹmi wọn.

Àkọlé fídíò, Beautiful Nubia: Kò sí wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ láàgbáyé tí kò ní ọwọ́ ẹ̀sìn lábẹ́nú

Iroyin ni ọlọpaa ni ọkọ oloogbe Mary, ṣugbọn ko si ni Oṣogbo nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Awọn ara adugbo sọ pe ariwo igbe ọmọ-ọmọ sajẹnti naa to jẹ ọmọ oṣu mẹrin ni wọn gbọ ni bii agogo meje aarọ ọjọ naa.

Ọkan lara awọn alabagbe rẹ to gbọ igbe ọmọ naa lo pe awọn aladugbo yooku ti wọn si ja ilẹkun wọ ile nibi ti wọn ti ri oku sajẹnti naa ati awọn meji miiran.

Iroyin ni eefin naa ko pa ọmọde naa lara. Akọbi sajẹnti Mary Samuel ti a gbọ pe o gbe awọn ọmọ rẹ meji wa ki iya rẹ naa fara kaasa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn a gbọ pe nigba ti wọn gbe e de ile iwosan, o ji pada.

Samuel to jẹ ọmọ Ipinlẹ Ekiti ṣiṣẹ ni ẹka iṣẹ ode ni Ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Osun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: