April Fool's Day: Wo àwọn ẹ̀tàn mánigbàgbé tí àwọn ènìyàn ti ṣe

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọjọ 'April Fool' kii se ọjọ isinmi amọ ẹgbẹgbẹrun eniyan lagbaye lo máa n sayajọ ọjọ yii lati sọ nkankan tabi omiran nipa bi April Fool se bẹrẹ ni agbaye.
Ọjọ Kini, Osu Kẹrin ọdọọdun tii se ayajọ ọjọ April Fool ni awọn eniyan ya sọtọ lati maa tan awọn ẹlomiran jẹ.
Ọpọlọpọ eniyan lo n sọ orisirisi nipa bi ọjọ naa ṣe bẹrẹ, awọn miran ni Hilaria to jẹ ọjọ ọdun kan ni ilẹ Rome, ti wọn ma n ṣe ni ọjọ kẹẹdọgbọn, osu kẹta
Bakan naa ni awọn kan sọ wi pe lati inu iwe ti Geoffrey Chaucer kọ to pe orukọ rẹ ni Canterbuty Tales ni ayajọ ọjọ itaja naa bẹrẹ.
- Mọ̀ sí i nípa Oba Yesufu Asanike, Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà
- Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà
- Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe mú mi lẹ́rú ní 1837 - Ajayi Crowther
- Ọlabisi Ajala rèé, ó gun ọ̀kadà yíká àgbáyé, tó sì dé orílẹ̀èdè 87
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ Aláàfin, ẹni tó pààrọ̀ nǹkan obìnrin sí ti ọkùnrin
Itan bi April Fool se bẹrẹ:
Asa titan awọn ẹlomiran jẹ yii lo bẹrẹ lọdun 1582 lasiko ti Pope Grgory XIII se agbekalẹ Kalẹnda Gregorian, to wa fun onka ọjọ ati osu.
Amọ ninu Kalẹnda ti wọn ti n lo bọ lati ẹyin wa, ọjọ Kinni osu Kẹrin ni ọdun tuntun bẹrẹ, ti wọn si maa n se ajọyọ rẹ.
Amọ nigba ti wọn paarọ kalẹnda naa, awọn eeyan kan si tun n tẹsiwaju lati maa se ajọyọ ọdun tuntun ni ọjọ kinni osu kẹrin ọdọọdun.
idi ree ti ọpọ eeyan se maa n fi awọn eeyan to n se ajọyọ ọdun tuntun naa se ẹlẹya, ti wọn si n pe wọn ni alaimọkan ati ẹlẹtan.
Idi ree ti wọn se n ni April Fool ni wọn n se, tori ẹtan lasan ni ajọyọ ọjọ tuntun ti wọn n se.
Ki ni pataki ayajọ April Fool?
Ọjọ Kini osu kẹrin ti wọn maa n se ayajọ ọjọ ẹtan yii lo wa lati da apara ti ko pa ni lara.
Amọ nigba miran, awọn ẹtabjẹ miran maa n lagbara, eyi to ti se ipalara fun ilera ọpọ eeyan miran.
Ọjọ April fool yii si lo n fawọn eeyan ni anfaani lati sinmi diẹ lẹnu isẹ, ki wọn si raye gba apara diẹ.
Amọ awọn eeyan gbọdọ sọra lati mase se apapra lo le pa ẹlomiran lara tabi ilera wọn.
Bakan naa ni wọn ko gbọdọ gbe iroyin ede sita eyi to le maa tan kalẹ lai le se pee pada wale mọ.
Wo awọn nkan itanjẹ ti awọn eniyan ti se ni Ọjọ April Fool
Ọjọ April Fool ti ọdun 2019 ni ile isẹ iroyin kan fi lede wi pe agbabọọlu Super Eagles, Alex Iwobi ti kuro ni Arsenal lọ si Barcelona.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ọjọ April Fool ni ọdun 1989 ni ile isẹ iroyin BBC gbe e jade loju aworan lasiko ti wọn n ka iroyin ere idaraya, ti awọn osisẹ akọrọyin si bẹrẹ si ni ja ninu aworan naa, amọ irọ lasan pẹlu itanjẹ ni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Bakan naa ni awọn eniyan kan ni Ilẹ Gẹẹsi lọdun 2019 n sọ wi pe wọn ti wọgile bii Ilẹ Gẹẹsi se fẹ kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti wọn si n beere pe ki awọn eniyan mu eleyii to ba jẹ April Fool ninu rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Oju opo imọ ẹrọ Google naa ko gbẹyin ninu itanjẹ Ọjọ April Fool. Wọn fi lede wi ldun 2019 pe awọn ti se ẹrọ ti yoo mu ki eniyan ba ewe Tulip sọrọ,ti ewe naa yoo si ma a fun eniyan lesi.
Bakan naa ni ile isẹ apanilẹrin ‘Ola’ naa ni awọn ti ni ile igbọnsẹ ni gbogbo ibi. Ohun ti o nilo lati se ni ki eniyan lọ si ori ẹrọ ayelujara wọn lori ẹrọ ilẹwọ wọn, pe ọkọ ile igbọnsẹ yoo de ibi to o wa lẹsẹkẹsẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4