Ìtàn mánigbàgbé: Ajayi Crowther ní ọjọ́ ìbànújẹ́ àmọ́ tó di ọjọ́ ayọ̀ ni ọjọ́ tí wọ́n kó òun lẹ́rú

Samuel Ajayi Crowther

Oríṣun àwòrán, @ArewaHistory

O ti pe irinwo ọdun bayii ti owo ẹru ti bẹrẹ jakejado agbaye, tawọn orilẹede agbaye si ti se ọpọ eto lati se ayẹyẹ naa, ninu eyi ti aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kopa.

Ọkan lara awọn eeyan to fori sọta akoko owo ẹru, to si di ẹru nigba naa, amọ ti ori ko yọ, to si pada di ojisẹ Ọlọrun ni oloogbe Samuel Ajayi Crowther.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu lẹta kan ti Ajayi Crowther kọ ko to dagbere faye lo ti salaye ohun ti oju rẹ ri loko ẹru ati bi wọn se koo lẹru, ko to di pe o ri idande gba.

Bi wọn se ko mi lẹru:

  • Ọjọ nla, tii se ọjọ manigbagbe ni ọjọ Kejilelogun osu Keji ọdun 1837, eyi ti n ko lee gbagbe lailai, se ọjọ ti ẹda yoo ba sọnu, gaga ni ara ya ni.
  • Ilu abinibi mi, Oṣogun lẹba ilu Ọyọ ni mo wa pẹlu awọn obi, ẹgbọn ati aburo mi lọkunrin ati lobinrin, taa si n gbadun aye wa nibẹ lai mọ pe ipinya sun mọ tosi, ti a ko si ni fi oju ri ara wa mọ.
  • Lootọ mo maa n ro pe ọjọ ibanujẹ nla gbaa ni sjọ naa, ams nigba ti mo roo nidakeji, mo ri pe ọjọ ibukun ati ọjọ ayọ lo jẹ ninu igbesi aye mi.
  • O ti to ọdun diẹ ti ogun ti n ja agbegbe Ọyọ laye igba naa, eyi to maa n mu ẹkun, ipayinkeke ati itajẹsilẹ nla wa, ti wọn yoo si ko ọps eeyan lẹru, isẹlẹ yii naa si yi kan ilu mi, Osogun nigba to ya.
  • Se bi ounjẹ aarọ la n dana lọwọ ni bii deede aago mẹsan aarọ, sadede la gbọ igbe pe ogun ti wọn ilu, tawọn ọmọgun to maa n mu eeyan lẹru fun tita si ti ya de.
  • Wọn ti wo ẹnu odi to wọ ilu mi, ninu eyi ti awọn ọkunrin to sangun bii ọọdunrun wa, amọ ogun naa ba wa lojiji, laarin wakati mẹrin, sn ti jẹ ilu Osogun run.
  • Iran yii ko se wo rara, awọn obinrin, ọkunrin, ọmọde ati agba di ẹru diẹ lori, wọn n sa lọ, nigba to ya, wọn sọ ẹru ori wọn nu lati du ẹbi ara wọn ati ti ọmọ, amọ nigba to tun ya ni ọrọ di bi ina ba jo ni, to jo ọmọ ẹni, tara ẹni laa kọkọ gbọn.
  • Asiko idarudapọ yii ni awọn akonilẹru raye wọ aarin wọn, ti wọn si so okun mọ ikọọkan wa lọrun bii ẹran, koda wọn pin lọkọ-laya niya, ti wọn si ta awọn ọmọ wọn sọtọ, lati igba yii si ni ipinya ayeraye ti de, ti wọn ko si fi oju ri ara wa mọ.
  • Wọn mu mi, ti wọn si pin mi mọ ibiti iya mi wa ati aburo mi obinrin meji, ti ọkan ninu wọn ko si ju ọmọ osu mẹwa lọ, pẹlu ibatan mi kan, ti n ko si foju kan baba mi mọ lati ọjọ naa, tori mo gbọ pe o ba ogun miran lọ.
  • Gbogbo ilu ni wọn sọ ina si, ti wọn si ko awa ti wọn mu lẹru gba ilu Isẹyin lọ, eyi to to ogun maili si ilu wa, ti mo si juwọ si ilu abinibi mi pe, o digbose, o tun di aye atunwa.
  • O nira fun awọn arugbo laarin wa lati rin bi awa ọmọ de ti n se, ti awọn ọta yii si n dunkoko pe awọn yoo ge ori wọn bọ silẹ, haa, ọjọ buruku, esu gbomi mu ni.
  • A de ibi odo to n san, wọn jẹ ka mu omi, taa si mu bii ẹni pe a ko ni mu omiran mọ, tori omi yii la fi se ounjẹ aarọ ni ọwọ irọlẹ.
  • Osu meji ni mo lo ni Iseyin, ti wọn si ta mi fun eeyan mẹta ọtọstọ, amọ ti wọn n da mi pada, ko to wa di pe wọn ta mi fun mi fun obinrin ara Popo kan, ẹni to ta mi fun eebo Pọtugi, ki wọn to gbe mi lọ soke okun.
Samuel Ajayi Crowther

Oríṣun àwòrán, @ArewaHistory

Oju ẹni maa la, a ri to, oju ẹni maa la, yoo ri iyọnu. Ọ́pọ́ isẹlẹ miran to n sẹlẹ si ẹda to maa n mu omije, idaamu ati iya nla wa, ni a maa n kọ, lai ms pe ọna ti a tọ de ibi ayọ wa ni.

Itan bi wọn si se mu Samuel Ajayi Crowther lẹru yii lo n kọ wa pe bi a ko ba jiya to to agbọ̀n, a ko lee jẹ aye to to aha.