BBNaija 2019: Gedoni kúrò ní BBNaija. Khafi bu sẹ́kún

Khafi ati Gedoni

Oríṣun àwòrán, khafibbn_officialfanpage

Gedoni Ekpata ati Jackye Madu ni wọn ti yọ kuro lori eto BBNaija 2019 to n lọ lọwọ.

Awọn meji yii ni wọn yọ ninu ile naa bi ẹni yọ jiga lọjọ Isinmi.

Gedoni, ẹni ti o jẹ ẹni kọkanla ti wọn yoo yọ ninu ile naa, ni o lọ lori ekun rẹ, to si n dupẹ lọwọ Ọlọrun lẹyin ti wọn ti yọọ tan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin yiyọ ti wọn yọ Gedoni yii lo gbomi loju Khafi bi ẹni ọfọ ṣẹ, bo tilẹ jẹ pe o gbiyanju lati maṣe da omi loju.

Nigba to n sọrọ lẹyin ti wọn yọ tan, Gedoni wi pe, ọpọlọpọ ẹkọ ni oun ti kọ ninu ile Big Brother.

Khafi ati ọrẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, khafibbn_officialfanpage

O tẹ siwaju pe, ọkan oun fa si Khafi, ti oun si nifẹ rẹ nitori pe Khafi jẹ ẹni ti kii dibọn, ti kii si hu iwa oniwa.

Gedoni salaye siwaju pe, oun ko ni ifẹ si Venita rara, sugbọn khafi nikan ni ọkan oun fa si.

Khafi ati Gedoni

Oríṣun àwòrán, khafibbn_officialfanpage

O wa pari ọrọ rẹ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe Mike lo maa jawe olubori ninu idije Big Brother naa.

Jackye ni tirẹ sọ pe, yoo jẹ didun inu oun to ba je pe Mercy lo maa jawe olubori ninu idije Big Briother naa.