Oúnjẹ àràmọ̀ǹdà mọ́kànlá tí wọ́n ń jẹ lágbààyé rèé, ẹ tẹ́wọ́ gbàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ounjẹ jijẹ jẹ ọrẹ ara, amọ jijẹ idin ninu burẹdi jẹ ohun to so si ni lẹnu, to si bu iyọ si.
Bayii ni ọrọ ri fun awọn to n gbe agbeegbe Sardinia ni orilẹede Italy, ti wọn fi idin se ounjẹ ajẹpọnnula, ti wọn yoo si dupẹ lọwọ ẹnikẹni to ba fun wọn ni burẹdi onidin jẹ.
Eyi lo mu ki wọn pinnu lati se afihan ile ounjẹ ti ko wọpọ lawujọ si awọn gbagede kan, eleyii to bẹrẹ ni Malmo, lorilẹede Sweden ni Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Kẹwa, ọdun 2018.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Só lè jẹ búrẹ́dì tí wọ́n fi Aáyán se?
- Ìdẹ̀ra dé, Gẹnẹrátọ̀ tó ń lo omi dé, a bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn
- Khafi jẹ̀bùn ọkọ̀ ₦7.6m lórí ètò BBNaija torí pó sọ̀rọ̀ ìwúrí nípa Nàíjíríà
- Bí mo ṣe dúró ti Toyin nílé ìgbẹ̀bí jẹ́ kí ń mọ̀ pé ó yẹ kí ọkùnrin máa bọ aya wọn - ọkọ Toyin Abraham
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji
- Ìjọba, ẹ yé fi ọlọ́pàá àtàwọn ológun dúnkokò máwọn èèyàn- Ṣoyinka
Sise afihan ounjẹ yii yoo fi agbara fun ero awọn eniyan wi pe, ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran.
Ẹ wo oúnjẹ àràmàndà 11 tí wọ́n ń jẹ lágbààyé
Yoruba bọ wọn ni bayii lati n se ni ilẹ wa, eewọ ibomiran ni.
Eyi lo mu ki onimọ nipa ihuwasi ati ise ọmọniyan, Samuel West sọ wi pe, ounjẹ jijẹ jẹ ohun abalaye to n se afihan ihuwasi eniyan ati ibi ti eniyan ti ṣan wa.
Orilẹede Italy ma n jẹ burẹdi ati iyẹfun ti wọn fi idin se:

Oríṣun àwòrán, Anja Barte Telin
China: Ni orilẹede China, wọn ma n jẹ oko akọ maluu. Awọn onimọ ni ki Obinrin o jẹ funfun, nigbati Ọkunrin yoo jẹ dudu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Anja Barte Telin
Uganda: Tata ni ounjẹ awọn ara Uganda, eleyii ti wọn ti yii lata. Wọn a ma jẹ ẹ pẹlu ọti waini.
Amọ eewọ ni fun awọn obinrin oloyun, ki wọn ma ba a bi ọmọ ti ọpọ́n ori rẹ yoo jọ ti tata.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mexico: Ounjẹ ati papanu ni ẹyin kokoro jẹ lorilẹede Mexico. Wọn ma n din, ti wọn si ma n gbadun rẹ lọpọ igba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Vietnam: Ọkan ejo Sèbé ni awọn eniyan ma fi n se ounjẹ jẹ. Wọn ni o ma n fi agbara kun agbara wọn.
Wọn si le e jẹ ọkan ejo naa pẹlu ẹjẹ ejo tabi oti waini Vodka.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ara orilẹede Iran, Afghanistan ati Iraq ko fi oju abo àgbò sere rara ati ọpọlọ rẹ. Gbogbo rẹ ni jijẹ fun wọn.
Wọn ni kii jẹ ki eniyan wuwo lalẹ to ba fẹ sun.
Ilẹ Gẹẹsi:Ounjẹ aarọ to peleke ni ki eniyan o fi ẹjẹ ẹlẹdẹ ti wọn ti sè, kun ounjẹ to fẹ jẹ lojumọ.
Ounjẹ owurọ ko i tii pe ni Ilẹ Gẹẹsi ti ko ba si ẹjẹ ẹranko ti wọn ti se nibẹ. Wọn ni o dara fun eroja asaraloore iron, zinc ati protein.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Peru: Omi ara ọpọlọ ti wọn ti rẹ ni awọn fi n se ara rindin, ti wọn si tun n ta a fun awọn eniyan gẹgẹbi omi ẹlẹrindodo to n mu araji pepe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun to wọpọ ni orilẹede Turkey ni lati fi igba aya ati ọmu akukọ se ounjẹ jijẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede China: Eleyii ya ni lẹnu pupọ ju. Orilẹede China a ma a fi ekute ile se ọti waini ẹlẹrin dodo.
Amọ awọn ekute yii gbọdọ jẹ eyi ti wọn sẹsẹ bi, ti ko i ti pẹ ju nilẹ. Wọn ni o ma n sisẹ fun aisan ikọfe e ati aisan jẹdọjẹdọ.

Oríṣun àwòrán, Mo Styles
Ni Russia: Ko buruju ti wọn ba fi omi ara ẹja to n sere ibalopọ se ọbẹ ti wọn yoo jẹ.
Moloka ni wọn n pe orukọ ounjẹ naa. Orilẹede Japan naa a ma a jẹ ounjẹ yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ ri pe awọn ounjẹ aramọnda pọ lorilẹ aye, ewo ni ẹyin fẹ ko jẹ ninu wọn?












