Búrẹ́dì Brazil: Èròjà 'Protein' tó wà lára Aáyán dára fún ènìyàn

Oríṣun àwòrán, FURG
Ajọ Isọkan Agbaye, United Nations ti fi lede wi pe, jijẹ kokoro bii aayan dara nitori eroja asaraloore 'protein' to wa lara kokoro naa dara fun eniyan.
Ajọ UN to ni ko to di ọdun 2050, eniyan to le ni billiọnu mẹsan ni yoo ma rin loke eepẹ, fikun wi pe, iyẹfun ti wọn fi kokoro ati aayan se dara fun eniyan, nitori eroja protein to pọ lara rẹ ju ti awọn eranko lọ.
Eyi waye lẹyin ti awọn onimọ lati orilẹede Brazil gbe abajade iwadii wọn sita wi pe, isoro si ọwọn gogo ounjẹ lagbaye ni ki eniyan bẹrẹ si ni lo eroja asaraloore protein, lati fi pese ounjẹ to se ara loore.
- Èèyàn mẹ́tàdínlógún jóná nínú ìjàmbá ọkọ̀ lọ́nà mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè
- Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ṣáájú ìdìbò abẹ́nú gómìnà ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Osun lọ́la
- Fọ́tò àǹkóò oyún ọmọ ìyá mẹ́ta gbòde kan
- Wo àwọn ewu àti ànfàní márùn ún tó wà nínú igbó mímu
- Ààrẹ Mozambique tẹ́lẹ̀ rí jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n fi kan ọmọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, FURG
Ninu ọrọ ti wọn, Ajọ Isọkan Agbaye ni, kokoro n sara loore, ti ko si wọn lati ri gẹgẹbi wọn ti n se lawọn apa agbeegbe kan ni Guusu-Ila oorun Asia.
Amọ, awọn oniwadii imọ ijinlẹ ni Brazil naa fikun wi pe, aayan ti awọn fi se burẹdi yii kii se iru aayan ti wọn n rin kaakiri nilẹ n lẹ, sugbọn eleyii ti wọn didi tọju lati se ara loore ni ayika Ariwa Ilẹ Afirika ni.

Oríṣun àwòrán, FURG
Awọn eroja kokoro miran ti awọn eniyan ma n jẹ ni alangba, alantakun, akekee, labalaba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, FURG









