Osun Guber Primary: Oyetola na ọwọ́ ìfẹ́ sáwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ń fi apá jánú

Àkọlé fídíò, Gomina Oyetọla pe ipe ifẹ yii ninu ọrọ to ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa sọ.

Gomina Gboyega Oyetọla ti ke sawọn oludije mejeeji ti wọn jọ dije fun aṣia idibo gomina nibi eto idibo abẹnu to waye lopin ọsẹ to kọja.

Gomina Oyetọla pe ipe yii ninu ipe akọkọ to sọ lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi olubori idibo abẹnu naa.

Moshood Adeoti pẹlu Lasun Yusuf lo baa dije fun ipo naa.

Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ṣáájú ìdìbò abẹ́nú gómìnà ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Osun lọ́la

Ibẹru bojo ti gbalẹ nipinlẹ Osun ṣaaju eto isibo abẹnu gomina ẹgbẹ oṣelu APC ọjọ Abamẹta.

Oludije mẹta ni yoo kopa ninu ibo abẹnu yii lati mọ ẹni ti yoo ṣoju APC ninu idibo gomina ọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ọdun 2022 yii.

Awọn oludije naa ni gomina ipinlẹ Osun lọwọ yii, Gboyega Oyetola, igbakeji adari ile aṣojuiṣofin l'Abuja tẹlẹ ri, Lasun Yusuff.

Oludije kẹta ti yoo kopa ninu ibo abẹnu ọhun ni Alhaji Moshood Adeoti to jẹ akọwe ijọba ipinlẹ Osun tẹlẹ.

Eto idibo gbangbalaṣanta ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC faramọ fun idibo naa.

Ki lo fa ibẹru-bojo ṣaaju eto ibo abẹnu gomina ẹgbẹ APC l'Osun?

Gboyega Oyetola ati Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Rauf Aregbesola

Laipẹ yii ni awọn ọmọlẹyin gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ, Rauf Aregbesola atawọn ọmọlẹyin gomina Oyetola kọlu ara wọn l'Osun.

Koda awọn kan ti fẹsun kan awọn ẹṣọ alaabo wi pe wọn n ṣegbe lẹyin ẹnikan pẹlu rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Osun.

Awọn ọmọlẹyin Aregbesola kan ti ẹ fẹsun kan kọmiṣọnna ọlọpaa Osun pe o n ṣegbe lẹyin gomina ipinlẹ Osun.

Oludamọran fun minisita ọrọ abẹnu, Aregbesola, lori ọrọ iroyin, Sola Fasure, sọ pe awọn janduku kan ṣe ikọlu si ọkọ Aregbe lọjọ Aje lẹyin ṣe ipolongo fun oludije rẹ.

Ṣugbọn kọmiṣọnna eto iroyin naa, Funke Egbemode, sọ pe awọn eeyan kan ti ya wọ ilu ti wọn si n wọ aṣọ ayederu ajọ abo ara ẹni ni abo ilu, NSCDC ati awọn to n sọ ọgba ẹwọn.

Aregbesola sọrọ lori aawọ to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ APC l'Osun

Aregbesola ṣalaye pe adari awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Osun ni Oyetola nigba ti oun fi jẹ gomina ipinlẹ Osun.

''Mo fi gbogbo agbara mi ṣiṣẹ lati ri pe Oyetola di gomina ipinlẹ Osun.

Ṣugbọn o jẹ iyalẹnu fun mi pe lati igba ti Oyetola ti di gomina ni o ti wa ṣọ mi lọwọ ṣọ mi lẹsẹ.

Ọdun meji ni mo fi bẹ Oyetola lati dẹkun aawọ to n ṣẹlẹ lọwọ yii ninu ẹgbẹ APC, amọ ko gbọ si mi lẹnu,'' Aregbesola lo sọ bẹẹ.

Adeoti ni oludije ti Aregbesola n ti lẹyin fun ipo gomina ninu ibo abẹnu ẹgbẹ APC.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti kede pe gbogbo eto lo ti to lati ri pe eto abo to muna doko wa fun eto idibo abẹnu naa lọjọ Abamẹta.