Supper Cop Abba Kyari: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti ni kí ACP Sunday Ubua àti ASP James Bawa lọ rọọ́kún nílé

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn òṣìṣẹ́ wa kò lọ́wọ́ nínú gbígbé egbògi olóró - NDLEA
Lati igba ti ajọ NDLEA ati iṣẹlẹ ṣeun ti wọn fi kan Abba Kyari yii ti bẹrẹ ni oriṣiiriṣii ti n jade nipa rẹ.
Àjọ tó ń gbógunti gbígbé egbògi olóró ní Nàìjíríà, NDLEA ti fọ ara wọn níbi ẹ̀sùn pé àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn gbígbé egbògi olóró tí wọ́n fi kan Abba Kyari.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ àjọ NDLEA, Femi Babafemi fi síta lọ́jọ́rú, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù kejì ní àwọn kò ní ìdí láti gbórí òṣìṣẹ́ tó bá lọ́wọ́ nínú bí egbògi olóró "cocaine" oní kílógíráàmù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, tí Abba Kyari ń kojú ẹ̀sùn rẹ̀, pamọ́.
NDLEA ní àwọn ní ìfarajìn sí lílo gbogbo ẹ̀rí tó wà ní ìkáwọ́ àwọn láti fi ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lóri ọ̀rọ̀ náà, tí àwọn kò sì ní fi ọwọ́ bo òótọ́ lójú mọ́lẹ̀.
- PDP àti APC pín ìjọba ìbílẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́ níbi ètò ìdìbó Abuja, èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
- Tí o bá ń pẹ́ jẹun alẹ́, o lè ní àrùn jẹjẹrẹ ọyàn àti asétọ̀
- Wo ọ̀nà mẹ́fà tí o fi lè gbógun ti ìdun nínú ilé rẹ
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Àjà ilé ọtí dàwó ní London, mẹ́tàlá nínú àwọn oníbàárà farapa
- Àwọn agbébọn ti yìnbọn pa ọlọ́pàá ní Enugu, kọlu àgọ ọlọ́pàá ní Anambra
- Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ọmọ ọdún kan àti oṣù méje pa ní ìpínlẹ̀ Delta, O bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá
Igbesẹ wo ni Ileeṣẹ Olopaa Naijiria ti wa gbe bayii?
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti kede pe ki awọn ọlọpaa meji mii lo rọọkun nile pẹlu Abba Kyari.
Wọn ti kede pe ki igbakeji Komiṣọnna ọlọpaa Sunday Ubua ati ọga ọlọpaa James Bawa lọ rọọkun nile.
Wọn ni koowa wọn ko gbọdọ kopa bii agbofinro mọ lasiko yii.
Awọn mejeeji ni wọn sọ pe wọn n ba Oga Olopaa Abba Kyari ti ẹnu n kun pẹlu ọrọ oogun oloro ṣiṣẹ papọ ni óọfiisi.
Awọn mejeeji yii wa labẹ Kyari ni ẹka Intelligence Response Team, Force Investigation and Intelligence Department nileeṣẹ ọlọpaa.
Awon mejeeji naa ni wọn tun fi ẹsun kan pe wọn lọwọ ninu ọrọ oogun oloro cocaine to n ja ranyinranyin nilẹ.
Kini o wa ninu lẹta lọ rọọkun nile naa?
Agbenusọ awọn agbofinro Ikechukwu Ani lo fi atẹjade naa sita loni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun yii.
O ni ọga agba pata ọlọpaa, Baba Alkali naa si mọ nipa ẹ.
Ani ni eyi wa ni ibamu pẹlu ofin Public Service Rules 030406.
Ati pe awọn mẹtẹẹta a wa bẹẹ titi ti wọn yoo fi pari iwadii bi o ti yẹ.
- Iléẹjọ́ tún sún ìgbẹ́jọ́ olórí ẹgbẹ́ IPOB Nnamdi Kanu síwájú
- Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè
- Olaleye Paul rí ẹ̀wọ̀n he ní àyájọ́ olólùfẹ́ ní Ilọrin
- Ẹ̀kún omi gbé èèyàn méjìdínlógójì lọ nílùú Petrópolis ní orílẹ́èdè Brazil
- Algeria yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní san N41,000 fáwọn ọ̀dọ́ tí kò rí iṣẹ́ ṣe lóṣù tó ń bọ̀
- Awakọ̀ dáná sun ara rẹ̀ lórí bí àwọn 'task force' ṣe mu l'Eko
- Ìjọba Canada ṣetán láti gbẹ́sẹ̀ lé àkáùntì àwọn tó ń ṣẹ ìwọ́de táko abẹ́rẹ́ covid-19
Ki ni o ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin?
Ẹ ó rántí pé àtẹ̀jáde kan tí ajọ ọlọ́pàá fi síta lọ́jọ́ Ajé láti fi kéde pé Abba Kyari ti wà ní gbaga àwọn ọlọ́pàá fẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ NDLEA kan lọ́wọ́ nínú bí egbògi olóró náà ṣe wọ ìpínlẹ̀ Enugu, Nàìjíríà.
Àtẹ̀jáde náà ní àwọn tó gbé cocaine náà wọ̀lú láti Ethiopia jẹ́rìí si pé àwọn ti ní àjọ̀ṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ NDLEA kan ní pápákọ̀ òfurufú Akanu Ibiam International Airport, Enugu lọ́dún tó kọjá tí wọ́n sì ṣe bí àwọn ṣe rọ́nà lọ.
Àjọ ọlọ́pàá wá ní NDLEA gbọ́dọ̀ ṣàfihàn orúkọ àwọn òṣìṣẹ́ náà kí wọ́n sì fi ìyà tó tọ́ jẹ wọ́n.
Kini NDLEA wa sọ bayii?
Ẹ̀wẹ̀, NDLEA jìyàn pé àwọn òṣìsẹ́ àwọn lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Kyari àti ti ọ̀kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ , Bawa James fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá ní àwọn tó ń gbé egbògi olóró náà pè láti Brazil.
NDLEA fẹ̀sùn kan pé Bawa jẹ́wọ́ pé IK kan ló pe òun láti Brazil pé àwọn ènìyàn méjì kan yóò gúnlẹ̀ sí Enugu pẹ̀lú bàálù Ethiopia Airlines pẹ̀lú cocaine àti zimmar.
Babafemi ní èyí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Abba Kyari àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé egbògi olóró wọ̀lú láti Brazil.


















